Wo àwọn iṣẹ́ tí ìjọba UK gbé jáde táwọn èèyàn fi lè gba físà wọ orílẹ̀ èdè náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba United Kingdom, UK ti kede awọn iṣẹ ti awọn eeyan ilẹ okeere fi le fi wọ orilẹ ede naa labẹ eto awọn ti wọn le gba ilana iṣẹ ṣiṣe wọbẹ.
Atẹjade naa ti ijọba UK gbe soju opo UK Home Office lori opo ayelujara ṣafihan iru awọn iṣẹ ti awọn eeyan le fi gba fisa wọ orilẹ ede naa.
Wọn ni atẹjade naa lo ilana igbanisiṣẹ UK tọdun 2020 iyẹn UK Standard Occupational Classification.
Gẹgẹ bi Home Office ṣe sọ, ẹni to ba fẹ fi awọn iṣẹ naa wọ UK gbọdọ mọ koodu mẹrin to wa niwaju iṣẹ naa ki wọn to wo o boya wọn le forukọ silẹ fawọn iṣẹ naa.
Lara awọn iṣẹ ti wọn fi lede gẹgẹ bi awọn iṣẹ ti wọn wa nipo nla ti wọn n wa awọn oṣiṣẹ si ni awọn adari ni ẹka ohun amuṣagbara, imọ ẹrọ, awọn to n ṣe ina mọnamọna, awọn onimọ ẹrọ nipa oju ofurufu, awọn nọọsi, awọn to n poogun, awọn dokita eyin ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni wọn tun gbe awọn iṣẹ ti ko fi bẹẹ lagbara to ti awọn ipele akọkọ yii jade bii awọn agbẹ, awọn to nimọ nipa ọsin ati tita ẹja, awọn to n jo irin, awọn to n tọju ododo ninu ọgba, awọn to n ṣiṣẹ lori paanu ile, awọn to maa n to paipu omi ati bẹẹ lọ.
Awọn mii ti wọn tun ka sabẹ ipele yii ni awọn oṣiṣẹ ilera ti wọn maa n ran awọn nọọsi lọwọ, awọn ti wọn maa n wa ọkọ iṣẹlẹ pajawiri, awọn nọọsi to n ri si ọrọ eyin, awọn to maa n tọju awọn eeyan nile ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ileeṣẹ Home Office ni awọn oṣiṣẹ to wa ni ipele keji yii maa nilo awọn nnkan mii ki wọn to le gba iṣẹ.
Labẹ ofin igbanisiṣẹ to wa lọwọ yii, awọn ti wọn ba fẹ fi iṣẹ wọ UK labẹ ipele iṣẹ keji nilo ki iṣẹ naa wa lara awọn iṣẹ ti ajọ to n ri si iwọlewọde orilẹ ede naa tabi ko wa lara awọn iṣẹ ti wọn nilo awọn eeyan sibẹ.
Ijọba tun ṣe afọmọ rẹ pe nini awọn iṣẹ yii ko tumọ si pe eeyan maa ri fisa gba.
Wọn ni ẹni to ba maa ri fisa gba gbọdọ ti kọkọ ri iṣẹ gba latọwọ ijọba UK ti Home Office buwọlu, ti iye ti wọn yoo si maa san loṣu gbọdọ w ani ibamu pẹlu ilana owo oṣu ijọba UK.
Iye to kere julọ lọdun ti wọn le san fun awọn to wa ni ipele yii ni £41,700 lọdun kan ti eyi si le pọ ju bẹẹ lọ fun awọn iṣẹ mii.
Wo awọn iṣẹ ti wọn le gba eeyan fun:
Olori ileeṣẹ ati adari lẹnu iṣẹ
- Alokooso atawọn adari ni ileeṣẹ ipese ọja
- Alokooso atawọn adari lẹka ile kikọ
- Alokooso atawọn adari lẹka iwakusa ati ohun amuṣagbara
- Awọn onimọ ẹrọ nipa ọkọ ṣiṣe
- Awọn onimọ ẹrọ nipa ina mọnamọna
- Awọn onimọ ẹrọ nipa ọkọ ofurufu
Awọn iṣẹ ẹka ilera
- Awọn nọọsi
- Awọn nọọsi nipa aarun ọpọlọ
- Awọn nọọsi nipa awọn ọmọde
- Awọn nọọsi nipa imọ ilera mii
- Awọn onimọ nipa ẹranko
- Awọn onimọ ipoogun
- Awọn onimọ nipa oju
- Awọn onimọ nipa eyin
- Awọn onimọ nipa akanda eeyan
Ẹka eto ọgbin ati okoowo
- Awọn agbẹ
- Awọn onimọ nipa ododo
- Awọn to maa n tun ọgba ṣe
- Awọn jorinjorin
- Awọn to maa n ṣe ohun elo
- Awọn ọlọsin ẹja
Ijọba parọwa sawọn ti ko ba ri iṣẹ wọn ninu awọn eyi ti wọn gbe jade yii lati wa a labẹ eyi to ba jọ ọ nitori iṣẹ mii maa n ni koodu ọtọ labẹ iṣẹ omiran.
Wọn ni awọn to ba fẹ wọ orilẹ ede naa UK gbọdọ ṣawari koodu iṣẹ wọn, iye ti wọn yoo maa gba lowo oṣu, ri atilẹyin ileeṣẹ ti wọn fẹ ba ṣiṣẹ, atawọn nnkan mii to so mọ iṣẹ wọn ki wọn to fi orukọ silẹ lati beere fun fisa.


























