Ibà Lassa pa èèyan 258 láwọn ìpínlẹ́ kan ní Naijiria, òǹkà ikú lé sí i ní ìdá mẹ́rìnlélógún- NCDC

Oríṣun àwòrán, Others
Bi aisan iba Lassa to maa n wa lati ara eku ṣe n ṣọṣẹ lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria, ajọ Nigeria Centre for Disease Control and Prevention (NCDC) ti kede pe o ti to eeyan ejidinlọgọtalenigba (258), ti aisan naa ti pa lorilẹede yii lọdun 2026 yii.
Bakan naa ni wọn ni onka iku naa ti gunke ni ida mẹrinlelogun(24%).
Atupalẹ NCDC nipa bi Iba Lassa ṣe ṣọṣẹ
Ninu atẹjade ti NCDC fi kede ijamba ti Iba Lassa ṣe nu ọsẹ karundinlogoji (week 35), iyẹn ọjọ kerinlelogun si ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ, eeyan mejidinlogun lo lugbadi aisan naa ni Ondo, Edo ati Bauchi .
Apapọ onka Iba Lassa ti wọn fi lede lọwọlọwọ lọdun yii ni 1,074, o si ti to eeyan 7,785 ti wọn ni òye foju han pe wọn ni aisan naa.
Alekun ba iye eeyan to ku lọdun yii ju tu asiko yii kan naa ni 2025 lọ bi NCDC ṣe kede. Eeyan 162 ni won lo pa niwoyi ọdun 2025.
Amọ adinku ba onka awọn to ni iba naa lati mọkanlelogun si mejidinlogun (21 to 18) lọsẹ karundinlogoji bi wọn ṣe sọ.
Ida 86% to waye lọdun yii ni wọn lo wa lati— Ondo, Bauchi, Taraba, Edo ati Benue.
Ondo ni ida 34% Bauchi, ni 24%, Taraba ni mejila (12 %), Edo ni mẹwaa nigba ti Benue ni mẹfa.
Awọn ọjọ ori wo ni aisan naa n kọlu ju?
NCDC sọ pe awọn eeyan ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mọkanlelogun si ọgbọn ọdun ( 21- 30) ni iba Lassa n kọlu julọ.
Bakan naa ni won lo n kan awọn ọmọde titi kan agba ti ọjọ ori wọn ti le ni aadọrun-un (90).
Ajọ naa sọ pe iba Lassa ko kan awọn oṣiṣẹ eleto ilera lọsẹ karundinlogoji yii, bo tilẹ jẹ pe mẹrinleladọta (54) wọn lo ti kan ninu ọdun 2026 yii.
Eeyan 816 ni wọn lo n gba itọju lọwọ nibudo itọju NCDC.
Awọn ohun ti wọn lo n fa iku Lassa yii ni aitete sọ awọn to mu, ai tete wa itọju si I ati bi owo itọju iba naa pẹlu ibudo itọju ṣe gara.
Idi miran ti NCDC la kalẹ ni ai to imọtoto, ai ni imọ to lori aisan naa ati bo ṣe n ran laaarin awọn olutọju.
Ajọ naa fi kun un pe oun ti bẹrẹ igbesẹ lorii iwadii, idena ati amojuto itankalẹ arun naa lawọn ipinlẹ kiri.
Awọn ile iwosan ipinlẹ meje ti ọrọ naa kan ju si ti gba awọn nnkan itọju aisan naa bi wọn ṣe sọ.
Bawo ni o se le mọ pe o ni arun iba ọrẹrẹ?
- Ko maa rẹ eeyan latinu wa
- Ki ọna ọfun maa dun eeyan
- Ki eeyan maa ya igbẹ leralera
- Ki ẹjẹ maa da lati imu, erigi
- Ki ẹjẹ maa wa ninu itọ eeyan tabi loju abẹrẹ
- Ki igba aya maa ro eeyan
- Ki eeyan ni irora lati mi
Ọna marun un lati dèna Lassa Fever
Aisan iba ọrẹrẹ jẹ aisan ti ko ni ẹrọ, amọ ti o ni itọju ti ẹni to ba ni aisan naa ba tete lọ si ile iwosan lati fi ara rẹ han.
Ọna ti a le gba dina aisan ti o wa lati ara ẹran igbẹ papa eku inu ile:
- Ẹ sọra fun jijẹ eku tabi ẹran igbẹ.
- Ẹ ma se sa garri sita gbangba.
- Ẹ pa awọn eku to ba wa ni inu ile ati agbegbe yin.
- Ẹ pa oko tabi koriko ti o ba wa ni agbeegbe, ki ayika naa le wa ni mimo ni gbogbo igba.
- Awọn ohun elo ounjẹ gbọdọ wa ni inu ike ti ẹkutele ko lee de bẹ.
- Ẹ sọra lati farakan ẹni ti o ma ni aisan iba ti kosi tete lọ.
























