Irọ́ làwọn tó ń sọ pé epo wọ́n ní Nàìjíríà ń pa, owó epo Nàìjíríà ló kéré jùlọ lágbègbè rẹ̀ – Dangote

Aworan Aliko Dangote
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aliko Dangote, baba olowo to ni ileeṣẹ ifọpo Dangote ti sọrọ sita pe irọ lawọn to n pariwo pe idasilẹ ileeṣẹ epo Dangote ko mu irọrun ba owo ti awọn eeyan n san lori epo bẹntiro lorilẹede Naijiria, ati wi pe dipo bẹẹ nṣe lo n peleke sii.

Aliko Dangote sọ eyi nigba to n dahun ibeere BBC lori bi idasilẹ ileeṣẹ ifọpo rẹ ṣe fẹ ṣe anfani fun awọn eeyan agbegbe ẹkun naa ati orilẹede Kenya gan an funrarẹ pẹlu bi awọn onwoye ṣe n sọ ọ pe idasilẹ ileeṣẹ ifọpo rẹ lorilẹede Naijiria ko mu adinku ba iye owo tawọn eeyan n san lori epo bẹntiroolu lorilẹede Naijiria. O ni ko si otitọ ninu ọrọ ti awọn eeyan n sọ ati wi pe iye ti awọn eeyan n san fun epo bẹntiroolu lorilẹede Naijiria lo fẹẹ kere julọ bi wọn ba gbe e yẹwo pẹlu iye ti awọn eeyan n san lawọn orilẹede to yii ka.

"Owo epo lorilẹede Naijiria lo lọ silẹ julọni ida marundinlọgbọn bi a ba fi we awọn orilẹede to yii ka"

O ni iye owo ori epo kọ ni iṣoro to wa nilẹ nitori pe, owo ti wọn n ta owo epo lagbaye ti oun n ra gan lo n fa bi nnkan ṣe n lọ.

'Ipinnu mi lati rii pe Africa ko ta ogun ini rẹ lowo pọọku silẹ okeere lo mu mi da ileeṣẹ ifọpo silẹ ni Kenya'

Aworan ibudo ifọpo Dangote

Eto gbogbo ti to bayii fun ifilọlẹ ibudo ifọpo Dangote ni orilẹede Kenya. Ibudo ifọpo naa yoo maa ṣiṣẹ fun ẹkun ila ooru Africa.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, Aliko Dangote ṣalaye pe, oun ko nii lọkan lati bẹrẹ ileeṣẹ ifọpo kankan ni agbegbe naa lawọn ọdun diẹ sẹyin, ṣugbọn ipinnu oun lati rii pe Africa dẹkun kiko awọn ohun alumọni rẹ ṣọwọ si oke okun, ki awọn naa le bẹrẹ si ni ta awọn ohun elo ti wọn ti funrawọn pari iṣẹ rẹ, lo mu ki oun pinnu lati da ileeṣẹ ifọpo naa silẹ.

Dangote ṣalaye pe ileeṣẹ ifọpo ti wọn fẹ ṣe ifilọlẹ rẹ lorilẹede Kenya yoo bẹrẹ iṣẹ ki o to di ọdun 2030, iyẹn ọdun mẹrin si asiko yii.