INEC fẹ́ẹ́ lo ẹ̀rọ AI fún ìdìbò ọdún 2027, bí yóò ṣe lọ rèé

Oríṣun àwòrán, INEC/X
Ajọ eleto idibo, INEC, ti kede erongba rẹ lati lo imọ ẹrọ agbelẹrọ ti a mọ si Artificial Intellgence (AI), fun eto idibo apapọ ọdun 2027 ti yoo waye loṣu Kin-in-ni.
Chukwuemeka Chukwu, Kọmiṣanna eto idibo nipinlẹ Enugu lo sọ eyi di mimọ lasiko to ṣoju Ọjọgbọn Joash Amupitan, Alaga INEC, nibi eto awọn olootu iroyin to waye l'Enugu lopin ọsẹ.
Chukwu to kede eyi lorukọ Amupitan, ṣalaye pe lilo AI yoo waye lati dẹkun magomago ati èrú ninu idibo naa.
O ni AI yoo ran INEC lọwọ lati mọ awọn ibi ti kudiẹ-kudiẹ ba wa ninu esi idibo naa.
Bi lilo AI yoo ṣe ṣiṣẹ fun idibo
Ninu alaye Amupitan lo ti ni yatọ si pe INEC yoo lo AI fun idibo yii, ajọ naa tun ti gbogun ti awọn to le lo ẹrọ naa lati gbe awuruju esi idibo jade.
Awọn bii lilo AI lati ṣe ofege iwe esi idibo, lilo ayederu ohùn ẹnu awọn oṣiṣẹ eleto idibo lati kede ofege esi idibo, gbigbe ayederu fidio esi ibo jade ati ṣiṣe ẹda awọn iwe ajọ INEC.
O ni imọ ẹrọ yii ko si fun lati pa ofin rẹ, bi ko ṣe lati kun un lọwọ fun abajade rere.
"A ti ṣe ẹka AI si abala imọ ẹrọ wa (ICT Department), a si tun ti ṣeto rẹ lọna ti ijọba naa yoo fi le lo o.
"Bakan naa ni a ti fi to awọn ileeṣẹ nla lagbaaye bii Microsoft ati Google leti, nipa bi a ṣe le da aabo bo o, eyi ti yoo di ewu ku."
Bẹẹ ni Ọjọgbọn Amupitan wi.
INEC tun n sowọpọ pẹlu awọn ẹka to n kọ awọn oṣiṣẹ wọn ni lilo AI ati ewu to rọ mọ lilo rẹ, ati ọna ti wọn le gba lo ẹrọ naa ki idibo too de rara.
Ṣaaju ni Ọjọgbọn Amupitan ti lọ si ipade lori AI ni Canada, eyi ti wọn pe ni "Global Conference on Responsible AI and Elections."
Ottawa, ni Canada, ni idanilẹkọọ naa ti waye ninu oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 yii, nibi ti Alaga INEC naa ti sọrọ lori bi wọn yoo ṣe lo AI lati mu eto idibo kun fun otitọ ni Naijiria.
Ọjọgbọn Amupitan sọ pe idibo Naijiri anilo AI, pẹlu bawọn eeyan to n forukọ silẹ fun idibo ṣe to miliọnu mẹtalelaadọrun-un, ti ibudo idibo si to ẹgbẹrun lọna ọgọsan-an (180,000).
Awọn imọ ẹrọ ti INEC ti lo ri ni: Bimodal Voter Accreditation System (BVAS) ati Result Viewing Portal (IREV).
























