Wo kókó ohun tí Ààrẹ Tinubu bá àwọn ọmọ Naijiria sọ ní àyájọ́ òmìnira

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu
Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti sọ fun awọn ọmọ Naijiria pe igbesẹ ti ijọba oun gbe lọdun 2023 ti n so eso rere bo tilẹ jẹ pe igbesẹ naa kọkọ mu inira ba araalu.
Tinubu lo sọ beẹ lasiko to n ba awọn araalu sọrọ laarọ kutu ayajọ ọjọ ominira, to jẹ ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 yii.
Tinubu sọ pe Naijiria ti n wọ igba ọtun ninu eyii ti ipese iṣẹ, idagbasoke awọn ileesẹẹ ati mimu adinkuba oṣi wa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, igba iṣoro ti Naijiria la kọja to n wa si opin, nitori naa ki awọn araalu ma sọ ireti nu ninu orilẹede wọn.
Gẹgẹ bo ṣe maa n sọ ninu awon ọrọ rẹ ṣaaju, Tinubu ni lootọ ni Naijiria ti la awọn ipele kan to le koko kọja amọ olori gbọdọ di oju rẹ lati gbe awọn igbesẹ to lagbara.
O ni Naijiria da bii eeyan to n ba aisan jẹjẹrẹ finra amọ to nilo lati lo oogun ti yoo dun un ko le gbadun.
Iwọnyi ni lara awọn koko mii to sọ ni oni ayajọ ọjọ ominira.
'A ko ni da owo iranwọ ori epo pada'
Tinubu bu ẹnu atẹ lu awọn eeyan kan to ni wọn lẹnulọrọ ni Naijiria amọ to da bii pe ọrọ ifaṣeyin ni wọn n sọ lori owo iranwọ ori epo naa.
Awọn kan gbagbọ pe atiku Abubakar ni Tinubu n fi ohun ranṣẹ si pẹlu ọrọ yii.
Ṣaaju ni Atiku ti sọ pe oun yoo da owo iranwọ ori epo naa pada ti oun ba le de ipo Aarẹ.
'Awọn igbesẹ ti a n gbe n so eso rere'
Tinubu ni awọn igbesẹ ti ijọba oun n gbe ko ṣakoba fun eto ọro aje Naijiria, kaka bẹẹ, niṣe lawọn igbesẹ ọhun n so eso rere.
O ni lọdun 2023 ti oun gba ijoba, ọpọ lo ti sọ ireti nu ni Naijiria, idi reẹ ti ijọba oun ko ṣe kọ lati gbe igbesẹ akin.
O ni "Ọdun mẹta abọ lẹyin naa, o han gbangba pe eto ọrọ aje Naijiria ti n daa ju bo sẹ wa tẹlẹ lọ.
"Awọn to n ji epo ta ko ri epo ji ta mọ, ọwọngogo ti wa silẹ ju bo ṣe wa ṣaaju lọ. Owo ti a ni silẹ okeere n pọ si… Naijiria si n pa owo gọbọi wọle lori epo rọbi to n ko jade."
'Ibukun ati aṣeyọri nlan n bọ lọna'
Tinubu sọ ninu ọrọ rẹ naa pe "Ti mo ba n sọ nipa ibunkun, mi o kan sọ nipa ọrọ aje ti orilẹede nikan, mo n sọ nipa eyii ti araalu yoo mọ lara."
O ni lakoko ibunkun nla yii, awọn agbẹ yoo le lọ soko wọn laisi ibẹru, wọn yoo ko ere oko jade, ounjẹ yoo pọ, awọn agbẹ ọjun yoo si pa owo wọle sapo ara wọn.
'Lootọ awọn eeyan n jiya amọ n ṣiṣẹ lori rẹ'
Tinubu ni oun mọ ọpọ ọmọ Naijiria lo ṣoro fun lati jẹun, san owo ile ẹkọ awọn ọmọ wọn, san owo ile iwosan ati lati wọ ọkọ ni igboro.
Amọ ṣa, o ni iya ti awọn eeyan n jẹ lonii jẹ ere ijọba buburu to ti waye sẹyin ṣaaaju asiko yii.
Lẹyin naa lo mẹnuba awọn nnkan ti ijọba rẹ n ṣe lati din awọn iya naa ku bi eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ, NELFUND, ati eto ẹyawo CREDICORP, atawọn nnkan mii.
'O ku diẹ ki a de ebute ogo'
Tinubu pari ọrọ rẹ pẹlu ọrọ iyanju si araalu pe ki wọn ma sọ ireti nu ninu ijoba wọn.
O ni oun ni igbagbọ ninu ọjọ ọla rere to wa niwaju Naijiria.
Tinubu sọ pe "A n wo ibi ti a n lọ niwaju, ipinlẹ wa lagbara, a mọ ibi ti a n lọ. Nitori naa, ẹ jẹ ki a maa tẹsiwaju lai wo ẹyin."


























