Wo kókó àbájáde ìwádìí ìjóba Oyo lórí ìjínigbé Oriire

Oríṣun àwòrán, Oyo State government
Igbimọ to ṣewadii ijinigbe to waye ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo ti gbe abajade iwadii rẹ jade, o si ti fi le gomina Seyi Makinde lọwọ.
Ninu ijinigbe naa ni awọn agbebọn ti ji awọn olukọ atawọn akẹkọọ gbe ki wọn to gba itusilẹ ni nnkan bii oṣu meji lẹyin naa.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ karundinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2027 yii ni awọn agbesumọmi ji awọn akẹẹkọ ati awọn olukọ naa gbe niluu Yawota ati Esinele to wa ni ijọba ibilẹ Orire, nipinlẹ Oyo.
Ki ni koko abajade iwadii igbimọ naa?
Awọn koko wọn yii ni igbimọ ọhun fi lede ninu abajade iwadii wọn to tẹ BBC Yoruba lọwọ.
- Ijinigbe naa kii ṣe lati gba owo
- Ohun ija oloro ni wọn fi ṣoṣẹ, lara awọn ohun ti wọn lo ni ado oloro
- Igbimọ naa ni ẹgbẹ agbesunmọmi Ansaru (Jama'atu Ansarul Muslima Fi Biladis-Sudan), to ni ibaṣepọ pẹlu ẹgbẹ to Al-Qaeda lo wa nidi ikọlu naa
- Igbimọ ọhun fidi rẹ mulẹ pe iṣẹ agbesunmọmi ni ikọlu naa, ati pe itusilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn to wa ni ahamọ ni wọn n bere fun, kii ṣe owo
- Igbimọ naa ni ko si ẹri kankan pe awọn agbesunmọni naa bere owo ti iye rẹ to biliọnu kan naira tabi awọn ọkọ ayọkẹlẹ
- Ohun to jẹ ki ikọlu naa ṣeeṣe
- Gẹgẹ bii igbimọ naa ṣe sọ, awọn nnkan wọn wọnyii lo jẹ ki ikọli naa ṣeeṣe
- Igbo ọba to pọ ti ijọba ko bojuto
- Eto aabo ti ko peye lawọn ile ẹkọ
- Aisi eto aabo to peye lawọn igberiko
- Mi mọọmọ dojukọ awọn ile ẹkọ gẹgẹ bii ibi to rọrun lati kọlu
Igbimọ ọhun tun siwaju si pe ko si ẹri kankan to fidi rẹ mulẹ pe ikọlu naa waye nitori pe gomina Seyi Makinde n du ipo Aarẹ Naijiria.
Iye awọn to ku ninu ikọlu ọhun
Abajade igbimọ naa ni eeyan mẹrindinlaadọta ni wọn ji gbe.
Amọ o ṣeni laanu pe apapọ eeyan mẹwaa lo jade laye lasiko ikọlu naa, lẹyin rẹ ati lasiko ti wọn n gbiyanju lati dola awọn eeyan naa ti wọn ji gbe.
Lara awọn to ku ni olukọ, ọmọ ogun, awọn ọdẹ, ẹṣọ aṣogbo ati ọlọkada kan.
Imọran igbimọ naa fun ijọba ipinlẹ Oyo
- Ki ijọba Oyo ṣagbekalẹ eto aabo to peye laarin awọn ẹṣọ alaabo
- Ṣagbekalẹ eto oju lalakan fi n ṣọri
- Jawe sobi eto aabo lawọn ile ẹkọ
- Ṣiṣe amulo eto 'Safe Schools Initiative'
- Fi awọn ẹṣọ alaabo ṣọwọ si awọn ile ẹkọ fun eto aabo to peye
- Gbe ibudo awọn ẹṣo alaabo sawọn ilu to ṣeeṣe ki ikọlu ti maa waye
- Ro ẹsọ alaabo Amotẹkun lagbara ju bi wọn ṣe wa yii lọ
- Yanju ọrọ oye Ọba Onikoyi ti Ikoyi Ile ti ko ni ọba
- Ṣeto owo gba mabinu fun awọn idile ti iṣẹlẹ naa kan gbọngbọn
- Ra ọkọ ati alupupu mii fun awọn ti wọn padanu ọkọ tabi alupupu wọn sinu ikọlu naa
- Pese iranlọwọ fun eto ẹkọ awọn ọmọde ti wọn ji gbe
- Ki ijọba gba olukọ ile ẹkọ aladani ti wọn ji gbe nibẹ sile ẹkọ ijọba
- Jawe sobi ibaṣepọ to dan mọran lori eto aabo laarin ipinlẹ Oyo, Kwara, Kogi ati Niger
- Ko awọn ọmọ ogun ati ọlọpaa si awọn igbo ọba
- San owo gba mabinu fun mọlẹbi gbogbo awọn agbofinro to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa, ati bẹẹ bẹẹ lọ
Ẹwẹ, gomina Seyi Makinde ti ṣeleri lati sọrọ lori gbogbo abajade iwadii yii ni gbangba.
O ni ijoba oun yoo jiroro pẹlu gbogbo ẹka ijọba apapọ to ye lori awọn abajade naa.
Alaga igbimọ oluwadii naa, Mojeed Owoade sọ fun BBC Yoruba pe iwadii fi han pe ọpọ ile ẹkọ ni awọn agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni ko ni odi rara, eleyi lo si faye gba bii awọn agbebọn naa ṣe ya wọ awọn ile ẹkọ ọhun laisi idaduro kankan.


























