Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ Ademola Adeleke lẹ́yìn tó wọlé ìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun fún sáà Kejì

Oríṣun àwòrán, @AAdeleke_01
Inu ẹni kì í dùn ka pa a mọra, bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ ṣe rí pẹlu Gomina Ademola Adeleke to n dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Osun leyin to wọlé fun saa keji gẹgẹ bíi gomina ipinlẹ naa.
Ninu ọrọ ti Adeleke fi soju opo X rẹ lọjọ Aiku ọjọ kẹrindilogun oṣù Kẹjọ yii, Adeleke gboṣuba fun Ọlọrun àtàwọn eeyan ipinlẹ Osun fun igbẹkẹle tí wọ́n ní ninu rẹ lati sin wọn sì í fún ọdún mẹrin mii.
Gomina ipinle Osun sọ pe awọn eeyan ipinlẹ Osun ni aseyori oun ninu eto idibo naa wà fún.
Adeleke dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Osun fún ìgboyà ati ifarada won lati ri pe ìjọba àwarawa f'ẹsẹ múlẹ l'Osun.
"Maa ṣe àtúnṣe àwọn aṣiṣe ti mo ti ṣe sẹyin, ijọba mi yoo tẹsiwaju pẹlu awọn eto to ti mu ilọsiwaju wa"
"Mi o ni já yin kulẹ, mo tun n fi asiko yii rọ gbogbo eeyan ipinlẹ Osun lati gba alaafia laaye ki a si wa ni isokan, ni báyìí ti eto idibo ti kọja.
Mo tun fi asiko ke pe awọn ti alajọdupo gomina wi pe ki won ṣiṣẹ pọ pẹlú mi tori Gómìnà gbogbo eeyan ipinlẹ Osun ni mi.
Mi o le ṣàì rántí àwọn èèyàn tí wọn padanu emi wọn nigba ti eto idibo ku si dẹdẹ.
Ki Eledua tẹ wọn si afẹfẹ rere," Adeleke lo sọ bẹẹ.
Gomina ipinlẹ Osun wa fi dawon eeyan ipinlẹ Osun loju pe oun yoo ṣe àtúnṣe àwọn aṣiṣe toun ti ṣe, nigba ti ijọba oun yoo tẹsiwaju pẹlu awọn eto to ti mu ilọsiwaju wa.
Adeleke ni Osun tun ti wa lori irin bayii, o ni ìjọba oun yoo mu idagbasoke wa sí ipinlẹ naa si i.
O fikun ọrọ rẹ pe ìjọba oun ko ni kaarẹ lati sọ ipinlẹ Osun di ipinlẹ t'awọn olokowo n lọ dokowo níbẹ, ti ipinlẹ Osun ko si ni i jẹ ipinlẹ awọn oṣiṣẹ ijoba mọ.
Adeleke ko ṣàì dupẹ lọwọ Ààrẹ Bọla Tinubu fun bi o ṣe gba eto idibo to lọ nirọwọ rọsẹ laaye nipinlẹ Osun.
Gomina tun fidi rẹ mulẹ pe ọmọbibi ipinlẹ Osun ni Tinubu, o si tun ṣeleri gẹgẹ bi o ti sọ tẹlẹ wi pe oun ni oludije tẹgbẹ Accord yoo dibo fun l'Osun ninu ibo aarẹ ọdun 2027 ki o le wọle fun saa keji.
Bakan naa ni Gomina tun dupẹ lọwọ gbogbo eeyan to fẹràn ètò ìjọba àwarawa nile ati loke okun fun ipa ti wọn ko, lai yọ awọn akoroyin silẹ.
''Aṣeyọri Adeleke tumọ si pe eto ijọba awarawa n gbilẹ si i labẹ isakoso ìjọba APC tó wa lode''
Ẹwẹ, Ààrẹ Bola Tinubu ti sọ pe bi Adeleke ṣe wọlé ibo gomina ipinlẹ Osun lẹẹkeji túmọ sí pé eto ìjọba àwarawa n gbilẹ si i labẹ iṣakoso ìjọba APC tó wà lóde.
Tinubu sọ nínú atẹjade ti Bayo Onanuga oludamọran ààrẹ lori eto iroyin fi lede wí pé òun pe Adeleke lori foonu lati ki í ku oríire fun aṣeyọri rẹ.
Ààrẹ Naijiria ni aseyori Adeleke tun tọka si igbẹkẹle t'awọn eeyan ipinlẹ Osun ni nínú rẹ.
"Mo gbadura pe Adeleke yoo ṣe àṣeyọrí bi o ti n gbaradi lati tukọ ipinle Osun fún ọdún mẹrin mii.
Ni báyìí tí Adeleke ti wọlé, o gbọdọ ko gbogbo eeyan Osun mọra ki gbogbo eeyan si gbọdọ wa ni iṣọkan.
Adeleke gbọdọ wa idagbasoke ati ilọsiwaju gbogbo eeyan ipinlẹ naa lai fi ti ẹni ti wọn dibo fun ṣe.
Mo ki awọn oludije yooku naa, bi wọn ṣe kopa ninu eto idibo gomina Osun tun ti jẹ ki ijọba awarawa fẹsẹ mulẹ si i,'' Tinubu lo sọ bẹẹ.
Aarẹ tun gboṣuba fun ajọ eleto idibo INEC atawọn ẹṣọ eleto aabo fun iṣẹ takun takun ti wọn ṣe eyi to jẹ ki eto idibo gomina ipinlẹ Osun lọ ni irọwọ rọsẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post



























