You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
ADC ní alága INEC ti gbàbọ̀dè, awọn fẹ́ kó kọ̀wé fipò sílẹ̀, APC fèsì pé kò sẹ́ni tó kó ba wọn, fúnra ara wọn, ni wọ́n ń ṣera wọn
Ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC ti pè fún ìyọnípò alága àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ilẹ̀ Nàìjíríà, ìyẹn Independent National Electoral Commission, INEC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Joash Amupitan.
Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC tún fẹ̀sùn kàn pé ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ń gbèrò láti lo INEC láti sọ Nàìjíríà di orílẹ̀ èdè ẹlẹ́gbẹ́ òṣèlú kan ṣoṣo ṣáájú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.
Alága ADC, David Mark nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní Yar'adua Centre tó wà ní Abuja sọ pé alága àjọ INEC ti gbàbọ̀dè, tó sì ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí kò tọ̀nà lábẹ́ òfin.
Ó ní ẹgbẹ́ òṣèlú ADC kò ní ìgbàgbọ́ nínú Amupitan láti ṣètò ìdìbò tí kò ní ẹja n bákàn nínú níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀ náà pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ti farasin sí ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Mark tó bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ INEC lórí bí wọ́n ṣe yọ orúkọ rẹ̀ àti Rauf Aregbesola kúrò lójú òpó wọn gẹ́gẹ́ bí alága àti akọ̀wé ẹgbẹ́ náà jẹ́ ohun tí kò bá òfin mu, tó sì jẹ́ ìdúnkokò sí ìjọba àwaarawa Nàìjíríà.
Ó sọ pé ohun tó fojú hàn tí ìjọba ń ṣe ni láti ri pé kò sí olùdíje sípò ààrẹ láti ẹgbẹ́ òṣèlú kankan yàtọ̀ sí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu pẹ̀lú gbogbo ìnira táwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú lásìkò yìí.
Ó fi kun pe kò sí àníàní nípa àwọn tó jẹ́ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC nítorí àwọn ṣe àpérò ẹgbẹ́ láti yan àwọn adarí tuntun fún ẹgbẹ́ náà ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2025.
Ó ní àwọn pe INEC láti mójútó àpérò náà nígbà náà èyí tó mú kí INEC fi orúkọ òun àti ti Aregbesola sójú òpó wọn gẹ́gẹ́ bí alága àti akọ̀wé ẹgbẹ́ òṣèlú ADC.
Ó tẹ̀síwájú pé bí INEC ṣe tú ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tí wọ́n ní ó ṣokùnfà ìdí tí àwọn fi yọ orúkọ wọn kúrò lójú òpó wọn kò tọ̀nà àti pé wọ́n fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ jẹ́ kí ẹgbẹ́ náà wà láì ní adarí kankan ni.
Alága ADC náà kọminú pé ìgbésẹ̀ INEC kò fẹ́ kí àwọn kópa níbi ètò ìdìbò sípò gómìnà tó máa wáyé ní ìpínlẹ̀ Ekiti àti Ondo tó máa wáyé ní ọdún yìí ni wọ́n ṣe gbé ìgbésẹ̀ náà.
Ó ní ẹni tó gbé ẹjọ́ ló sílé ẹjọ́ tí INEC ń gba ìdájọ́ lórí rẹ̀ wọlé ìyẹn Nafiu Bala ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igbákejì alága ẹgbẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó dìbò yan àwọn, èyí tí àwọn sì ti fi lẹ́tà tó fi kọ̀wé fipò sílẹ̀ ránṣẹ́ sí INEC láti ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹjọ, ọdún 2025.
Ó wòye pé Bala mọ̀ wí pé wọ́n ti yan àwọn adarí míì fún ẹgbẹ́ ADC kó tó gba ilé ẹjọ́ lọ láti máa fẹ̀sùn kàn pé òun ni alága ẹgbẹ́ náà tọ́ sí.
Mark fẹ̀sùn kàn pé INEC ń tú ìdájọ́ ilé ẹjọ́ bí ẹni pé ìdájọ́ náà kò yé wọn, tó sì jẹ́ pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń tẹ ètò ìṣèjọba àwaarawa rì ní Nàìjíríà ni.
A máa tẹ̀síwájú pẹ̀lú àpérò wa, kò pọn dandan kí INEC wà níbẹ̀
Alága ẹgbẹ́ ADC náà tún sọ pé àwọn máa tẹ̀síwájú pẹ̀lú àpérò ẹgbẹ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe láàárín ọjọ́ Kẹsàn-án sí ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹrin, ọdún 2026.
Ó ní àwọn ti jẹ́ kí INEC mọ̀ nípa àpérò náà tí wọ́n sì ti jẹ́ kó yé àwọn pé àwọn ti gba ìwé náà wọlé.
Ó fi kun pé gbogbo ètò ẹgbẹ́ náà ló máa tẹ̀síwájú lábẹ́ ìdarí òun àti pé kò pọn dandan fún aṣojú INEC láti wà níbi àpérò àwọn.
APC sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí ADC: Kò sẹ́ni tó kó ba yín, ẹ̀yin lẹ ṣe ara yín lóhun
Bi ọrọ ẹgbẹ ADC yii ṣe n lọ lọwọ, ẹgbẹ APC to n ṣejọba lọwọ naa ti da si i.
APC fesi ni idahun si awijare ADC, pe wọn lo agbara wiwa ni ijọba fawọn ni. Ati pe APC fẹ ki Naijiria jẹ ẹgbẹ oloṣelu kan ṣoṣo ti i ṣe APC ni.
Ninu atẹjade ti Akọwe apapọ APC, Felix Morka, buwọlu l'Ọjọbọ lo ti ni ko sẹni to koba ADC, ẹgbẹ naa funra rẹ ni ko mọ bo ṣe n lọ.
APC ninu atẹjade naa sọ pe ẹgbẹ ti ko figba kan wa laye ni ADC.
"Bi wọn ṣe gbe e kalẹ ni ohun ti yoo ba a jẹ ti tẹle e wa, wọn ṣẹṣẹ n mọ ohun to ṣẹlẹ bayii ni.
"Nigba ti igun rẹ ti David Mark ati Rauf Aregbesola n dari ja wọnu ẹgbẹ naa bii apaṣẹ lai lero ati ati eto kankan, ti wọn fipa gba ẹgbẹ naa lọna to lodi si ofin rẹ, ti wọn tapa si ofin to de ilana tootọ, wọn ko mọ nigba yẹn."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade APC naa ṣalaye.
APC sọ pe ADC lo fi ọwọ ara rẹ kọ kadara rẹ bo ṣe fẹ.
Wọn tẹsiwaju pe bi INEC ṣe le wọn danu, wa ni ibamu pẹlu aṣẹ ile ẹjọ, o si ba ilana idibo ati ijọba awaarawa mu.
APC sọ pe ohun ti oju ẹgbẹ to ba fi waduwadu ṣe nnkan maa n ri ni ADC ri yẹn.
"Ai mọ ohun to kan lo mu ADC maa da ẹgbẹ APC lẹbi fun iṣubu wọn."
APC lo sọ bẹẹ ninu atẹjade wọn.
Ẹgbẹ APC sọ pe ADC ko ni nnkan kan to le ṣe ju atako lọ, wọn ni o jọ pe iṣẹ kan gboogi ti wọn dojukọ naa ni ṣiṣe atako awọn.
INEC naa fesi pada fun ADC
Awọn eeyan kan n sọ pe INEC ṣeka ni bo ṣe yọ awọn adari ADC kuro lori atẹ.
Awọn kan n sọ pe niṣe lo yẹ ki wọn yọ Ọjọgbọn Joash Amupitan to jẹ Alaga INEC kuro nipo rẹ, nitori o mọ ọn mọ kọ oju ADC si oorun alẹ ni.
Nigba ti INEC n fesi si eyi ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọru, eyi ti Adedayo Oketola ti i ṣe Akọwe iroyin fun Alaga INEC buwọlu, ajọ naa sọ pe awọn to n sọrọ yii lẹtọọ lati sọ ero ọkan wọn labẹ ofin.
INEC sọ pe ṣugbọn wọn ni lati mọ pe lara ofin orilẹede Naijiria ni idasilẹ ajọ eleto idibo yii naa wa.
Wọn fi kun un pe abala 157 ofin ọdun 1999 lo n ri si iyansipo, asiko ti alaga yoo lo ati iyọnipo alaga INEC.
Lafikun, ajọ naa sọ pe ko sẹni to mọ igun David Mark yii tẹlẹ, bi ko ṣe pe ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 ni wọn ṣẹṣẹ de.
Eyi si jẹ ọjọ keje lẹyin ti ẹjọ de ile ẹjọ giga.
INEC tẹsiwaju pe aṣẹ kootu kotẹmilọrun ti oun ati gbogbo eeyan ni Naijiria gbọdọ tẹle loun lo fun ADC, ki i ṣe titẹ ẹtọ wọn mọlẹ rara.
"INEC ki i ṣe ajọ to n pe fun ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo, a ti fi aaye ijọba awaarawa silẹ daadaa pẹlu bi awọn ẹgbẹ bii Democratic Leadership Alliance (DLA), Nigeria Democratic Congress (NDC) ati National Democratic Party (NDP) ṣe ṣẹṣẹ fi orukọ silẹ ti a si gba wọn.Eyi to mu apapọ ẹgbẹ oṣelu jẹ mejilelogun bayii (22)."
Ajọ yii sọ pe o ṣee ṣe ki awọn igbesẹ kan ma tẹ awọn eeyan lọrun nigba to ba waye lagbo oṣelu, ṣugbọn ohun to ṣe koko ni pe oun duro lori mimu idibo ti ko lẹjọ ninu dani.
Tinubu nìkan ló fẹ́ dá dupò ààrẹ bí Abacha, Dele Momodu àti Dino yarí lẹ́yìn tí INEC yọ orúkọ David Mark àti Aregbe gẹ́gẹ́ bí adarí ADC
Awuyewuye si n lori bi ajọ eleto idibo INEC ṣe ni awọn ti tẹle aṣẹ ile ẹjọ Kotẹmilọrun, eyi ti yọ orukọ awọn igbimọ amuṣẹṣe (National Working Committee) fun ẹgbẹ oṣelu ADC, labẹ idari alaga wọn; David Mark, kuro loju opo wọn.
Nigba to n sọ ero tiẹ lori ọrọ naa, gbajugbaja akoroyin, Dele Momodu, sọ pe igbesẹ INEC ko ṣẹyin erongba Aarẹ Bola Tinubu lati ri pe oun nikan ni yoo dupo ààrẹ lọdun 2027.
Momodu sọ pe igbesẹ ajọ eleto idibo Naijiria naa buru jai.
O ni nigba ti aarẹ to wa lori aleefa ti da dije ninu eto idibo ààrẹ ní aye Ogagun Sani Abacha to ti doloogbe.
Momodu ni "orilẹede wa ti bajẹ sii lati igba ti Ọgagun Ibrahim Babangida ti fagile esi idibo Ààrẹ June 12 eyi ti Oloye MKO Abiola jáwé olubori ninu rẹ.
Bi ajọ INEC ṣe sare fontẹ lu igun Nyesom Wike ninu ẹgbẹ oṣelu PDP sọ iru àjọ elétò ìdìbò ti INEC jẹ.
Oniruuru aawọ lo n lọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC lawọn ipinlẹ, ṣugbọn INEC ko sọ nkankan nipa rẹ.
O yami lẹnu pe APC si tun n bẹru pẹlu bi wọn ṣe fipa mu gbogbo awọn gomina lati darapọ mọ wọn.
Ni bayii, INEC tun ti sọ pe oun ko mọ ẹgbẹ ADC, ile ẹjọ nikan lo le yanju ọrọ naa bayii."
Momodu toun naa ti figba kan ri jẹ oludije sipo aarẹ sọ pe Ọlọrun si ju gbogbo ẹda lọ.
Ifinojoye ni Tinubu n fẹ, kii ṣe eto idibo lo jẹ kẹru maa ba APC - Dino Melaye
Sẹnẹtọ Dino Melaye naa ti sọ pe bawọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n darapọ mọ ADC lo n ba APC lẹru.
Melaye to sọrọ yii l'Ọjọbọ lori ileeṣẹ tẹlifísàn Channels TV ṣalaye pe ẹru n ba APC tori pe ẹgbẹ oṣelu ADC nikan lẹgbẹ alatako to le figa gbaga pẹlu rẹ ninu eto idibo gbogbogboo ọdun 2027.
"Wọn ti ri bí àwọn olóṣèlú ṣe n darapọ mọ ADC lati inu awọn ẹgbẹ oṣelu mii.
Iyalẹnu lo jẹ fun mi pe ẹru si n ba wọn lẹyin ti wọn ti ni gomina mejilelọgbọn," Melaye lo sọ bẹẹ.
O ni ọrọ ijọba awarawa lọrọ to wa nilẹ, kii ṣe nipa ẹgbẹ oṣelu ADC nikan.
Sẹnẹtọ Melaye sọ pe Tinubu fẹ ki wọn foun joye ni, ko fẹ eto idibo rara.
O ni eto ifinijoye ni Tinubu fẹ gbe wọ eto oṣelu Naijiria.
Ẹgbẹ́ ADC di àgùntàn tí kò ní Olùṣọ́, INEC yọ orúkọ Rauf Aregbesola, David Mark kúrò bíi adarí ẹgbẹ́, ariwo sọ
Pẹlu bi wọn ṣe ni awọn tẹle aṣẹ ile ẹjọ Kotẹmilọrun, ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ti yọ orukọ awọn igbimọ amuṣẹṣe (National Working Committee) fun ẹgbẹ oṣelu ADC, labẹ idari alaga wọn; David Mark, kuro loju opo wọn.
Eyi tumọ si pe orukọ Rauf Aregbesola ti i ṣe Akọwe apapọ ẹgbẹ ati David Mark to jẹ alaga apapọ gan-an atawọn ọmọ ADC mi-in ko si loju opo INEC mọ, wọn ko da wọn mọ labẹ ofin.
Ajọ INEC tun tẹsiwaju pe oun ko ni I gba ohunkohun wọle latọdọ awọn eeyan yii mọ, bẹẹ ni oun ko ni I da si ipade yowu ti wọn ba n ṣe lorukọ ADC.
INEC sọ pe bẹẹ ni yoo wa titi digba ti ilẹ ẹjọ giga ilu Abuja ba da ẹjọ naa.
Gbogbo eyi jẹ jade ninu atẹjade kan ti Mohammed Haruna to n ri si ikede ati ilanilọye ni INEC fi sita l'Abuja l'Ọjọru ana.
O ni igbesẹ yii wa lati ma ṣe tako ohun ti ile ẹjọ n fẹ ko too di pe wọn yoo gbọ ẹjọ naa tan.
Wọn fi awọn lẹta ti wọn gba lati kootu gbe igbesẹ yii lẹsẹ, eyi to kilọ pe INEC gbọdọ yọ orukọ Aregbe, Mark, Nafiu Bala Gombe toun naa fẹ di Alaga apapọ ADC atawọn yoku wọn danu.
Wọn fi kun un pe awọn ti ọrọ kan ninu ẹgbẹ ni wọn kọwe ifisun.
Ki lo de ti INEC gbe igbesẹ yii?
"Niwọn igba ti orukọ awọn igbimọ amuṣẹṣe ti Seneto David Mark n dari ti wa loju opo wa lati ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 (Ọjọ keje lẹyin ipẹjọ) INEC yoo yọ orukọ wọn kuro loju opo wa bi aṣẹ ile ẹjọ Kotẹmilọrun, lati tẹle ohun ti kootu n fẹ titi igbẹjọ.
"Bẹẹ ni INEC ṣalaye ninu atẹjade naa.
Ajọ naa sọ pe oun yoo maa tẹsiwaju ninu otitọ.
O rọ ẹgbẹ ADC lati ma ṣe ohun ti yoo koba alakalẹ eto ti INEC gbe jade fun idibo ọdun 2027.
Alaye naa tẹsiwaju pe ile ẹjọ ko fi gbogbo ara gba David Mark bii Alaga apapọ ADC, eyi to si gbọdọ yanju ki ajọ eleto idibo to le gba a wọle.
Tẹ o ba gbagbe, ẹgbẹ ADC yii ni ibi isadi keji ti awọn oloṣelu ti ko fẹ darapọ mọ APC n sa si latigba ti rogbodiyan ti n ṣẹlẹ ninu PDP, ti ẹgbẹ Alaburada si ti pin si igun ọtọọtọ.
Ki ni ADC, PDP ati awọn eeyan Peter Obi wi?
Nigba ti won n fesi si igbesẹ INEC, Agbẹnusọ ADC; Bolaji Abdullahi ati Ini Ini Ememobong fun PDP, sọ pe INEC ṣe bẹẹ lati le sọ Naijiria di ilu ẹlẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo ni.
Wọn ni wọn ṣe bẹẹ lati koba ijọba awarawa ni, bakan naa ni wọn ni ijọba APC lo n da àrà yii.
O yẹ ki gbogbo awọn alatilẹyin ẹgbẹ alatako dide si ọrọ yii bi wọn ṣe sọ.
Bakan naa ni Alakooso apapọ fun Obidient Movement ti I ṣe awọn alatilẹyin Peter Obi, Yunusa Tanko, kilọ pe ipinnu to le da rogbodiyan silẹ ni INEC ṣe.
O ni ohun to le da wahala silẹ ni bi ajọ yii ba pinnu lati maa ṣe iru eyi.
Bolaji Abdullahi tẹsiwaju ni tiẹ pe ki i ṣe ile ejọ Kotẹmilọrun ni INEC tẹle, o ni awuruju ni awijare naa.
O ni David Mark to wa nipo alaga apapọ lo yẹ ki wọn fi silẹ si aaye rẹ.
Agbẹnusọ ADC naa sọ pe awọn ko ni I gbe etekete kankan wọle fun ajọ INEC.