Mi ò lè dìbò fún Peter Obi lọ́dún 2027, bẹ́ẹ̀ni kò sí aáwọ̀ láàrin wa - Gbadebo Rhodes-Vivour

Àkọlé fídíò, Mi ò lè dìbò fún Peter Obi lọ́dún 2027, bẹ́ẹ̀ni kò sí aáwọ̀ láàrin wa - Gbadebo Rhodes-Vivour
Mi ò lè dìbò fún Peter Obi lọ́dún 2027, bẹ́ẹ̀ni kò sí aáwọ̀ láàrin wa - Gbadebo Rhodes-Vivour
Published

Gbadebo Rhodes-Vivour, tii se oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbe oselu African Democratic Congress, ADC nipinlẹ Eko, ti salaye nipa ajọsepọ rẹ lọwọ lọwọ pẹlu Peter Obi, tii se oludije sipo aarẹ ninu ẹgbẹ oselu National Democratic Party, NDC.

Rhodes-Vivour ni ko si aawọ kankan laarin oun ati Peter Obi nitori Asiwaju ati ọga oun si ni ninu oselu.

Rhodes-Vivour sisọ loju ọrọ yii lasiko to n kopa ninu ifọrọwerọ kan pelu BBC News Yoruba.

Amọ o ni oludije aarẹ ti oun n tẹle lẹyin lasiko yii ni Atiku Abubakar to n soju ẹgbẹ oselu ADC tori ẹgbẹ oselu ko pa oun ati Peter Obi papọ.

Gbadebo Rhodes-Vivour salaye pe "Nigba akọkọ ti mo dije fun ipo oselu lati lọ sile asofin agba, Atiku Abubakar lo n dije fun ipo aarẹ, ti Peter Obi si jẹ igba keji rẹ.

Nibayi ti awọn mejeeji n dije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu ọtọọtọ, ẹgbẹ oselu ADC t imo wa, ni maa se, tori naa, Atiku ni oludije sipo aarẹ t imo n sugba rẹ.

Awọn oludije sipo aarẹ mejeeji ni wọn jẹ ẹni ọwọ, ti n ko le sọrọ abuku si, koda, nigba ti mo wa ninu ẹ́gbẹ oselu Labour, mo lọ si Adamawa nibi iwuye Atiku.

Oun si lo n gba awọn eeyan si isẹ julọ nipinlẹ naa tori ọpọlọpọ ileesẹ to ti da silẹ nipinlẹ naa, mo si nifẹ si eleyi tori ọpọ awọn oloselu wa nilẹ yii lo ni owo gọbọi amọ ti wọn n ko lọ soke okun.