You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé ó yẹ kí àwọn obìnrin máa fi ẹ̀yìn sùn tí wọ́n bá fẹ́ bímọ?
- Author, Lucy Sherriff
- Role, BBC Future
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun sẹyin, kaakiri agbaye, ilana ti obinrin n gba bimọ n ṣe atilẹyin fun wọn.
Wọn le kunle, wọn le duro mọ aga tabi ki wọn loṣoo. Koda, liloṣoo yẹn le jẹ ki aaye to wa ni ẹgbẹ wọn fẹ si i ni ida 2.5cm (1in), bẹẹ ni yoo rọrun lati bi wẹrẹ.
Ki lo wa ṣẹlẹ lode oni ti ọpọ obinrin n takaaka sori ibusun ti wọn ba fẹ bimọ?
"Kinni kan kari laaarin awọn eeyan ati awọn oloyun, aimọkan ni nnkan ọhun, nipa ibimọ si ni."
Janet Balaskas, oludasilẹ Active Birth Centre ni UK, to tun jẹ onkọwe nipa bi obinrin ṣe le gba akoso asiko ibimọ rẹ lo sọrọ yii.
Ni 1982, Balaskas gbe iwe kan jade lori ibimọ, to di opo mulero ileeṣẹ rẹ.
"Kaakiri agbaye, ati fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun, ilana ikunlẹ tabi ki wọn loṣoo ni obinrin n gba bimọ loju ẹsẹ. Ko yọ ẹya tabi ilu kan silẹ, ilana kan yii lo kari."
Bẹẹ lo wa ninu iwe ti Balaskas kọ ni 1982.
"Ọpọ obinrin ni awọn ilu to ti gunke agba ni wọn maa n dubulẹ bimọ ni tiwọn. Balaskas lo sọ bẹẹ.
"Ilana yii ko ba laakaye mu, o maa n mu ibimọ lọju ni, o si maa n sọ ohun to yẹ ko waye nirọrun di ohun ti awọn dokita yoo maa ṣe akitiyan le lori, obinrin to si n rọbi naa yoo kan wa nibẹ bii alaisi ni.
Bẹẹ ni Balaskas tẹsiwaju.
"Ko si ẹya iṣeda kankan to n lo iru ilana ti ko daa yii mọ lasiko yii, afi eeyan nikan."
Awọn akọṣẹmọṣẹ yoku naa gba ohun ti Balaskas sọ yii wọle.
"Koda, ki obinrin maa rọbi nidubulẹ jẹ ohun ti wọn n fi ọlaju ṣe lasiko yii."
Hannah Dahlen, Ọjọgbọn ninu gbigba ẹbi ọmọ ni Australia's Western Sydney University lo kọ ọrọ yii kalẹ ni 2013.
Oyun nini bii 'aisan '
Lọdun bii ọọdunrun si irinwo ọdun ti obinrin n bimọ pẹlu idubulẹ, ọkunrin ọmọ ilẹ Faranse kan; François Mauriceau lo fa a.
Oun lo ni yoo rọ wọn lọrun bi won ba dubulẹ, yoo si tun rọrun fun agbẹbi ọkunrín to n gbebi oloyun naa (Wọn ti da ẹgbẹ kan silẹ nigba naa ti wọn fi fẹ dẹkun awọn agbẹbi obinrin lati maa gbẹbi oloyun).
Mauriceau wo oyun nini gẹgẹ bii aisan.
Ninu iwe rẹ to kọ ni 1668, eyi to pe ni 'The diseases of women with child and in child-bed,' Mauriceau gba wọn nimọran pe : "Ọna to dara ju ni ki eeyan gba ẹbi wọn lori ibusun, ki wọn si ṣẹgun gbigbe kiri lẹyin ibimọ."
Ṣugbọn awọn onimo kan ko gba eyi wọle, wọn ni o ṣee ṣe ko jẹ ọkunrin ara Faranse miran toun naa wa laye lasiko Mauceau, iyẹn – King Louis XIV lo wa nidii ayipada ilana ibimọ yii.
"Nigba ti iroyin ti ro o pe Louis XIV fẹran lati maa wo awọn obinrin lasiko ti wọn ba n rọbi lọwọ, inu bi i nigba ti wọn bẹrẹ ilana ikunlẹ ati rirọ mọ aga bi wọn ba fẹ bimọ, oun lo si bẹrẹ si i kede idubulẹ."
Lauren Dundes, Ọjọgbọn kan ninu imọ awujọ (Sociology) ni McDaniel College,Maryland, US, lo kọ ọ sinu iwe ẹ to ṣe ni 1987, eyi ti i ṣe ayipada ninu ipo ibimọ.
"Louis XIV's to fẹ ohun to fẹ le jẹ idi kan ti idubulẹ bimọ ṣe n waye."
Ohun yowu to fa ki obinrin maa dubulẹ bimọ , ohun to foju han ni pe aṣa naa gbilẹ, ko si daa to fun wọn .
"Ibimọ ti di ohun ti wọn n ṣe lọna ọtọọtọ, bii ki wọn gba ẹbi oloyun ninu ile – eyi wa fun awọn obinrin to fẹ bimọ nilana to rọ wọn lọrun to si jẹ ilana Iṣẹda. "
Balaskas lo ṣalaye bẹẹ.
Sayẹnsi fidi ẹ mulẹ
Idi pataki tawọn obinrin fi n bimọ nilana iloṣoo tabi ikunlẹ fun ọpọ ọdun ko ruju rara: Ohun kan to wa nibẹ ni pe agbara maa n wa fun wọn lati gbin sisalẹ pẹlu ipo ti wọn wa.
Ọmọ ni lati maa tọ ọna iya rẹ bọ nipasẹ oju ara iya, bi iya si ṣe duro, kunlẹ tabi loṣoo yoo ran eyi lọwọ.
O ti fi han pe bi wọn ba fi awon obinrin silẹ lati mu eyi to wu wọn, wọn yoo lo ọgbọn inu lati duro si ọwọ iwaju lasiko ibimọ, wọn ko ni i fi sẹyin.
Wọn yoo mu awọn ipo bii ibẹrẹ, ki wọn kunlẹ pẹlu nina ọwọ siwaju, tabi ki wọn loṣoo ki wọn di aga mu.
Iwadii kan ni 2013, ṣayẹwo mẹẹẹdọgbọn fun obinrin ẹgbẹrun marun-un o le ni igba (5,200) abajade rẹ ni pe awọn to bimọ nikunlẹ tabi liloṣo din ewu iṣẹ abẹ ṣiṣe ku.
Yatọ si awon to jẹ niṣe ni wọn dubulẹ lasiko igbẹbi, wọn ko lo ilana to n din bi ọmọ ṣe maa n mu inira ba obinrin ku (epidural), bẹẹ lo din ewu ki ọmọ wọn lọ si yara itọju ọtọ fun ọmọde (neonatal unit) ku.
"Ki obinrin loṣoo tabi kunlẹ lasiko to n rọbi ni anfaani to pọ fun iya ati ọmọ"
Dahlen lo ṣe akọsilẹ naa ni 2013.
O yannana awọn anfaani to pọ, titi kan bi ọmo yoo ṣe tete mu obinrin to ba n rọbi, ti inira yoo dinku fun un ati bi eemi yoo ṣe de ọdọ ọmọ naa daadaa ninu ile ọmọ iya rẹ.
Ni 2011, Dahlen ati awọn akẹgbẹ rẹ ṣe iwadii lori awọn obinrin to n rọbi, lati mọ boya ipo ti wọn yan lati bimọ ni nnkan lati ṣe lori ibimọ .
Nnkan meji ni wọn wo, ibi ti obinrin ti n bimọ, nibi ti awọn nnkan eelo ti wọn nilo gbogbo wa, ati yara igbẹbi ileewosan to jẹ bẹẹdi nikan lo wa nibẹ.
Wọn ri i pe awọn obinrin to wa nile igbebi ti wọn ti n kunlẹ yoo maa tẹle ilana yii fun ipele akọkọ ati ikeji igbẹbi. Wọn jẹ ida mejilelọgọrin (82%)
Yatọ si awọn to wa ni wọọdu ti ibusun wa nile iwosan, ti awọn jẹ ida jẹ mẹẹẹdọgbọn (25% ).
Itaniji ti wa bayii ni awọn orilẹede to ti gunke agba lori ilana ọmọ bibi, Balaskas lo sọ bẹẹ
Ilana to le jẹ ki iya rin ko yan fanda bo ṣe wu u lasiko to n rọbi lọwọ ni ikunlẹ tabi liloṣo, yatọ si ki obinrin dubulẹ ko takaaka ko si maa wo ẹrọ oyinbo.
Bẹẹ si ni awọn to n ṣiṣẹ abẹ n pọ si i.
Balaskas lo tẹsiwaju bẹẹ.
Ni UK, ilana ibimọ ti yi pada.
Amọran lati UK National Institute for Health and Care Excellence (NICE), rọ awọn obinrn to n rọbi lati ma ṣe dubulẹ nigba ti ọmọ ti mu wọn de ipele keji, wọn ni ki wọn maa lo ilana mi-in to ba rọ wọn lọrun.
Ọgbọn ju agbara lọ, bawọn obinrin ba ṣe n kẹkọọ si i nipa ilana ọmọ bibi ti wọn ba yan laayo, bẹẹ ni yoo ṣe rọrun si lati mu eyi to ba daa lojuu wọn.
"Kikọ awọn obinrin lẹkọọ nipa ibimọ lawujọ yoo maa ṣe anfaani ni gbogbo igba." Eileen Hutton, agbẹbi to di olukọni ni Canada's McMaster University, lo sọ bẹẹ.
"Ti a ba wo ibimọ lori amohunmaworan tabi ninu fiimu, yoo ye wa pe ilana ibimọ ko i ri bo ṣe yẹ ko ri. Bi a ba ṣe ohun to le tako eyi, yoo ran wa lọwọ pupọ."