You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn ojú pópó tí yóò wà ní títì pa nílùú Eko lásìkò àbẹ̀wò Tinubu bẹ̀rẹ̀ láti òní
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede awọn oju popo ti yoo wa ni titi pa lasiko abẹwo ọlọjọ meji ti Aarẹ Bola Tinubu n ṣe si ilu Eko bẹrẹ lati oni ọjọ kẹjọ oṣu Kẹrin yii.
Kọmiṣọna fun igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Oluwaseun Osiyemi, sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe igbesẹ yii waye lati le jẹ ki eto ifilọlẹ awọn akanṣẹ iṣẹ ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ṣe lọ ni irọwọ rọsẹ.
Kọmiṣọna ni oni Ọjọru ọjọ kẹjọ oṣu Kẹrin yii ati ọla Ọjọbọ ọjọ kẹsan an ni Tinubu yoo ṣi awọn akanṣẹ iṣẹ naa ti ijọba ipinlẹ Eko ti ṣe.
Ọgbẹni Osiyemi rọ awọn awakọ lati yago fawọn ọna ti yoo wa ni titi pa, ki wọn si lo awọn ọna mii ti wọn le gba eyi ti ijọba ti kede.
Kọmiṣọna fun igbokegbodo ọkọ sọ pe oni Ọjọru ni Tinubu yoo ṣi afara Opebi-Mende.
O ni laarin aago mẹsan an aarọ si ago kan ọsan ni eto naa yoo waye.
Ọgbẹni Osiyemi sọ pe eto naa yoo ṣakoba fun lilọ bibọ ọkọ lawọn agbegbe bii Opebi-Allen, Ikeja ati Ojota.
O wa rọ awọn awakọ lati wa ọna mii gba lawọn agbegbe yii lasiko eto ifilọlẹ afara naa.
Kọmiṣọna tun sọ pe l'Ọjọru ni aarẹ yoo ṣi ile ẹkọ nla Tolu Schools, eyi ti yoo ṣakoba fun lilọ bibọ ọkọ lagbegbe Ajegunle ati Apapa.
O rọ awọn awakọ lati wa ọna mii gba laarin ago mẹsan an si ago kan l'Ọjọbọ lagbegbe Ajegunle ati Olodi Apapa.
Aarẹ Tinubu yoo tun lọ fun eto mii ti yoo waye laarin ago mẹrin si ago meje irọlẹ nile itura Eko Hotel to lagbegbe Victoria Island.
Osiyemi rọ awọn awakọ lati yago fun agbegbe naa ki wọn ma ba ri idaduro.
Kọmiṣọna ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ ajọ LASTMA to n ri si lilọ bibọ ọkọ ti wa loju popo kaakiri ilu Eko lati dari igbokegbodo ọkọ lasiko abẹwo aarẹ.
Ọgbẹni Osiyemi wa rọ awọn olugbe ilu Eko lati fọwọ ṣowọ pọ pẹlu ajọ LASTMA lasiko abẹwo Aarẹ Tinubu.