You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòótọ́ ni ìjà wà láàrin Tinubu àti Sanwo-Olu? Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko sàlàyé
Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe irọ ni iroyin to sọ pe ija si wa laarin Aarẹ Bola Tinubu ati Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko.
Kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso, lo sọrọ yii lori eto Morning Brief ileeṣẹ tẹlifisan Channels TV laarọ oni ọjọ Iṣẹgun.
Omotoso ni ''bawo ni baba ṣe fẹ sọ pe ko si ọjọ iwaju fun awọn ara ile oun.
Baba ni Aarẹ Tinubu jẹ fun Sanwo-Olu, ati pe ahesọ ọrọ lasan ni gbogbo nnkan tawọn eeyan n gbe kiri.
Nnkan ti awọn eeyan kan n ro ninu ọkan wọn ni wọn n sọ sita ti wọn si n gbe kiri.''
Omotoso ni Tinubu ko sọ fun ẹnikẹni wi pe inu oun ko dun si Sanwo-Olu.
O ni aarẹ ko ni gbero lati ṣabẹwo si ipinlẹ Eko bẹrẹ lati ọla Ọjọru ọjọ kẹjọ si ọjọ kẹsan an oṣu yii.
Kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ Eko sọ pe Tinubu lẹtọọ lati lọ sibi kibi to ba wu u, o ni ko si bi aarẹ yoo ṣe ṣabẹwo si ipinlẹ ti ko dunnu si gomina rẹ.
Lori bo ya Tinubu ti buwọlu ẹni ti yoo rọpo Sanwo-Olu, Omotoso ni ọrọ ko tii de ibẹ.
O ni awọn eeyan kan lo kan n sọ ahesọ ọrọ kaakiri lori itakun ayelujara.
Omotoso sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC yoo sọ ẹni ti yoo rọpo Sanwo-Olu ti asiko ba ti to.
Kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ Eko tun sọ diẹ nipa awọn akanṣe iṣẹ ti Tinubu yoo ṣi lasiko abẹwo ọlọjọ meji ti yoo ṣe si ipinlẹ Eko.
Omotoso sọ pe afara kan to lamilaaka wa lara awọn iṣẹ ti Tinubu n bọ wa ṣe ifilọlẹ rẹ niluu Eko.
O ni awọn akanṣe iṣẹ mii naa wa ti Tinubu yoo ṣi lasiko abẹwo ọlọjọ meji rẹ si ipinlẹ Eko lati Ọjọru ọjọ kẹjọ oṣu Kẹrin yii.