Mi ò bá Makinde àti Olubadan jà, ìdí rèé táwọn èèyàn kò fi rí mi pọ̀ mọ́ Gómìnà àti Ọba Ladoja - Alaafin

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alaafin Oyo, Ọba Akeem Owoade, ti sọ pe irọ nla ni iroyin to ni ija wa laarin oun ati Olubdan ti ilẹ Ibadan ati Gomina Seyi Makinde ipinlọ Oyo.

Alaafin ni oun ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu Ọba Rashidi Ladoja ati Gomina ipinlẹ Oyo.

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ niluu Oyo, Alaafin Owoade ni ko si ede-ai-yede kankan laari oun ati Ọba Ladoja ati Makinde.

Kabiyesi naa sọ pe ti nnkankan ba tiẹ wa, awọn yoo yanju rẹ laarin ara awọn ti ẹnikẹni ko si ni i gbọ.

''Mi o ni idi nnkankan lati tako ijọba ipinlẹ Oyo, Omoluabi ni gomina wa.

Mo maa lọ ba a sọrọ ti nnkankan ba tiẹ ṣuyọ lati jiroro le lori.

Bakan naa, mo ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu Olubadan, ko si ede-ai-yede kankan laarin wa,'' Alaafin Oyo lo sọ bẹẹ.

Ọba Owoade ni awọn oniroyin ori ayelujara kan ti ko bikita lo n gbe iroyin ofege kiri nipa itẹ Alaafin.

''Mo nawọ si Olubadan, amọ, o ṣalaye fun mi pe oun ko ri ọwọ mi''

Nigba to n sọrọ nipa bii awọn eeyan ko ṣe maa ri oun pọ mọ Olubadan ati gomina ipinlẹ Oyo fun igba diẹ bayii, Alaafin ni oun ni ailera diẹ lo fa a.

Kabiyesi wa sọ pe oun yoo maa yọju sibi gbogbo eto to ba yẹ koun wa nibẹ bayii.

Ori-ade naa sọ pe iṣẹlẹ aibọwọ pẹlu Olubadan lode kan to pa wọn pọ lo jẹ kawọn eeyan maa gbe iroyin ofege kiri.

Alaafin Owoade sọ pe oun ko mọ-ọn mọ ṣe bẹẹ, ati wi pe oun ati Olubadan ti pari ọrọ naa.

''Mo nawọ si Olubadan, amọ, o ṣalaye fun mi pe oun ko ri ọwọ mi.

A ti jọ sọrọ lẹyin igba naa, mi o fi ṣe ibinu rara,'' Alaafin lo sọ bẹẹ.

Alaafin ni oun yoo tẹsiwaju lati maa wa alaafia, iṣọkan ati idagbasoke awujọ, nigba to rọ awọn eeyan lati kọ eti ikun si ahesọ ọrọ tawọn kan maa n gbe kiri.