Àwọn afurasí darandaran ṣá àgbẹ̀ sínú oko rẹ̀ l'Ogbomoso lẹ́yìn tó ní wọn kò gbọdọ̀ da ẹran níbẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

‎Isẹlẹ naa lo waye lagbegbe Igbopupa, Yawota lagbegbe lẹgbẹ Iiu Alawusa ni ijọba ibilẹ Orire.

‎Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti tẹ awọn afurasi Fulani darandaran mẹta to sẹkupa agbẹ kan Ọgbeni Kehinde Ojo ni agbegbe ijoba ibilẹ Orire, nipinlẹ Oyo.

‎Awọn afurasi darandaran naa ni wọn fẹ fi awọn maalu wọn jẹ oko oloogbe Kehinde lọjọ Isinmi, ọjọ karun un, oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii, amọ o kọ jale.

‎Agbẹ naa lọ ṣere lo si oko re lati lọ wo awọn ẹgẹ ti o gbin sibẹ ni nnkan bii aago mẹrin irolẹ ọjọ Isinmi ọhun to si ba awọn afurasi darandaran naa ninu oko rẹ, ki awọn afurasi darandaran naa to ṣa ni ada.

‎Ile iṣe BBC News Yoruba ri gbọ wi pe wọn gbiyanju lati gbẹ agbẹ naa lọ si ile iwosan lẹyin ti awọn afurasi darandaran naa ṣa ni ada tan, ṣugbọn o padanu ẹmi rẹ ni bii aago meji aarọ ọjọ Aje.

‎Awon afurasi darandaran mẹta ti wa ni atimole lori iṣẹlẹ naa bayii.

‎Alukoro ile iṣẹ ọlọpa ipinlẹ Oyo, Olayinka Alayande fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin.

‎Alayande ṣalaye siwaju si pe ni kete ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn ti fi to awọn agbofinro to wa ni ijọba ibilẹ Orire leti.

‎Alayande tesiwaju wi pe ọgbẹ pọ lara oloogbe naa, eleyi lo si faa to fi padanu ẹmi rẹ.

‎Oni ile iṣe ọlọpa Ipinlẹ Oyon tesiwaju ninu iwaadi rẹ ti yoo si fi imu awọn afurtasi naa danrin.

‎Ti ẹ ko ba gbagbe, kii ṣe igba akọkọ ti irufẹ iṣẹlẹ yii yoo sẹlẹ nilu Ogbomoso ree.

Lọdun 2024 ni awọn afurasi Fulani darandaran kan sẹkupa pasitọ Segun Adegboyega ninu oko rẹ not wa lagbegbe Gege, to wa ni opopona Ogbomoso si Iseyin lasiko to n kilọ fawọn darandaran to da ẹran jẹ oko rẹ ki wọn to gun un lọbẹ pa.