'Bí mo ṣe kó Ebola ní Nàìjíríà' - Arákùnrin tí orí kó yọ lọ́wọ́ Ebola ṣàlàyé ohun tójú rẹ̀ rí

Arakunrin kan wo awo oju wọ aṣọ funfun.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ikupani ni aisan Ebola, ọkan lara awọn aisan to saba maa n ja siku bi eeyan ba lugbadi rẹ ni.

Lorilẹede Naijiria yii, ọdun 2014 ni a kọkọ gburoo rẹ, ko too tun ṣẹyọ bayii niluu Abuja lati ara arinrinajo kan to wa lati Uganda.

Amọ ti ọdun 2014 naa ko ṣai mu ẹmi awọn kan lọ, bii Dokita Stella Adadevoh to fi ẹmi ara rẹ jin, ati ọdọbinrin nọọsi kan torukọ rẹ n jẹ Justina Ejelonu Obioma.

Inu oyun oṣu meji ni Justina wa to fi lugbadi Ebola latara Patrick Sawyer ti oun ati Dokita Adadevoh tọju, iyẹn ọmọ Liberia to gbe arun naa wọlu Eko nigba yẹn.

Ọkọ nọọsi naa; Chukwuemeka Akagha Dennis, ṣalaye boun ṣe rin in ti aisan naa ko fi gbẹmi oun bo ṣe mu Justina lọ toyun-toyun.

Àkọlé fídíò, Ohun to yẹ ki o mọ nipa Ẹbola

Bawo ni Dennis ṣe lugbadi Ebola?

Chukwuemeka Akagha Dennis, onimọ nipa ẹrọ igbalode, ṣalaye fun BBC pe lati ara iyawo oun to jẹ nọọsi ni oun ti ko arun naa.

O ṣalaye pe lẹyin ti iyawo oun ko Ebola lati ara Patrick Sawyer lo ko o ran oun.

"Mo fẹran iyawo mi gan-an, mo si fẹẹ ṣegbeyawo pẹlu rẹ ka si jọ bẹrẹ idile ni, ṣugbọn o ku nipasẹ Ebola.

"Inu oyun lo wa nigba yẹn, emi gan-an o dẹ mọ pe mo ti ko arun naa lara rẹ. Ko dẹrun rara nigba yẹn pẹlu bawọn eeyan ṣe n dẹyẹ si idile mi.

"Mo la awọn idojukọ naa kọja mo si bori wọn, nitori ẹ lo ṣe jẹ pe nigba ti mo wa nibi ti wọn fi mi pamọ si fun itọju, awọn to ti bọ lọwọ Ebola ni mo n wa kiri.

"Mo n fẹ lati gbọ ohun to ṣẹlẹ si wọn ati bi wọn ṣe ṣẹgun rẹ, emi naa wa n nigbagbọ pe mo le ma ku."

Dennis sọ fun BBC pe bo tilẹ jẹ pe oun ko pada ku iku Ebola, oun ti figba kan pa ọkan oun pọ, oun si ti gba pe to ba ja siku, o pari naa niyẹn, nigba toun ti ri i pe iku ni ti iyawo oun pada ja si.

Bi wọn ṣe pade ki Ebola too tu wọn ka

Chukwuemeka Akagha Dennis lapa osi, pẹlu iyawo rẹ, Oloogbe Justina Ejelonu ti Ebola pa ni 2014
Àkọlé àwòrán, Chukwuemeka Akagha Dennis lapa osi, pẹlu iyawo rẹ, Oloogbe Justina Ejelonu ti Ebola pa

Ọkunrin yii ṣalaye pe ori redio loun ti kọkọ gbọ ohùn iyawo oun, koun too pada ri i soju.

O ni ko dẹrun lati ba eeyan sọrọ lori ayelujara lasiko naa ti I ṣe 2010 si 2011, nitori awon oju opo bii Whatsapp ko si nigba yẹn.

"Ori eto redio kan ti wọn ti maa n sọrọ ifẹ ni mo ti pade iyawo mi. O si tiẹ ti maa n wu mi tẹlẹ lati fẹ obinrin to ba jẹ nọọsi, amọ ki i ṣe nitori iyẹn nikan ni mo ṣe fẹ ẹ, mo fẹran rẹ gan-an."

Dennis sọ pe iriri Ebola toun ri ti mu ọkan oun le, o ni oun ki i bẹru ohunkohun mọ.

Ọkunrin naa sọ pe ohun to le mu oun ye Ebola ni 2014, ko sohun toun ko le koju mọ.

Bi o ṣe le dena Ebola

Aworan atọwọda lori idanilẹkọ nipa bi aarun Ebola ṣe maa n ṣiṣẹ ninu agọ ara.
  • Maa fọ ọwọ rẹ deede pẹlu omi to mọ ati ọsẹ.
  • Ṣọra fun omi ara ẹni to ni arun naa; lara omi ara bẹẹ ni itọ́, ìtọ̀, ẹjẹ ati igbọnsẹ wọn.
  • Da ara rẹ lẹkọọ nipa awọn apẹrẹ Ebola ki o le mọ bi o ṣe le tete yẹra fun un.
  • Tẹlẹ imọran awọn eleto ilera ti o ba ni nnkan lati ṣe pẹlu ẹni to ni arun naa.Ṣọra fun fifi ọwọ kan awọn ẹranko bii Adan to ti ku.
  • Yẹra fun pinpin awọn nnkan ti omi ara ẹlomii n kan bii aṣọ, abẹrẹ atawọn nnkan mii.
  • Ma ṣe itọju ẹni to ni Ebola funra rẹ lai ki i ṣe onimọ eto ilera tabi lai ni imọ itọju alaarun naa ṣaaju.
  • Oku ti Ebola pa gbọdọ wa ninu apo ti wọn maa n gbe oku si, awọn to fẹẹ sin in si gbọdọ wọṣọ to wa fun isinku bẹẹ.

Amọ bi o ba tete kẹẹfin awọn apẹẹrẹ kan ti o si gbe igbesẹ to yẹ, o ṣee ṣe ki eeyan ye Ebola bawọn onimọ nipa ilera ṣe sọ.