Gbájúẹ̀ oúnjẹ olówópọ́ọ́kú dá wàhálà sílẹ̀ l'Osun, àwọn kan ní àwọn yóò tún tẹ́rí síi lọ́jọ́ ìwájú, àwọn yóò tún tẹ́rí síi
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Ọpọ eeyan ti ko sinu niluu Osogbo, nipinlẹ Osun lẹyin ti ileeṣẹ kan to ni oun n ta irẹsi, sẹmo ati ororo ni owo perete lu wọn ni jibiti.
Awọn eeyan naa ti sọ fun BBC pe ọwọngogo ounjẹ to gbode ati bi nnkan ṣe gbowo lori lo faa ti awọn fi ko sọwọ awọn onijibit naa.
BBC Yoruba lọ siluu Osogbo nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, ohun ti a gbọ ninu iwadi wa ni pe, ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Food Global Initiative to wọ ilu lọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan an ọdun yii lo ṣọṣẹ naa.
A gbọ pe ileeṣẹ naa sọ fun awọn eeyan naa pe awọn wọ ilu lati ran wọn lọwọ lori ọrọ ounjẹ bii irẹsi, ororo, sẹmo ati bẹẹbẹẹ lọ.






















