Ẹ jẹ́ kí n padà sí sinimá ṣiṣe, ó hàn pé mí ò kí ń ṣe ẹlẹ́ṣẹ́ – Nkechi Blessing sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jàn án mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing/screenshot
Gbajumọ oṣere tiata Nkechi Blessing Sunday to wọ agbo ẹṣẹ kikan lọjọbọ ti jade lati ṣalaye pe bi o tilẹ jẹ pe oun fidirẹmi ninu idije ẹṣẹ kikan naa, o daju pe oun ṣi ni olubori to tayọ.
Ninu atẹjade to fi si oju opo Instagram rẹ, Nkechi Blessing ṣalaye pe ọjọ meji loun fi ṣe igbaradi fun ija naa sibẹ oun le fọwọ sọya pe oun tayọ.
Nkechi Blessing tun ṣalaye iriri ọtun ni oja naa jẹ fun oun pẹlu bi o ṣe jẹ igba akọkọ ti oun maa gbe ọwọ soke lati na ọmọlakeji oun.
O fi kun un pe gbogbo awọn to n kan sara si oun atawọn to n fi oun ṣe yẹyẹ loun ri ti oun si n dupẹ lọwọ gbogbo wọn.
O ni lootọ mi o bori ninu ija naa ṣugbọn 'ẹmi akin lati ja gẹgẹbi jagunjagun niwaju ẹgbẹlẹgbẹ eeyan' jẹ nnkan kan ti oun ko le gbagbe laelae.
Bakan naa lo kan sara si iya rẹ fun ẹmi akikankanju to gbin si inu oun. O ni bi anfani lati ja ẹsẹ ba tun yọju lẹẹkan sii, oun yoo ja o
Nkechi Blessing ṣubú yakata, Phyna fẹ̀ṣẹ́ fọ́ ọ lẹ́nu gba ẹ̀bùn ₦50m

Oríṣun àwòrán, X/PoojaMedia
Ẹni to gbegba oroke ninu idije Big Brother Naija nigba kan ri, Ijeoma Josephina Otabor, ti ọpọ mọ si Phyna ti fi agba han oṣere tiata, Nkechi Blessing, ninu idije ẹṣẹ kikan wọn to waye niluu Eko.
Asiko ti ija naa to waye nile itura Federal Palace, to wa lagbegbe VI, niluu Eko, de ipele kẹrin ni Phyna fi ẹṣẹ ranṣẹ si Nkechi ti Nkechi si ṣubu lulẹ rọgbọndọn.
Ija naa ni akọkọ iru rẹ fun awọn gbajumọ obinrin ni Naijiria, eyii ti ileeṣẹ Balmoral Promotions ṣe agbatẹru rẹ.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti Balmoral Promotions yoo ṣagbatẹru ẹṣẹ kikan laarin awọn gbajumọ ori ayelujara, eyii ti wọn n pe ni 'Chaos in the Ring' to maa n waye loorekoore.
Ere Phyna lẹyin to na Nkechi
Owo ti iye rẹ to aadọta miliọnu naira ni Phyna yoo gba lẹyin aṣeyọri naa, to fi mọ igbanu mo yege ati ọkọ ayọkẹlẹ tuntun.
Ija naa jẹ ọkan lara awọn nnkan ti ileeṣẹ ọhun fi ṣajọyọ ayajọ ominira Naijiria, eyii ti ilẹẹṣẹ Bet9ja ṣe onigbọnwọ rẹ ti awọn eeyan si wo lori ikanni SuperSport bo ṣe n lọ lọwọ.
Ninu ija naa, Phyna ja fafa ni ibẹrẹ nigba ti Nkechi kọkọ n gbe sunmọ alatako rẹ.
Nigba ti yoo fi di ipele kẹrin ni Phyna fi ẹṣẹ kan ṣọwọ si Nkechi ti ẹmi Nkechi ko si gbaa mọ.
Lẹyin ti Nkechi balẹ to si sun gbalaja ni rẹfiri to n ṣakosa ija naa bẹrẹ si n ka onka lati ẹni amọ o ti bọ sori nigba ti Nkechi yoo fi pada dide.
Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin ija yii?
Lẹyin to fẹyin Nkechi gbolẹ tan ni Phyna bẹrẹ si n fi oko ọrọ ranṣẹ to oṣere tiata mii, Etinosa Idemudia lẹyin to ni Etinosa ti n fi ọrọ ranṣẹ si oun ṣsaju.
Etinosa, ti oun naa wa ninu gbagede ti ija oun ati Nkechi ti waye fesi pe ẹru ko ba oun, ati pe oun ṣetan lati koju Phyna lori papa.
Eyii n tumọ si pe o ṣeeṣe ki ija Phyna ati Etinosa waye laipẹ.
Phyna ti sọ ṣaaju pe yoo wu oun lati maa ja ẹṣẹ bii iṣẹ oojọ lọjọ iwaju.
Ẹwẹ, ni gbagede ija kan naa ni Carter Efe ti na Speed Darlington, ti ọmọ orilẹede Ghana nni, Seth 'Freezy Macbones' Gyimah si na Godday 'Zodsolo' Appah.




























