A ò lè máa bínú ara wa kí a máa retí ìlọsíwájú ní Nàìjíríà - Ooni Ile Ife

Ooni Ile Ife, Oba Ogunwusi wọ aṣọ ati ade funfun, o fi aṣọ olomi aro pa kaja, o wọ ọpọlọpọ ilẹkẹ si ọrun ati ọwọ, o mu ọpa funfun dani.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ọọni ti ile-ifẹ, ti rọ gbogbo awọn ọmọ Yoruba ati gbogbo ẹya to ku ni Naijiria lati wa ni irẹpọ ati iṣọkan ki orilẹ-ede Naijiria le dara. Ooni parọwa yii nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ to waye ni ilu Ile Ife, ipinlẹ Osun.

‎Ọba Ogunwusi woye pe, a ko le maa binu ara wa ki a maa wa ni ireti pe orilẹ-ede Naijiria maa goke agba tabi ki alaafia ko jọba nibẹ nigba to jẹ pe awọn eeyan naa lo n jẹ orilẹ ede.

‎O ni gbogbo igba ni awọn ẹlẹṣin Kristẹni, awọn Musulumi ati awọn Oniṣẹṣe maa n ke pe Olodumare fun ilọsiwaju orilẹ-ede Naijiria ṣugbọn to ni eyi ko le wa si imuṣẹ ti ko ba si ifẹ ati irẹpọ to dara laaarin gbogbo ọmọ Naijiria lai fi ẹsin tabi ẹya ṣe.‎

O wa rọ gbogbo ọmọ Naijiria maa lo ifẹ laaarin ara wọn, to si ohun nikan lo le ṣe iranwọ lati tun orilẹ-ede Naijiria ṣe.

Ọọni parọwa yii lasiko to wa ni igbele ọlọjọ meje to maa n ṣaaju aṣekagba Ọdun Ọlọjọ, ki wọn to gbe ade Are jade lati fi wure fun gbogbo ilu.

Ọọni de ade Are, awọn ọkunrin meji mu dani ni ẹgbẹ mejeeji

Kí ni ọdún Ọlọ́jọ́?

Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá, irinwó àti ẹyọ̀kan ni àwọn Òrìṣà tó wà ní Ile-Ife, ìpínlẹ̀ Osun àti pé gbogbo wọn ló ní ọjọ́ tí wọ́n máa ń bọ wọ́n.

Ọdún Ọlọ́jọ́ jẹ́ ọdún kan pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá èyí tí wọ́n fi máa ń ṣàmì ọjọ́ tí Olódùmarè dá ilé ayé.

Ọdún Ọlọ́jọ́ wà lára àwọn ọdún tó ti pẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá.

Ó jẹ́ ọdún tó máa ń wáyé ní ìrántí Ogun tí ìgbàgbọ́ wà pé ó jẹ́ àkọ́bí Olódùmarè.

Ṣáájú àyájọ́ ọdún yìí ni Ooni Ile-Ife yóò ti wà ní ìgbélé ọjọ́ méje níbi tí yóò ti máa ṣe àdúrà fún ìran Yorùbá àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀.

Lẹ́yìn èyí ni Ooni máa jáde síta pẹ̀lú Ade Are, èyí tí ìgbàgbọ́ wà pé òhun ni Oduduwa kọ́kọ́ dé.

Láàárín oṣù Kẹsàn-án sí oṣù Kẹwàá ọdún ni ọdún Ọlọ́jọ́ máa ń wáyé.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé ni wọ́n máa ń péjú pésè sí ìlú Ile-Ife láti kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọdún Ọlọ́jọ́.

Awọn ero to mu ẹgba dani tẹle Ọọni

Báwo ni ti Ade Are níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎Oladotun Hassan, to jẹ ọkan lara awọn Sooko ti Ile-ifẹ, ṣalayepe ade Are jẹ ade ti ẹnikẹni tabi Ọba kankan ko gbọdọ ni tabi de nilẹ Yoruba yatọ si Ọọni Ile Ifẹ.

‎O sọ pe ibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ nikan ni Ọọni paapaa ti maa n de ade Are, eyi to tumọ si pe ẹẹkan lọdun ni ade naa maa n ri ita.

O ni idi niyii ti Ooni fi kọkọ maa n lọ si idi oriṣa fun ọjọ meje ko to di pe yoo de ade Are naa ni ọjọ ti wọn ba n ṣe aṣekagba ọdun Ọlọjọ.

"Bi Ọba kankan ba dan wo lati gbe ade Are si ori, ọrùn ni yoo wọ Ọba bẹẹ pa nitori Ọọni nikan ṣoṣo ni Eledumare gbe ade naa fun.

‎Ninu ọrọ tirẹ, Oloye Oludotun Aworeni, Araba awo agbaye sọ pe ade Are jẹ ade iṣẹmbaye fun ilẹ Oodua, kii si ṣe fun Oriade miiran rara.

‎O ni ade Are wa fun iwure gẹgẹ bi orukọ rẹ to si jẹ wi pe Ọọni ile-Ifẹ nikan lo ni anfaani lati gbe sori lati le fi wure fun gbogbo eeyan ati lati le tun fi bi ibi tabi wahala danu.

‎Ọna ko gba ẹsẹ nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ ti ọdun yii, to si tun gbe ọna ara mi yọ bi aṣọ ṣe n pe aṣọ ranṣẹ nibi ayẹyẹ naa.