Àwọn ọmọ Naijiria sọ èrò wọn lórí Ààrẹ Tinubu tí kò sí nípàdé àwọn olórí àgbáyé (UNGA 81) tó bẹ̀rẹ̀ l'America lónìí

Oríṣun àwòrán, President Bola Tinubu/Facebook
Bi ipade apapọ awọn olori lagbaaye ṣe bẹrẹ ni New York, lorilẹede America lonii ọjọ Iṣẹgun ọjọ kejilelogun, oṣu Késan-an ọdun 2026, iyẹn UN General Assembly (UNGA 81), awọn eeyan Naijiria ti n fi ero ọkan wọn han nipa bi Aarẹ orilẹede yii, Bola Tinubu, ko ṣe si nibẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ileeṣẹ Aarẹ ti fi atẹjade sita lọjọ Aiku, pe Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima, ni yoo ṣoju Tinubu nibi eto naa, ti yoo si ko awọn ikọ Naijiria sodi.
Bi ikede naa ṣe waye ni ọpọ eeyan lori ayelujara ti n sọ pe bii ẹni to fi iṣẹ igbọnsẹ ran ọmọ ni iṣe ti Tinubu ran Shettima naa.
Atiku Abubakar to n dupo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ADC lo kọkọ lewaju ninu awọn to n sọ pe Tinubu lẹbọ lẹru l'America ni ko ṣe fẹ yọju sibẹ.
E ọ ranti pe ẹẹkan pere ṣi ni Tinubu yọju sipade apapọ naa ri latigba to ti gun ori aleefa ni 2023, eyi si ni igba kẹta ti Shettima yoo ṣoju fun un nibẹ.
Ṣaaju ni Jimoh Ibrahim, aṣoju Naijiria lẹka Iṣọkan Orilẹede Agbaye ti kede pe Aarẹ Tinubu yoo wa nibi ipade naa lọdun yii, koda, o ni awọn ti ṣeto pe itosi Donald Trump ni yoo jokoo si pẹlu.
Amọ bo ṣe ku dẹdẹ ki ọjọ eto naa pe ni ọrọ yii pada, ileeṣẹ Aarẹ kede pe Aarẹ to wa ni Europe lọwọ bayii ko ni i yọju sibi ipade naa, wọn ni Igbakeji rẹ ni yoo ṣoju Naijiria laṣepe ni New York.
Diẹ lara ohun tawọn eeyan sọ lori ayelujara nipa ai lọ si UNGA Aarẹ Tinubu
- Muhammad Awwoal: "Ibẹru FBI ni ipilẹṣẹ ọgbọn."
- Kemjika Hilary Kemjika, loju opo Facebook, kọ pe: "Ṣebi awọn kan sọ pe ẹni to kọ́ ilu Eko yoo jokoo lẹgbẹ Aarẹ Trump ni UNGA ni!"
- Umar Abubakar Zumami: "Olori to ka ojuṣe rẹ nilẹ Okere kun ni Naijiria nilo. Bi aarẹ ko ba le lọ sipade UNGA, o yẹ ki ileeṣẹ aarẹ ṣalaye idi ẹ fawọn ọmọ Naijiria, ati bi wọn ṣe ṣoju wọn si."
- Sani Saidu Yayangida: "A n reti esi latọdọ awọn aṣoju ijọba lori idi ti aarẹ ko ṣe lọ sipade UNGA ni New York."
- Baban Yasmin: "Tinubu ko ni I lọ sipade apapọ awọn olori agbaye ni New York laye, boya o n bẹru ki ohun to ṣẹlẹ si Nicolas Maduro ma ṣẹlẹ soun naa. Lati ọdun mẹta sẹyin lo ti n yẹra fun ipade naa to si n ran Igbakeji rẹ, Kashim Shettima lọ."
- Stephen Lenebari: "O ya mi lẹnu bawọn eeyan ṣe n sọ pe Tinubu n bẹru FBI ni, aarẹ to ṣi wa lori aleefa ni Tinubu, wọn ko si le mu un bayii. O kan wu u lati fiṣẹ naa ran ẹlomi-in n,i ko si sohun to buru ninu iyẹn."
- Rotimi Ayodele-Smith: "Gbogbo awọn to n pariwo nibi ko mọ pe Tinubu ti lọ s'America lẹẹmeji. Ki lo jẹ pataki ninu UNGA. Ipade tawọn alagbara ti n fi ibinu wọn han ni UNGA, ko ju bẹẹ lọ. Ibẹ naa si ni awọn orilẹede kekere ti le ko agbako tiwọn naa, nitori ti wọn ba to sẹyin alagbara aye kan, o le tun orilẹede wọn ṣe bẹẹ lo si le ko ba a."
- Lenrey Aroge @olanrewaju2sure: "Ipinnu to daa ju lati ṣe niyẹn. Imura kankan Atiku lo fa eyi. Otitọ ibẹ ni pe wọn ko le fofin mu Aarẹ, o kan jẹ pe awọn ọmọ Naijiria to wa lẹyin odi le yẹyẹ rẹ ni."
- Mohammed Nasir Abdullahi @abdull_nasir: "Ẹni ti orilẹede to n gbalejo kede pe awọn n wa ko le ni igboya lati kopa ninu iru akojọpọ agbaye bẹẹ.
Atipo to ṣe funra rẹ gan-an to ẹsun lọtọ"
- Ibileye Benjamin Sunday: "Ki lo de ti Baba Chicago n bẹru lati lọ si US? Nise lo yẹ ki Aarẹ fi anfaani naa tun darapọ mọ awọn ti wọn jọ kawe ni Chicago."
- Muhammad Yusuf Adam @myAdam200: "Ẹru maa n ba ẹni to ba jẹbi ni gbogbo igba ni."
- Ndayako @abdul_ndk: "Tinubu yoo maa fo kiri to ba jẹ ti abẹnu, amọ ko le ṣoju orilẹede rẹ nipo. Bi o ko ba le foju rẹ han ko o si ṣoju awọn eeyan rẹ pẹlu awọn tẹ ẹ jọ kawe kaakiri agbaye, oo ṣe fipo silẹ. #TinubuMustGo"
Amọ ileeṣẹ Aarẹ ti fesi sawọn awuyewuye yii, wọn ni ai si Tinubu ni New York lasiko yii ko din ọla Naijiria ku.
Ileeṣẹ Aarẹ sọ pe agba nilẹ Adulawọ (Giant of Africa) ṣi ni Naijiria n ṣe.
Atiku bínú sí Tinubu tó rán aṣojú ló sípàdé UNGA fún ìgbà kẹ́ta, ó ní ṣe ẹ̀rù ń ba Ààrẹ láti wọ America ni

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Facebook
Atiku Abubakar, Igbakeji aarẹ Naijiria nigba kan, ti koro oju si bi Aarẹ Bola Tinubu ṣe ran aṣoju lọ sipade awọn olori agbaye ti a mọ si UNGA 81, eyi ti yoo waye ni New York, lorilẹede America.
Ọla ode yii ti i ṣe ọjọ kejilelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni ipade naa yoo bẹrẹ pẹrẹwu, Igbakeji aarẹ Naijiria, Kashim Shettima ni yoo si ṣoju fun Aarẹ.
Ni 2023 ti Aarẹ Tinubu gori aleefa lo yọju sipade naa funra rẹ, amọ ni 2024, 2025 ati ti ọdun 2026 yii, igbakeji rẹ lo ran lọ.
Ẹhonu Atiku
Ninu atẹjade ti Amugbalẹgbẹẹ pataki fun Atiku Abubakar, Phrank Shaibu,fi sita lo ti beere pe ki lo de ti Tinubu n pa ọkan lara awọn agbejọpọ nla agbaye naa jẹ.
"O sọ fun wa pe ẹgbẹ Aarẹ Trump ni wa a jokoo si — ki lo n ba ọ lẹru ninu America?"
Bẹẹ ni Atiku beere ninu atẹjade rẹ naa.
Igbakeji aarẹ Naijriia tẹlẹ naa sọ pe ipade UNGA yii ṣe pataki pupọ.
O ni o n fun orilẹede ni anfaani lati ba awọn olori aye pade, sọrọ okoowo ati idagbasoke ilu ẹni.
Atiku mẹnuba awọn asọti ọrọ Tinubu l'America, to ni I ṣe pẹlu igbẹjọ, o ni boya nitori rẹ ni Aarẹ ṣe n sa fun America lẹmọlemọ.
Amọ ileeṣẹ Aarẹ ti sọ pe ko sohun to jọ pe Tinubu n sa fun America.
Wọn ni Aarẹ ti lọ si America tẹlẹ, ọrọ abẹnu Naijiria si jẹ ẹ logun, titi kan ọrọ aje ati aabo ilẹ wa bo ti wa ni Europe lọwọlọwọ.
UNGA 81: Mọ̀ nípa ìpàdé àwọn olórí àgbáyé ní New York, àti ìdí tí Ààrẹ Tinubu fi ní kí Shettima lọ

Oríṣun àwòrán, Vice President Kashim Shettima/Facebook
Bẹrẹ lati ọjọ kejilelogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 yii, titi di ọjọ kejidinlọgbọn oṣu yii kan naa, ipade apapọ awọn olori agbaye yoo maa waye ni New York, lorilẹede America.
Ipade naa ti i ṣe "United Nations General Assembly'' (UNGA) jẹ ẹlẹẹkọkanlelọgọrin (81) iru rẹ.
Akori ipade apapọ UNGA ti ọdun yii ni wọn pe ni "Restoring trust, managing transformation: A United Nations that delivers for all".
Gẹgẹ bo ṣe yẹ, orilẹede Naijiria naa n kopa ninu ipade naa, Aarẹ Tinubu si yẹ ko wa nibẹ pẹlu, amọ Aarẹ fa iṣẹ naa le Igbakeji rẹ; Kashim Shettima lọwọ.
Shettima lewaju ikọ awọn gomina, minisita atawọn mi-in lọ si UNGA 81
Lati fidi ẹ mulẹ pe Aarẹ Bola Tinubu ko ni i le yọju sibi ipade naa fun ti ọdun yii, ileeṣẹ Aarẹ fi atẹjade kan sita lọjọ Aiku to kede pe Igbakeji rẹ, Kashim Shettima ni yoo ko ikọ Naijiria sodi lọ si New York.
Atẹjade ti Stanley Nkwocha; Amugbalẹgbẹẹ pataki fun Aarẹ lori eto iroyin fi sita, ṣalaye pe Aarẹ ti gbe iṣẹ naa le Igbakeji rẹ lọwọ.
Lara awọn ikọ ti wọn ni Shettima yoo lewaju fun ni Gomina Siminalayi Fubara lati ipinlẹ Rivers; Gomina Dauda Lawal ti ipinlẹ Zamfara; awọn minisita atawọn lọga-lọga lẹnu iṣẹ ọba.
Ki ni Shettima yoo ṣe gẹgẹ bii aṣoju Naijiria ni UNGA 81?
Nibi ipade yii, Igbakeji Aarẹ Naijiria; Kashim Shettima yoo ka ọrọ apapọ Naijiria, ninu rẹ ni yoo ti sọ ipo ti orilẹede yii wa ati ohun to mu lọkunkundun lori awon ọrọ to n ṣẹlẹ lagbaaye.
Yoo sọrọ nipa aabo, idagbasoke ọrọ aje ati ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ilẹ okeere, gẹgẹ bi atẹjade ijọba wa ṣe sọ.
Bakan naa ni Igbakeji aarẹ Naijiria yoo tun kopa ninu ipade awọn onipo giga, nibi ti wọn yoo ti sọrọ lorii ẹtọ idagbasoke, ayipada oju ọjọ atawọn iṣẹlẹ mi-in to ṣe pataki si Naijiria ati ilẹ Adulawọ.
Eyi ni igba kẹta ti Aarẹ Bola Tinubu ko yọju sibi ipade apapọ UNGA latigba to ti depo aarẹ ni 2023.
Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Tinubu ko si ni Naijiria lasiko yii, ṣaaju ni ahesọ ti n jade pe yoo gba ilẹ Europe to wa lọ si New York, nibi ipade naa.
Koda, awọn kan sọ pe eto ti wa nilẹ fun un lati jokoo lẹgbẹ Aarẹ Donald Trump ilẹ America.
Amọ eyi ko pada ri bẹẹ, pẹlu bi ileeṣẹ Aarẹ ṣe kede pe Igbakeji rẹ ni yoo ko awọn ikọ Naijiria lọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awon idi ti aarẹ ko fi lọ mọ ni ai si nile rẹ ati ko le mojuto awọn ọrọ abẹle miran nibi to lọ.


























