Eré bọ́ọ̀lù ní Naijiria ń kojú ìṣòro tó lágbára lọ́wọ́ yìí – Segun Odegbami

Àwọn agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà márùn-ún, níbi ti àwọn mẹ́rin ti wọ aṣọ funfun tí adilémú ti wọ aṣọ aláwọ̀ ewé
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Bi orile-ede Naijiria ṣe n gbaradi fun ipolongo idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ, iyẹn AFCON ti ọdun 2027, gbajugbaja agbabọọlu Naijiria tẹlẹ, Segun Odegbami ti sọ pe asiko ipenija to buru julọ ninu itan ni orileede naa n koju lọwọlọwọ.

Lati bi oṣu mejila sẹyin, ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ati Super Falcons ti awọn obinrin ti n padanu lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye.

Yatọ si bi awọn agbabọọlu agba ṣe kuna lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye yii, o tun jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ wi pe awọn agbabọọlu to ṣẹṣẹ n dide bọ, iyẹn awọn ti ọjọ ori wọn ko to ogun ọdun, ti wọn padanu ninu idije ife ẹyẹ ni ipele to kọgun si eyi to kọgun si aṣekagba tii ṣe quarter-finals.

Odegbami sọ pe ohun to ku diẹ kaato ni ipo ti orileede Naijiria wa lasiko yii, paapaa pẹlu bi awọn alakoso ṣe n lo agbara.

"Ko tii figba kankan bajẹ bayii ri ninu itan wa, wi pe a ko yege fun idije ife ẹyẹ agbaye," Ọdegbami sọ bẹẹ fun BBC.

Awọn obinrin wa (Super Falcons), to jẹ pe awọn ni ogo Afrika, kuna lati gba ife ẹyẹ AFCON ti ọdun 2025 to yẹ ki wọn gba. Awọn ikọ ọjẹ wẹwẹ wa gan-an ko ṣe daadaa.

"Idije ere idaraya orileede wa naa ko tun mu owo wọle. Nnkan n ṣẹlẹ ti ko dara."

Wahala to n ṣẹlẹ yii ti jẹ ki opo atunto wa ninu ajọ to n ṣakoso ere bọọlu nilẹ Naijiria, iyẹn NFF.

Oṣu to kọja ni alaga ajọ NFF, Ibrahim Gusau; akọwe rẹ, Mohammed Sanusi ati awọn igbimọ iṣakoso kọwe lati fi ipo wọn silẹ, lẹyin oniruuru ọrọ kugbakugbe ti wọn sọ si wọn.

Odegbami sọ pe kii ṣe awọn to yẹ ko maa ṣakoso ajọ NFF ni wọn n ṣakoso rẹ, to si sọ pe ohun to ṣe pataki ni pe ki atunto waye, lati le pese aaye idagbasoke ọlọjọ.

"Ariwo ti awọn ọmọ Naijiria pa lo n ṣiṣẹ. Gbogbo awọn araalu ni wọn ko fẹ wọn mọ, debi wi pe Aarẹ orileede yii gan, Bola Tinubu sọrọ jade pe ohun fẹ ki atunto wa," Odegbami sọ bẹẹ.

"Niṣe ni gbogbo nnkan wa dabi idan, to si jẹ pe ni bayii, wọn ti n fi apẹẹrẹ rere lelẹ, ti yoo mu idagbasoke ba eto ere bọọlu."

Àwọn àyípapà nínú àjọ NFF

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni bayii, awọn igbimọ alabaṣiṣẹpọ ninu ajọ to n ṣakoso ere bọọlu lagbaye, FIFA ati ti ilẹ Afrika, iyẹn CAF ti dide lati bẹrẹ ajọsọ pẹlu ajọ to n ri sọrọ ere bọọlu nilẹ Naijiria, NSC, lori ọna abayọ si atunto ere bọọlu nilẹ Naijiria.

Awọn igbimọ naa ni wọn n ṣiṣẹ lori ọna lati ṣagbekalẹ bi atunto naa yoo ṣe waye, ṣugbọn to jẹ pe eto idibo ti NFF yoo ṣe lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹsan, ni wọn ko tii wọgile.

Sibẹsibẹ, Aarẹ Tinubu ti sọ erongba rẹ lati jẹ ki atunto waye, leyi ti yoo dẹkun bi ilẹ Naijiria ṣe n padanu loorekoore.

Emmanuel Ikpeme ni wọn ti yan bayii gẹgẹ bi adele akọwe fun ajọ NFF, nigba ti wọn yan Ademola Olajire gẹgẹ bii igbakeji adele akọwe.

Latigba ti wọn ti kede yii ni oniruuru ijiroro ti n lọ kaakiri igboro laaarin awọn alẹnulọrọ nipa wi pe boya orileede na anilo atunto to jinlẹ.

Gbajugbaja akọroyin ere idaraya nni, Fisayo Dairo ti wa sọ pe oun nigbagbọ wi pe atunto naa yoo kọja wi pe wọn n ṣe ayipada lori awọn alakoso.

"Atunto yẹ ko nii ṣe pẹlu ṣiṣe agbekalẹ ilana ti ere bọọlu wa le maa ṣe daadaa le lori," Dairo sọ fun BBC.

"A ni lati wa awọn ọlọgbọn, oloye ati awọn akọṣẹmọṣẹ ti yoo mu ki ẹgbẹ agbabọọlu awọn agba wa duro digbi.

"Bẹẹ si la ni lati jẹ ki awọn alẹnulọrọ ni ojuṣe gidi ti yoo jẹ ki ẹka ere bọọlu jẹ ohun ti wọn fi n pa owo wọle."

Irú bọ́ọ̀lù wọ ni Nàíjíríà ń gbá?

Segun Odegbami, lasiko to n ba BBC sọrọ
Àkọlé àwòrán, Aami ayo mẹta si odo ni ikọ Super Eagles fi bori akẹgbẹ wọn lati orileede Algeria, ti wọn fi gba ife ẹyẹ naa to waye niluu Eko lọdun 1980.

Fun Segun Odegbami, o ni iru ere bọọlu ti awọn to wa nibẹ n gba lasiko yii, yatọ si eyi ti awọn gba nigba ti wọn, lati fi mu ayipada ati idagbasoke de ba awọn ere idaraya nilẹ Naijiria.

Odegbami ti wọn tun n pe ni 'Mathematical' nitori awọn ọna ara to n gbe ere bọọlu tirẹ gba lori papa, nipa awọn ẹbun ati ọgbọn atinuda, eyi to wa lara nnkan to fun Super Eagles ni aṣeyọri lọdun 1980 ti wọn gba ife ẹyẹ ilẹ adulawọ ti CAF.

Fun awọn ti ko ba ranti Segun Odegbami, goolu mẹtalelogun lo gba sawọn fun ilẹ Naijiria ninu ifarahan mẹtadinlaadọta to ti kopa fun Naijiria, bẹẹ lo si wa ninu ikọ to gba ife ẹyẹ AFCON lọdun 1980.

Odegbami sọ pe ipo ti Super Eagles wa bayii, yatọ gidigidi si asiko ti wọn wa nibẹ lati mu ayipada rere ba ere idaraya Naijiria.

"A ni atilẹyin ti ko wọpọ, bẹẹ si la ni irawọ to lọ ni ibamu pẹlu irori wa," Odegbami jẹ ko di mimọ.

Lẹyin naa, Super Eagles tun gba ife ẹyẹ AFCON lọdun 1994 ati 2013, bẹẹ si ni wọn ṣe ipo keji lọdun 2023.

Yatọ si eyi, Naijiria tun ṣe ipo kẹta lọdun 2019, ninu idije to waye lorileede Morocco.

Ṣugbọn sibẹ, Odegbami jẹ ko di mimọ pe ere bọọlu kii ṣe ohun iwuri fun awọn iṣakoso to n jọba nilẹ Naijiria, to si lo jẹ ẹdun wi pe awọn alakoso ere bọọlu ti n ja orileede oun kulẹ lati idaji ọdun 1990s.

"Awọn to n tukọ rẹ bayii ko ṣe daadaa fun wa, wọn ko si daabo bo wa bo ti tọ," Odegbami sọ bẹẹ.

"Eleyi si ti ṣe akoba fun gbogbo ẹka idagbasoke ere bọọlu wa: lati ipilẹ bii wiwa awọn agbabọọlu, mimu idagbasoke de ba awọn agbabọọlu, ṣiṣe agbekalẹ ẹka ti yoo maa tọju wọn, ẹka eto idanilẹkọọ, ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn yoo lọ nilẹ yii ati lagbaye.

"Bawo ni ilana kikọnimọ-ọn-gba? Ki ni erongba ati ilana ere bọọlu lorileede yii?

"Ki ni aṣa wa, ki ni ọna imọ atinuda wa?"

Àwọn pápá ìṣeré tó ti ń dẹnukọlẹ̀

Papa iṣere Godswill Akpabio to wa niluu Uyo, awọn obinrin meji kan n rin lọ, ninu ayika na to mọ tonitoni
Àkọlé àwòrán, Papa iṣere Godswill Akpabio to wa niluu Uyo

Odegbami kọminu lori ipo ti ọpọ awọn papa iṣere wa kaakiri ipinlẹ to wa nilẹ Naijiria, to si lo jẹ ohun ibanujẹ wi pe awọn ijọba ti pa awọn papa iṣere ti.

O sọrọ nipa papa iṣere to wa ni Surulere nipinlẹ Eko, nibi ti wọn gba oniruuru ifẹsẹwọnsẹ lasiko idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ laaarin ọdun 1980 si 2000.

Bakan naa lo mẹnuba awọn papa iṣere bii Liberty, ti wọn ti yi orukọ rẹ pada si papa iṣere Obafemi Awolowo, iyẹn to wa niluu Ibadan; to fi mọ papa iṣere Ahmadu Bello to wa niluu Kaduna ati papa iṣere UJ Esuene tiluu Calabar.

"Mo maa n sunkun nigba ti mo ba n ri iru awọn ibajẹ ti wọn ti ṣe si awọn agbegbe ere bọọlu nilẹ Naijiria, iyẹn awọn papa iṣere wa, awọn eyi to jẹ ibi itan ti Naijiria ti bẹrẹ ere idaraya," o sọ bẹẹ.

"Boya ohun ti wọn mọ-ọn-mọ ni, boya aikọbi ara sii ni, wọn ti ṣe ipalara to pọ si ohun ajogunba ilẹ Naijiria.

"Uyo jẹ eyi to dara julọ ti a ni ni Naijiria lọwọlọwọ, ṣugbọn ṣa, ko dara to bi a ti ni awọn eyi ti a lọ laaarin ọdun 1960s si 1990s."

Super Eagles yoo bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ lati yege fun idije ife ẹyẹ ilẹ Adulawọ, AFCON ti ọdun 2027 lonii, nibi ti wọn yoo ti maa waako pẹlu awọn akẹgbẹ wọn lati orileede Madagascar ni papa iṣere Godswill Akpabio to wa ni Uyo

Lẹyin naa ni wọn yoo ṣẹṣẹ rin irin ajo lọ si orileede Guinea-Bissau lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹsan.