Àwọn ọmọ gbajúmọ̀ akọrin Juju St. Janet ṣàlàyé ohun tó ṣekúpa gbajúgbajà Olórin náà

Oríṣun àwòrán, St. Janet/Instagram
Lẹyin awuyewuye lori ayelujara lori nnkan to ṣekupa gbajumọ akọrin Juju n ni, Iyun Janet Oluwatoyosi Ajilore ti ọpọ mọ si St. Janet, awọn ọmọ rẹ ti ṣalaye nnkan to ṣekupa a gan an.
Ninu ifọrọwerọ ti o ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin ori ayelujara kan, akọbi St. Janet, Fola St. Janet, ṣalaye wi pe ṣadeede ni akọrin naa bẹrẹ sii di mọ aya rẹ lọjọ ti o ku.
Fola sọ pe nile ọkọ oun loun wa nigba ti iṣẹlẹ ọhun waye, o ni awọn aburo oun ti wọn wa pẹlu mama awọn ni wọn pe oun lori foonu lalẹ wi pe mama ti dakẹ.
O ni ọrọ naa ba oun lojiji tori St. Janet ko ṣaisan ṣaaju ọjọ ti o jade laye.
''Wọn ni mama kan n pariwo wi pe aya n dun awọn debi wi pe awọn ko le mi daadaa mọ.
Awọn naa lo sọ pe ki wọn gbe awọn lọ si ile iwosan lọjọ naa.
Aburo mi to wa pẹlu wọn lo le ṣalaye daadaa tori mi o tiẹ mọ bi ara mi ṣe ri lọjọ yẹn.
Iyalẹnu lo jẹ tori wọn si lọ sode orin ṣaaju ọjọ ti wọn ku yii, koda, mo ba ọbẹ ti wọn sọ pe wọn se nigba ti mo de.
Awọn ni wọn lọ sọja funra wọn lati ra nnkan ọbẹ, nigba ti wọn se ọbẹ naa tan ni wọn sọ pe aya n dun awọn ti si wọn dero ile iwosan.
Lẹyin naa ni wọn pe mi wi pe mama ti dakẹ,'' Fola lo sọ bẹẹ.
''St Janet lo lọ sọja funra rẹ lọjọ to ku, o si se ọbẹ nigba to de lati ọja''
Ọmọwunmi to wa pẹlu St. Janet sọ pe oun ba a lọ sode orin ṣaaju akoko iku rẹ.
O ni awọn elegbe rẹ gan an patẹwọ fun un lọjọ naa lẹyin to ṣere tan.
Owowunmi fikun ọrọ rẹ pe St. Janet tun lọ sọja funra rẹ lọjọ keji lati lọ ra nnkan ọbẹ, o si pada sile ni nnkan bii ago mẹfa irọlẹ.
''Koda wọn bawọn ṣere daadaa lasiko ti wọn wa lọja.
Funra wọn si ni wọn da ina ounjẹ to wu wọn lati jẹ lọjọ naa.
Ṣadeede ni wọn bẹrẹ sii di aya mu nibi ti wọn jokoo si i, wọn sọ fun mi pe aya awọn n ṣe bakan bakan bi ẹni pe nnkankan le si awọn laya.
Lẹsẹ kẹsẹ naa ni wọn sọ pe ki a gbe awọn lọ sile iwosan, ko ju iṣẹju mẹwaa lọ ti wọn gbe wọn de ile iwosan ti ẹlẹmi fi gba a.
Ẹran nikan ni wọn mu sẹnu ninu ọbẹ ti wọn se lọjọ naa ti won fi jade laye,'' Omowunmi ṣalaye.
Omowunmi ni irọ to jinna si ootọ ni ọpọ iroyin tawọn kan n gbe kiri lori ohun to ṣokunfa iku St. Janet.
Ta a ni Saint Janet akọrin Juju to jade laye?
Odu ni Janeth Omotoyosi Janet Ajilore Iyun, ẹni ti wọn tun n pe ni Mama Yabis, kii ṣaimọ foloko lagboole olorin Juju nilẹ Naijiria, ti ọpọ awọn to gbafẹ si gbadun ori rẹ nigba to wa laye.
Ko fẹẹ si agbo ariya tabi ibi ti awọn eeyan ti ma lọ n jaye, ti wọn kii tii gbọ orin rẹ lagbaye. Bo ṣe n ṣere orin nilẹ Naijiria, lo tun ti lọ soke okun lati lọ kọrin fawọn ololufẹ rẹ.
Inu ẹgbẹ akọrin ti ijọ Kerubu ati Serafu ni St Janat, ọmọ bibi ipinlẹ Ogun naa ti bẹrẹ iṣẹ orin rẹ, nibẹ lo si ti bẹrẹ sii nifẹ si iṣẹ orin kikọ.
Nigba to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun, St Janet bẹrẹ sii tẹle gbajumọ olorin nni, Segun Lawaye jade orin kikọ, to si n ṣe elegbe lẹyin rẹ.
Igba to ya loun naa pinnu lati ṣe awo orin tiẹ sita, bo tilẹ jẹ pe ko tii gbajumọ nigba naa.
Diẹdiẹ ni Mama Yabis tun bẹrẹ sii mu idagbasoke ba orin rẹ, leyi to jẹ ko bẹrẹ sii di gbajugbaja laarin awọn olorin.
Ohun pataki tubọ jẹ ki Mama Yabis di ilu mọ-ọn-ka ni ti bo ṣe bẹrẹ sii yi awọn orin ti wọn n kọ lawọn ile ijọsin si ikọkukọ, eyi gan-an lo jẹ ki awọn to gbafẹ fẹran orin ọhun.
Nigba naa lo bẹrẹ sii pe ara rẹ ni oludasilẹ ile ijọsin Saint Bottles, eyi ti oloyinbo n pe ni "General Overseer of Saint Bottles Cathedral (Sinners' Chapel),".
Apejẹ yii lo ṣafihan iru awọn orin to n kọ fun awọn olulufẹ rẹ kaakiri agbaye
Pẹlu bo ṣe n kọ irufẹ orin yii to, awọn eeyan tun ṣi n gba tiẹ siwaju si i, to jẹ ki wọn maa pe e si oniruuru ode ariya nilẹ Naijiria ati loke okun.
Awo orin rẹ to pe ni 'Faaji Plus' gan-an lo tubọ gbe e ja sita gbangba, to di pe ko si ibi naa ti wọn kii tii kọ ọ.
Ọpọ igba ni ẹgbẹ olorin bii PMAN ti fi ofin de Saint Janet nitori irufẹ orin to n kọ, leyi ti wọn sọ pe ko ṣagbelarugẹ fun iwa ọmọluabi.
Bakan naa ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekoo tun gbe igbesẹ lori awo orin rẹ to pe ni 'Faaji Plus', ti wọn si fagile e lawọn ode to ba nii ṣe pẹlu ijọba ipinlẹ naa.

























