Iná ṣẹ́yọ nínú ọjà Bode n'Ibadan, jó ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá

Oríṣun àwòrán, Others
Ariwo 'ẹ gba wa' lọ gba ẹnu awọn ara ọja Bode to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo laaro oni, ọjọ Ẹti tii ṣe Furaide nigba ti ina deedee ṣẹyọ.
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ yii ni ko tii sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa ijamba ina ọhun, ṣugbọn sibẹ, ẹdun ọkan nla lo jẹ fun gbogbo awọn to kagbako rẹ.
Ọpọlọpọ dukia ati ọja olowo iyebiye ni iroyin fi to wa leti pe wọn ba ijamba ina naa lọ.
Bi awọn kan ṣe n gbera ṣanlẹ, bẹẹ lawọn miran n bu sẹkun, nigba ti wọn ri ọṣẹ ti ina ọhun ṣe fun ile itaja wọn.
A gbọ pe loju ẹsẹ ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ pannapanna ti debẹ, ni wọn ti bẹrẹ sii gbiyanju lati pa ina ọhun, lati rii pe ko tan kaakiri.
Ṣaaju ki awọn oṣiṣẹ pannapanna too debẹ, ọpọ dukia lo ti bajẹ kọja sisọ.
Odu ni ọja Bode to jọna yii niluu Ibadan, to si jẹ pe kaakiri ẹkun Guusu-Iwọ-Oorun ilẹ Naijiria ni wọn ti n lọ sibẹ lati ra ọja ti wọn ba fẹ.
Yatọ si eyi, ọkan pataki lara awọn to tobi julọ nigboro ilu Ibadan ni ọja Bode yii, nibi ti awọn eeyan ti n ta oniruuru ọja bii agbo, awọ ẹran ati awọn nnkan ibilẹ miran.


























