Kí ni òfin sọ nípa wíwo ilé táwọn ajínigbé bá fi ṣe ibùgbé?

Ni owurọ ọjọ Aje, ọjọ Kẹjọ, osu Kẹfa ọdun 2026 ni ijọba ipinlẹ Ọyọ wo ile ti awọn ajinigbe, to jí aburo Adebayo Adelabu Pẹnkẹlẹmẹẹsi ati awọn ibeji rẹ si.
Ilé-isé ìjọba to wa fun iṣẹ òde àti ìgbòkègbodò ọkọ pẹlu awọn ẹ̀ṣọ́ alaabo to wa nipinlẹ Oyo ni wọn ṣe agbátẹrù bí wọn ṣe wo ile naa.
Ijọba ipinlẹ Ọyọ, nínú awijare rẹ to fi wo ile naa, ni òun wo ile naa ni tori pe oun ko fara mọ iwa ibajẹ rara bi o ti wulẹ ko kere mọ.
Amọ igbesẹ ijọba ti n fa oniruuru ariwisi laaarin awọn araalu. Bawọn kan ṣe n sọ pe igbesẹ ijọba ipinlẹ Oyo yii ti ya ju ni awọn mii n kan saara si ijọba.
Eyi lo mu BBC News Yoruba kan si amofin Ademola Owolabi lati ṣalaye ohun ti ofin sọ nipa irúfẹ́ ìgbésẹ̀ báyìí.
"Iwa aibikita fun ofin, iwa aibikita fun ẹtọ ọmọniyan ati ẹtọ araalu ni wiwo ile ti wọn ba ti ba ọdaran"
Agbẹjọ́rò Owolabi sọ pé kò sí òfin kankan lábẹ́ ìwé òfin Nàìjíríà tó ní kí wọ́n wo ilé tí wọ́n bá ti bá àwọn ajínigbé.
Owolabi bu ẹnu irufẹ igbesẹ bẹẹ bi o ṣe ni ile ẹjọ lo yẹ ko fun awọn ijọba laṣẹ lati ṣe ohunkohun ti wọn ba ka mọ ọdaran lọwọ.
O woye pe iru ile naa yẹ ko jẹ ohun elo to yẹ ki ijọba fi ṣe ẹjọ tako awọn ọdaran ti wọn irufẹ iwa ijinigbe bẹẹ mọ lọwọ ni.
O ni awọn ofin bayii jọ mọ ohun ti ijọba jogun lọwọ awọn Ologun to ti logba ri ni Naijiria to jẹ pe ipa ni wọn fi maa n ṣe ohun gbogbo.
Owolabi ni abala Kẹrinlelogoji, iwe ofin Naijiria fi aaye gba ẹnikẹni lati ni ile tabi ohun ini ati pe ijọba ko le ṣadede gba ile tabi ilẹ ẹnikẹni lai tẹle ofin to yẹ tabi fun ẹni to ba ni ohun ini bẹẹ ni ajẹmọnu to peye.
"Iwa aibikita fun ofin, iwa aibikita fun ẹtọ ọmọniyan ati ẹtọ araalu ni wiwo ile ti wọn ba ti ba ọdaran.
"Ṣe to ba jẹ pe iru ile itura nla bii Eko Hotel tabi Sheraton to wa ni Ikeja ni wọn ji eeyan pamọ si, ṣe ijọba maa ni ki wọn wo ile itura bẹẹ ni?
"To ba jẹ pe ẹni to nile ko mọ ohunkohun nipa iwa ijinigbe, tabi ti ẹni naa ko si ni Naijiria, ijọba ti ko ofo ba a, to si le wọ ijọba lọ sile ẹjọ labẹ ofin"
Amofin Ademola Owolabi tẹsiwaju pe ẹri nla ni ile ti ijọba ipinlẹ Oyo wo naa yẹ ko jẹ nile ẹjọ.
"Ibi ti iru iṣẹlẹ bayii ba ti waye ni a le pe ni ẹri pe iwa ọdaran ti waye nibẹ ti wọn maa gbe siwaju ile ẹjọ pe iwa ọdaran waye nibẹ.
"Ko si idi kankan ti ijọba fi maa wo ile naa nitori to ba jẹ awọn to hu iwa ibi bẹẹ kii ṣe awọn lo ni ile gangan, ko si bi ẹni to nile ṣe maa mọ pe wọn fẹ fi ile oun huwa ọdaran.
"Ko si ofin to fọwọ si ni Naijiria pe lai ṣe pe ile ẹjọ da eeyan lẹbi lori nnkankan lati lọ wo ile ẹni bẹẹ."
Agbẹjọro Owolabi ni ijọba ipinlẹ Oyo labẹ idari gomina Seyi Makinde ko ba ṣe suuru ki wọn to gbe igbesẹ wiwo ile naa.
O ni igbesẹ naa fi ijọba han pe wọn ko bikita fun iwadii to munadoko, ki wọn to gbe igbesẹ.
O ni to ba jẹ pe ẹni to nile naa ko mọ ohunkohun nipa iru iwa bẹẹ, tabi ti ẹni naa ko si ni Naijiria, ijọba ti ko ofo ba a, to si le wọ ijọba lọ sile ẹjọ labẹ ofin.
Nigba to n sọrọ lori awọn ipinlẹ ti wọn ti ṣagbekalẹ ofin wiwo ile ti wọn ba ti ba awọn ajinigbe, amofin naa ni o yẹ ki ijọba kọkọ fi ofin ti wọn ba fẹ gbe kalẹ to awọn araalu leti lati gbọ ariwisi wọn ki wọn to gbe ofin bẹẹ kalẹ.
O ni ofin gbọdọ jẹ ohun to maa mu irọrun ati igbeaye dara sii fawọn araalu ni.
Awọn ipinlẹ ti wọn ti ṣofin wiwo ile ti wọn ba ti ba ajinigbe
- Enugu: Ofin iwa ọdaran ipinlẹ Enugu kan an nipa ki ijọba wo ile tabi gba ile tabi ayekaye ti wọn ba ti lo fun ijinigbe.
- Edo: Ofin to de ijinigbe ti ipinlẹ Edo pa ijọba laṣẹ lati fofin de ati wiwo ile ti wọn ba awọn ajinigbe, ki wọn sib a ibugbe wọn jẹ, ki wọn si ma fi aaye gba awọn to ba n ṣiṣẹ pẹlu wọn.
- Oyo ati Abia: Awọn ijọba ni ipinlẹ Oyo ati Abia ti gbe igbesẹ wiwo awọn ile tawọn ajinigbe n lo lati fi dẹkun iwa awọn oniṣẹ ibi.

























