Rélùwéè yà kúrò lójú irin, èèyàn mẹ́ta kú

Ọkọ oju irin to yawọ atawọn ero to gbe, wọn duro sibi ti isẹlẹ naa ti waye

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ileeṣẹ ọlọkọ oju irin Naijiria,Nigerian Railway Corporation' (NRC), ti fidi ẹ mulẹ, pe eeyan mẹta di oloogbe lanaa ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹfa ọdun 2026, lasiko ti ọkọ oju irin Warri-Itakpe kan ya kuro loju ọna rẹ ni Agbor, ipinlẹ Delta.

Ileeṣẹ naa fi kun un pe ẹka mẹrin lo ya kuro lara reluwee naa.

Ọga agba ileeṣẹ NRC, Dokita Kayode Opeifa, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan, ṣalaye pe ẹsẹkẹsẹ ni wọn ti ran awọn ẹka to yẹ lọ sibẹ lati ran awọn ero ọkọ naa lọwọ.

Ọkọ oju irin to yawọ atawọn ero to gbe, wọn duro sibi ti isẹlẹ naa ti waye

Oríṣun àwòrán, Screenshot

"A ti ṣe onka awọn ero ọkọ, eeyan mẹta lo jade laye"

Ninu alaye Opeifa, o ni:

"Ileeṣẹ ọlọkọ oju irin Naijiria n fidi ẹ mulẹ, pe ijamba ọkọ oju irin to lagbara kan waye, eyi to kan ileeṣẹ Warri-Itakpe, ni horo Agbor, ipinlẹ Delta.

"O ba ni ninu jẹ pe eeyan mẹta ni a ti fidi ẹ mulẹ bayii pe wọn ku ninu iṣẹlẹ naa, nigba ta a ṣe onka awọn ero inu ọkọ naa."

Opeifa fi kun un pe awọn alaṣẹ n tẹsiwaju ninu iwadii lati mọ ohun to ṣokunfa ohun to mu reluweee naa kuro loju ọna rẹ.

Bẹẹ lo ni awọn n ṣeto iranwọ to yẹ fun awọn ẹbi ti eeyan wọn padanu ẹmi.

Bakan naa lo rọ araalu lati ma ṣe gba iroyin ofege ti ko ba ti ọdọ NRC wa, ki wọn si maa tẹti leko fun bo ba ṣe n lọ lori iṣẹlẹ naa atawọn nnkan miran ti ileeṣẹ NRC ba fi n lede.

Ọna oju irin Warri-Itakpe yii jẹ ọna kan to so Delta, Edo ati ipinlẹ Kogi pọ.

Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo si maa n gba ibẹ lati ṣe ọrọ aje wọn lorilẹede yii.

Bi ijamba tuntun yii si ṣe ṣẹlẹ ti mu ipaya ba awọn eeyan to nigbagbọ ninu aabo to wa fun wiwọ ọkọ oju irin.

Ọkọ oju irin to yawọ atawọn ero to gbe, wọn duro sibi ti isẹlẹ naa ti waye

Oríṣun àwòrán, Screeshot

Awọn ijamba ọkọ oju irin to ti waye ri

  • Oṣu Kin-in-ni ọdun 2023: Ọkọ oju irin to n rin irinajo lati Warri lọ si Itakpe lo ya kuro loju irin ninu igbo kan nipinlẹ Kogi, to si mu ibẹru boju ijinigbe ba awọn arinrin ajo.Eeyan 148n ni ori ko yọ.
  • Oṣu Kẹjọ 2025: Ọkọ oju irin kan to ko ero pupọ, ya kuro loju ọna rẹ loju ọna Abuja si Kaduna.

Agbegbe Kubwa si Asham lo ti ṣẹlẹ, o si to ero ọkọ ẹgbẹta (600) ti wọn ko jade nibẹ.

  • Loṣu Kọkanla ọdun 2025, wọn da iṣẹ duro fun igba diẹ loju ọna Warri-Itakpe kan naa, nigba ti ọkọ oju irin kan ya kuro loju ọna nitosi Agbor.

Awọn alaṣẹ sọ pe ijamba igba naa ni nnkan lati ṣe pẹlu awọn to n ba oju ọna irin naa jẹ, bo tilẹ jẹ pe ẹnikan kan ko ku ninu iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni oju ọna yii ti koju iṣoro awọn nnkan ti wọn yoo fi ṣiṣẹ, ti wọn si tori rẹ ti ọna naa pa fun igba pipẹ ni 2025.

  • Oṣu Kẹta 2026: (Abuja-Kaduna): Ere asaju mu ki ọkọ oju irin fi ọna rẹ silẹ, eeyan to le ni mẹrindinlọgbọn (26) lo farapa.
  • Oṣu Kẹfa 2026 (Warri-Itakpe): Reluwee ya kuro loju ọna rẹ ni Kogi, ọpọ arinrinajo ni ko le tẹsiwaju ninu irinajo wọn, ọpọ lo si farapa.
Ọkọ oju irin to yawọ atawọn ero to gbe, wọn duro sibi ti isẹlẹ naa ti waye

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Awọn ohun to n fa ijamba ọkọ oju irin

Laarin ọdun 2019 si 2026, o ti to igba mọ́kàndínláàdọ́wàá, (189) ti ọkọ oju irin ti ya kuro loju ọna rẹ, gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe fi han.

Gẹgẹ bi akọsilẹ lati ọdọ NRC ati National Bureau of Statistics ṣe wi, awọn ti wọn n ba oju irin jẹ lati ji awọn nnkan ta nibẹ, lo wa nidii ijamba to n ṣẹlẹ naa ju.

Omiran maa n waye latari awọn irinṣẹ ti ọjọ ti lọ lori won, ti ileeṣẹ naa n lo, pẹlu aṣiṣe to le ti ọwọ ọmọniyan wa.