Àṣírí abilékọ̀ tó jí ara rẹ̀ gbé, béèrè ₦50m owó ìtúsílẹ̀ tú, ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ̀ ẹ́ pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nílé ìtura

Arabinrin Oluchi to ji ara gbe wọn aṣọ ankara atawọn afurasi ọdaran ti wọn jọ ṣiṣẹ pọ

Oríṣun àwòrán, Edo State Police Command/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo ti fọwọ ofin mu arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Oluchi, atawọn mẹrin mii, lẹyin to sọ fun ẹbi rẹ pe oun ti bọ sọwọ ajinigbe, awọn ajinigbe si n beere ₦50m gẹgẹ bi owo itiusilẹ.

Ni ile itura kan lawọn ọlọpaa kogberegbe ti mu arabinrin naa pẹlu ọrẹkunrin rẹ, lẹyin to ti sọ pe wọn ji oun gbe.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, ASP Eno Ikoedem, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe lọjọ kinni oṣu Kẹfa yii isẹlẹ naa waye.

Atẹjade naa ni ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Tony Ugbowan to n gbe ni opopona Agbor niluu Benin, fi to ọlọpaa leti wi pe wọn ti ji iyawo oun, Arabinrin Oluchi Ugbowan, ẹni ọdun marundinlaadọta gbe lọ.

Ọgbẹni Ugbowan sọ fawọn ọlọpaa wi pe ẹnikan to pe oun lori foonu beere fun aadọta miliọnu naira gẹgẹ bi owo itusilẹ.

Agbẹnuṣọ ileesẹ ọlọpaa sọ pe ni kete tawọn gbọrọ naa ni awọn bẹrẹ iwadii lati mọ ibi ti obinrin naa le wa kawọn le doola rẹ.

ASP Ikoedem ni iṣẹ iwadii ọlọpaa lo jẹ kawọn fọwọ ofin mu ọkunrin kan to n jẹ Israel Ability ẹni ọdun mejidinlọgbọn lopopona Agbor.

O ni lọwọ Israel lawọn ti ri foonu Oluchi ẹni to ji ara rẹ gbe.

Iwe ikede ti wọn gbe jade, maa beere fun owo fun obinrin ti wọn ro pe ajinigbe lo ji i

Oríṣun àwòrán, mazitundeednut/Instagram

''Gbogbo afurasi ọdaran to ṣiṣẹ pọ pẹlu Oluchi ni ọwọ ileesẹ ọlọpaa tẹ bayii''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe Israel lo jẹwọ fun ọlọpaa wi pe Arabinrin Oluchi lo gbimọ pọ pẹlu oun wi pe koun beere aadọta miliọnu naira owo itusilẹ lọwọ ẹbi oun, lẹyin to ti puro wi pe wọn ti ji oun gbe.

O fikun ọrọ rẹ pe iṣẹ iwadii naa lo tun gbe awọn ọlọpaa de ile itura kan to wa ni ijọba ibilẹ Ukwani nipinlẹ Delta nibi ti wọn ti fọwọ ofin mu Oluchi.

Nigba ti wọn fọrọ wa Oluchi lẹnu wo ni o jẹwọ wi pe loootọ loun ji ara oun gbe lati gbowo, o si tun mu awọn ọlọpaa lọ si ile Ochukwudem Uwadia ẹni ọdun mejidinlogoji ti wọn jọ gbimọ pọ ṣiṣẹ naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ninu ile naa ni wọn ti ṣẹ fidio to ṣafihan bi wọn ti fokun so Oluchi lọwọ kawọn ẹbi rẹ le lọ wa owo wa.

Gbogbo afurasi ọdaran to ṣiṣẹ pọ pẹlu Oluchi ni ọwọ ileesẹ ọlọpaa tẹ bayii.

Ileeṣẹ ọlọpaa tun ri ibọn ninu ile ti wọn ti mu awọn afurasi naa.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Edo, CP Monday Agbonika, ti lu awọn ọlọpaa ti wọn ṣe aṣeyọri iṣẹ naa lọgọ ẹnu.

O wa kilọ fawọn araalu wi pe iwa ọdaran gidi ni ẹnikẹni to ba ji ara rẹ gbe hu labẹ ofin, iru ẹni bẹẹ yoo si foju wina ofin.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

"Oṣù mẹ́ta sẹ́yìn ni àwọn ajínigbé, tó jí àbúrò Adelabu gbé, tí háyà ilé àmọ́ wọn kò gbé ibẹ̀ títí ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn"

Ile ilẹ̀ ti àwọn ajínigbé tó jí àbúrò Adelabu gbé háyà.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti wo ile ti awọn ajinigbe, to jí aburo Adebayo Adelabu Pẹnkẹlẹmẹẹsi ati awọn ibeji rẹ,

Owurọ ọjọ Aje ana, ọjọ kẹjọ, osu kẹfa, ọdun ti a wa yii ni wọn wo ile àwọn ajínigbé náà.

Àdúgbo Lakoun to wa lójú ọna Ayegun Olojuoro ni ile àwọn ajínigbé náà wa nilu Ibadan.

Ilé-isé ìjọba to wa fun isẹ òde àti ìgbòkègbodò ọkọ pẹlu awọn ẹ̀ṣọ́ alaabo to wa nipinlẹ Oyo ni wọn ṣe agbátẹrù bí wọn ṣe wo ile naa.

Ile ilẹ̀ ti àwọn ajínigbé tó jí àbúrò Adelabu gbé háyà, ti ijọba ipinlẹ Oyo wo lulẹ

"Ijọba ti gbẹsẹ le ilẹ naa, ti ẹni ti oni ilẹ ba ni iwe asẹ ijọba, C of O, ijọba yoo gba a ẹni bẹẹ"

Ijọba ipinlẹ Ọyọ, nínú awijare rẹ to fi wo ile naa, ni òun wo ile naa ni tori pe oun ko fara mọ iwa ibajẹ rara bi o ti wulẹ ko kere mọ.

Ninu ọrọ rẹ, Kọmísánà fún isẹ òde àti ìgbòkègbodò ọkọ nipinlẹ Oyo, Abdul-Mojeed Mogbonjubola salaye pe, ijọba ko ni fi aaye gba ẹnikẹni lati da omi alaafia ipinlẹ Ọyọ ru.

Abdul-Mojeed fi kun pe, ile ti wọn wo yi maa kọ awọn onile to ku lọgbọ́n lati maa waadi ẹni ti wọn ba fẹ gba sile daada, ki wọn to gbé ilé fun iru ẹni bẹẹ.

"Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti gbẹsẹle ilẹ naa bayii, ti ẹni ti oni ilẹ naa ba ni iwe asẹ ijọba, C of O, ijọba ipinlẹ Ọyọ maa gba lọwọ iru ẹni bẹẹ."

Komisana fi kun pe, ojúṣe awọn ara àdúgbò ni lati mọ awọn ti wọn jọ n gbe ladugbo daada, nitori iru ọrọ bayi ni, ọrọ eto aabo ki n ṣe fun ẹnikan.

Kọmisana wọ inu ile naa, ki wọn to wo o

"Obirin to ni ile naa ko gbe pẹlu wa ni adugbo yii tori ilu Eko lo n gbe, ẹkọọkan ni o maa n yọju si Ile naa"

Lara awọn ti wọn ba ikọ iroyin ile-iṣẹ BBC Yoruba sọrọ, ni alaga awọn baba onile ni agbegbe naa.

Ẹni naa, ti ko darukọ rẹ sọ pe, lati bi osu mẹta sẹyin ni awọn ajinigbe naa ti haya ile ọhun sugbọn ti wọn kọ lati wa maa gbe ile naa.

O fi kun pe, bii ọsẹ meji ni wọn ṣẹṣẹ n gbe ninu ile naa, ti awọn ko si fura rara pe iru eniyan bayẹn ni wọn.

"Gbogbo wa ni a maa n lọ si ibi isẹ oojọ wa lati owurọ kutukutu, ti a ko si mọ ohunkohun to n ṣẹlẹ ni adugbo wa mọ."

Alaga awọn lanlọdu naa fi kun pe, obirin ti oni ile naa ko gbe pẹlu awọn ni adugbo naa tori ilu Eko lo n gbe, ẹkọọkan ni o maa n yọju si Ile naa.

Imam agba ni agbegbe naa, wa dupẹ lọwọ Gomina ipinle Ọyọ, onimọ-ẹrọ Seyi Makinde fun iṣẹ takuntakun wọn lati gba awọn ọmọ naa pada.

"Ko si ẹnikẹni to le ro pe iru adugbo bayii ni awọn ajinigbe naa wọlẹ sí"

Imaamu naa wa rọ awọn ọmọ ipinlẹ Ọyọ pe wọn nilo lati maa ranti pe oju lalakan fi n sọri, ki ọrọ aabo ipinlẹ Ọyọ le mọyan lori.

Adugbo ti ile ti wọn wo wa

Bawo ni isẹlẹ ijinigbe naa se waye?

Ti a ko ba gbagbe, ọjọ Aje to kọja ni awọn ajinigbe ji Busayo Adegoke John-Paul, to jẹ aburo minisita tẹlẹ ri fun ohun amusagbara, Adebayo Adelabu Pẹnkẹlẹmẹẹsi gbe ati awọn ibeji ọkunrin rẹ gbe.

Gomina ipinle Ọyọ, si fi da awọn araalu l'oju pe oun maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹsọ alaabo lati ri daju pe awọn eniyan naa gba ominira wọn.

Alẹ ọjọ abamẹta (Saturday) ni iroyin gbode kan pe awọn oṣiṣẹ alaabo yalu ile naa, ti wọn si gba iya ati awọn ibeji naa sillẹ lọwọ awọn ajinigbe naa.

Àkọlé fídíò, Ìjì òjò líle sí òrúlé, da ògiri wó nílé ẹ̀kọ́ girama ọgbọ̀n l‘Ogbomoso, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ n kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ ilé àlàpa

Àwọn agbébọn ṣèkọlù sínú oko, pa àgbẹ̀ mẹ́rìnlá

Awọn agbebọn to gbe ibọn da ni, fi aṣọ boju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Egbinrin ọtẹ bi a ṣe n pana ọkan ni omiran n ru.

Ko din ni agbẹ mẹrinla ti wọn ti padanu ẹmi wọn nigba ti awọn agbebọn tun ṣe ikọlu si awọn ilu meje ni ijọba ibilẹ Isa ati Sabon Birni, ipinlẹ Sokoto.

Iroyin ni niṣe ni awọn agbebọn naa lọ ṣe ikọlu sawọn agbẹ naa lasiko ti wọn n ṣiṣẹ oko lọwọ ninu oko wọn, eyi to ṣokunfa iku eeyan mẹrinla, to si tun da ipaya silẹ laaarin awọn araalu.

Họnọrebu Muhammad Sa'idu Bargaja to n ṣoju ẹkun Isa ati Sabon Birni ni ile igbimọ aṣojuṣofin ni ilu Abuja sọ fun BBC pe awọn agbebọn naa ṣọ igba ti ojo n rọ, tawọn agbẹ naa wa loko lati gbin ireke ki wọn to ṣe ikọlu naa.

O ṣalaye pe ilu Isa, Tidibale, Mansalawa, Tsabar, Hadawa, Masawa ati Gidan Nagor ani wọn ti ṣe awọn ikọlu naa.

O sọ pe yatọ si awọn ti wọn pa, niṣe ni awọn ajinigbe naa tun ji ọpọlọpọ eeyan gbe wọ inu igbo lọ.

Aṣofin naa sọ fun BBC pe ni ọsẹ to kọja ni awọn agbebọn naa ti kọkọ ṣọṣẹ, nibi ti wọn ti ṣe ikọlu sawọn eeyan, ti wọn si pa bii eeyan meje ni awọn ilu ọtọọtọ.

Awọn olugbe awọn agbegbe yii ni ikọlu yii lo n waye nigba lasiko ti eto ọgbin n bẹrẹ ni pẹrẹu, eyi to n da ibẹru sọkan awọn agbẹ lati jina soko.

Niṣe ni ibẹrubojo ti gbilẹ bayii pe o ṣeeṣe ki ipenija aabo to n ba Naijiria finra ni ipa lori eto ọgbin lọdun yii pupọ, paapaa ti ko ba si amojuto to peye lati fi da aabo bo awọn agbẹ.

Ki nipa ti aisi aabo le ni lori ipese ounjẹ ni ọdun yii?

Ipinlẹ Sokoto wa lara awọn ipinlẹ ni ẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria nibi ti awọn agbebọn ti n ṣọṣẹ julọ paapaa ni awọn ijọba ibilẹ to paala pẹlu orilẹ ede Niger Republic.

Lati bii ọdun diẹ sẹyin bayii ni awọn agbegbe bii Isa, Sabo Birni, Goronyo, Tangaza ati Gudu ti n koju ipenija ikọlu awọn agbebọn, ijinigbe eyi to ti mu ki ọpọ awọn araalu sa fi ile won silẹ.

Ipenija aabo naa ko mọ ni ipinlẹ Sokoto nikan, niṣe ni awọn ipinlẹ Zamfara ati Katsina ti wọn paala pẹlu Sokoto naa n koju ijinigbe lati fi gba owo, ipaniyan ati ikọlu awọn agbebọn ni gbogbo igba.

Awọn onimọ atawọn alaṣẹ ti fori ipenija sọ aisi aabo to peye lawọn ilu ẹsẹ kuku, bi lilo ohun ija ṣe di tọrọ fọnka sile ati ayipada si igbeaye awọn ni ẹsẹ kuku.

Bakan naa ni wọn ṣekilọ pe ikọlu gbogbo igba sawọn agbẹ maa ni ipa lori ipese ounjẹ ni ọdun yii nitori bi ibẹru ko ṣe jẹ kawọn agbe lọ dako.

Ọpọ awọn olugbe agbegbe yii lo ti ke pe ijọba atawọn ẹṣọ aabo lati ji giri si ojuṣe wọn, ki wọn pọnku igbesẹ wọn lati da aabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan, ki wọn si pese aabo to peye fawọn agbẹ ki asiko ọgbin to wa sopin.