Kí ló dé tí ìjọba àpapọ̀ fi ₦9trn kún owó ìṣúná ọdún 2026?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Tinubu ti ke si ile igbimọ aṣofin Naijiria ko buwọlu owo ti iye rẹ to N9.09tn gẹgẹ bii afikun eto iṣuna ọdun 20206 yii.

Ijọba ni owo ti oun ba pa lori ele ori epo rọbi latari ogun ti Amẹrika ati Israel n gbe ti Iran ati owo ti oun ba ya loun yoo fi gbọ bukata eto iṣuna naa.

Ana ọjọ Iṣẹgun ni Aarẹ ile aṣofin agba, Godswill Akpabio ka lẹta Tinubu kọ nipa afikun naa niwaju awọn aṣofin.

Tinubu ṣalaye ninu lẹta naa pe igbesẹ ọhun ko ṣẹyin ọna ati sin ọmọ Naijiria daadaa nipa pipese awọn ohun amayedẹrun fun wọn.

Lẹta naa sọ siwaju si pe afikun owo naa yoo ran ijọba lọwọ lati san awọn gbese kan to ti wa nilẹ.

Ẹwẹ, ile aṣofin ti buwọlu ẹbẹ Aarẹ naa bayii, eto iṣuna ọdun 2026 si ti di N68.32tn lati N58.18tn ti Aarẹ kọkọ daba rẹ ṣaaju.

Awọn aṣofin ọhun sọ pe bibuwọlu atunṣe si eto iṣuna yii yoo ran ijọba apapọ lọwọ lati ṣe awọn ojuṣe rẹ fun ọmọ Naijiria ati lati ṣatilẹyin to yẹ fun eto idibo ti yoo waye lọdun 2027.

Alaga igbimọ ro n ri si afikun naa nile aṣofin Solomon Adeola ni afikun ọhun ṣe pataki fun ọrọ aje Naijiria latari ọwọngogo to gbode lasiko yii.

Ṣaaju ni Tinubu ti kọkọ gbe N58.18tn lọ siwaju awọn aṣofin ọhun lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2025, eyii to pe orukọ rẹ ni "Budget of Consolidation, Renewed Resilience and Shared Prosperity."

Tinubu sọ lọjọ naa pe eto iṣuna naa yoo mu ki ijọba le ṣe awọn nnkan to yẹ fun igbayegbadu ọmọ Naijiria.

Gẹgẹ bii awọn aṣofin naa ṣe sọ, nnkan bii ida 70% ohun to yẹ ki ijọba ṣe lọdun 2025 ni ko le gbe ṣe latari ọwọngogo, eyii to mu ki awọn iṣẹ naa tun fi sinu owo to yẹ ki ijọba na lọdun 2026 yii.

Diẹ lara awọn ohun to wa ninu afikun naa

Lara nnkan to wa ninu owo ti awọn aṣofin buwọlu yii ni N8.96bn fun atunṣe ọna Calabar si Maiduguri ati ti Maiduguri si Sokoto.

Ni ẹka eto ilera, ijọba ṣe afikun N482.76bn si eto iṣuna rẹ.

Lara owo ti wọn ya sọtọ fun ẹka eto idajọ ni N98.5bn fun ile ẹjọ kotẹmilọrun, N36.7bn fun ile ẹjọ to ga julọ ati N268.54bn fun yiyan awọn adajọ tuntun ṣaaju eto idibo ọdun 2027.

Awọn aṣofin naa sọ pe eyii ṣe pataki nitori awọn adajọ ni yoo yanju gbogbo kudiẹ-kudiẹ to ba ṣẹyọ lẹyin eto idibo naa lọdun 2027.

Wọn ni igbagbọ wa pe $10 yoo gun ori agba epo rọbi kan lagbaye, eyii ti yoo pa owo ti iye rẹ to N2.592tn wọle sapo ijọba Naijiria.