You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
A ti yanjú aáwọ̀ láàárín Makinde àti Olubadan-Ìgbìmọ̀ ọmọ Ibadan
Igbimọ awọn ọmọ bibi ilu Ibadan, labẹ akoso apapọ ẹgbẹ kan ti a mọ si Central Council of Ibadan Indigenes (CCII), ti ni awọn ti yanju aawọ to wa laaarin gomina Seyi Makinde ati Olubadan Rashidi Adewolu Ladoja.
Atẹjade ni CCII fi sita lo kede eyi, Aarẹ wọn, Amofin Sulaimon Ajeniyi Ajewole si buwọ lu u.
Ninu atẹjade to jade lọjọ Aiku naa ni igbimọ awọn ọmọ ilu Ibadan ti sọ pe asọye ti waye, awọn si tun lo ilana ibilẹ lati yanju awuyewuye to gbode nipa iyọni-nipo ọba ati ipo gomina ni gbogbo ọsẹ to kọja.
Kí ló fa aáwọ̀?
Tẹ o ba gbagbe, Ayo Fayose to jẹ gomina Ekiti nigba kan lo ke ibosi lọjọ kejila oṣu Kẹrin yii, loju opo X rẹ, pe Gomina Seyi Makinde fẹ yọ Olubadan Ladoja kuro nipo.
Fayose sọ pe ẹṣẹ ti Ladoja ṣẹ Makinde ni pe ko yọju sibi ti gomina ti fi awọn oloye Ibadan mẹta jọba lai jẹ pe awọn ọba naa wa nikalẹ.
Ko pẹ lẹyin eyi ni ọrọ tun yipada, ti wọn ni Olubadan Ladoja gan-an lo n pete ati yọ Gomina Seyi Makinde kuro nipo, nipa lilo Adebo Ogundoyin to jẹ Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Oyo .
"A ti kapa awọn to fẹẹ sọ ọrọ naa di awuyewuye''
Gẹg bi igbimọ CCII to wa nipo giga ju nilẹ Ibadan ṣe ṣalaye, wọn ni awọn ikọ alagbara ita to fẹẹ sọ ọrọ yii di ariwo ti mu òfo, nitori awon ti gba agbara lọwọ wọn.
Bakan naa ni igbimọ ọmọ Ibadan yii sọ pe ko si nnkan kan to n jẹ igbiyanju tabi ète iyọnipo ninu ohun to ṣẹlẹ.
CCII ṣalaye pe ohun to n jẹ ede aiyede laaarin gomina ati Olubadan ti di nnkan igbagbe, nitori ọrọ ajọsọ ti waye,
awọn si tun ti lo ilana ipari ja ni ibamu pẹlu ti ilẹ Ibadan.
"Ọrọ to wa laaarin Gomina Makinde ati Olubadan ti yanju, awọn alagbara ita to si fẹ da wahala silẹ ni a ti gba agbalọwọ wọn.
"Ko sẹni to fẹẹ yọ Gomina Makinde nipo, ko si sẹni to fẹẹ yọ Olubadan kuro lori itẹ rẹ."
Bẹẹ ni atẹjade naa wi.
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Tẹ o ba gbagbe, o ti to ọjọ meloo kan ti awuyewuye ti n gbode, pe aarin Gomina Seyi Makinde ipinle Oyo ati Olubadan Rashidi Ladoja ko gun rege bo ṣe yẹ.
Ko tile too di pe Ayo Fayose ke gbajare tiẹ ni awon kan ti n gbe e kiri, bo tilẹ jẹ pe ko fi bẹẹ rinlẹ bii ti asiko yii.
Ṣugbọn igun mejeeji maa n sọ pe ko si nnkan to jo ija laaarin awon.
Nigba ti oro oba ti Makinde fi awon oloye Ibadan mẹta jẹ sẹlẹ, ti Olubadan to yẹ ko jokoo bii baba awon ọba naa ko si nibe, ọpọ eeyan lo sọ pe nitori aarin rẹ ati gomina ti ko gunrege naa ni.
Ṣugbọn Olubadan sọ pe ko si rogbodiyan kankan laaarin oun ati gomina nigba naa.
Ohun ti ọpọ eeyan n sọ lori ayelujara nigba ti ọrọ naa ṣẹlẹ ni pe bi ko ba si ina to n jo nibi kan, eefin ko le si.
Won ni bi ko ba je pe nnkan kan n sẹle laaarin Olubadan ati Gomina, awọn akiyesi kan ko ni I maa waye.
Ni bayii saa ti igbimo CCII ti ni oun ti pari aawọ yowu ko le wa laaarin Olubadan ati Makinde, ohun to n lọ lori ayelujara ni pe olóye ni ọro yoo maa yé lọ́jọ́kọ́jọ́, ko le ye awon omugọ eeyan.