You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Alaafin ní kí Aare Onakakanfo gbé ìgbésẹ̀ lórí ètò àbò ilẹ̀ Yoruba, kí ni òfin sọ?
Alaafin ke si Aarẹ Ọnakakanfo ko wa nnkan ṣe eto abo ilẹ Yoruba
Alaafin ilu Oyo, Ọba Akeem Owoade, ti ke si Aarẹ Ọna kakanfo, Iba Gani Adams lati wa nnkan ṣe si eto abo to mẹhẹ nilẹ Yoruba.
Ọrọ yi lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Alaafin, Ademola Adeniyi, fi lede.
Ninu atẹjade naa ni Alaafin ti rọ Gani Adams lati bẹrẹ ijiroro pẹlu awọn ori ade nilẹ Yoruba lori ọna abayọ si eto abo naa to mẹhẹ.
Owoade sọ pe igbesẹ ọhun ṣe pataki lasiko yii ki nnkan to buru ju bo ṣe wa lasiko yii lọ.
Atẹjade naa sọ pe "Mo gba Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams lamọran ko bẹrẹ ijiroro bi wọn ṣe le lo ọna ibilẹ lati koju eto abo pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọba alade, olori ilu atawọn ti ọrọ eto abo kan ki eto abo to mẹhẹ le di ohun atijọ nilẹ Yoruba.
"Nibi ti ọrọ de duro yii, a rọ awọn araalu ki wọn maa ṣe sun gbera, ki wọn maa tẹlẹ ofin, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro.
"Ẹtọ gbogbo araalu ni lati maa gbe layọ ati alaafia, dandan si ni ki wọn ni eto abo to dara."
Ki ni ofin sọ lori ọrọ Alaafin yii?
BBC Yoruba kan si amofin Olusegun Kofoworola lati ileeṣẹ Lincs Attorneys lati mọ ipo ofin lori irufẹ ipe bayii.
Nigba to n sọrọ, Kofoworola sọ pe labẹ ofin Naijiria, ijọba apapọ nikan lo lẹtọọ lati da si eto aabo, eredi ree ti gbogbo awọn ileeṣẹ ati ẹka eto abo fi wa labẹ rẹ.
Ninu alaye rẹ, awọn orilẹede kan bii Amẹrika gba awọn ijọba ipinlẹ laaye lati da si ọrọ eto abo, eredi ree ti wọn fi ni awọn ọlọpaa ipinlẹ bii New York City Police Department, NYPD, Los Angeles Police Department, LAPD, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ni Ijọba apapọ nikan, ati ile igbimọ aṣofin agba nikan lo le daba lori eto abo ni Naijiria.
Kofoworola sọ pe "Alaafin ilu Oyo ko lagbara, Gani Adams ko lagbara, gomina ipinlẹ gan ko lagbara lati sọrọ lori aabo."
Amọ ṣa o fi kun pe Alaafin tun lẹtọọ lati gbe igbesẹ eto abo lori awọn eeyan rẹ labẹ ẹka ofin to ni eeyan le daabo bo ara rẹ lọwọ ẹni to ba fẹ ṣe ijamba si, iyẹn 'right to self defence.'
Amofin ọhun sọ pe irufẹ eeyan bẹẹ le lo oogun abẹnugọngọ lati daabo bo ara rẹ, o tun le lo awọn ohun ija bii ibọn amọ wọn gbọdọ gba aṣẹ ijọba ki wọn to le lo ibọn.
O ni "Ofin to gba wọn laaye lati ṣe bẹẹ lo rọ mọ ofin to gba awọn adugbo laaye lati ni fijilante fun abo ara wọn."
Afurasí darandaran ṣá Olóyè ìlú Ibadan pa, ṣèlérí láti padà wá fún ìkọlù míì
Lẹyin nnkan bii ọsẹ mẹfa ti awọn agbebọn ṣọṣẹ ni Ori Apata, to wa ni ijọba ibilẹ Ido, nipinlẹ Oyo, iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe wọn tun ti gbẹmi oloye kan nipinlẹ naa.
A gbọ pe Aba Asa, to wa lagbegbe Omi Adio, niluu Ibadan ni wọn ti gbẹmi oloye ọhun to jẹ agbẹ.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe inu oko ni Oloye Mutairu Oladosu, to jẹ Otun Balogun Okelade Okin wa ki awọn afurasi Fulani darandaran to gbẹmi rẹ sibẹ.
Iyawo oloogbe naa ati ọmọ rẹ obinrin ti wọn wa nibẹ lasiko ikọlu ọhun ṣalaye pe awọn ri awọn Fulani meji ti wọn n da ẹran jẹko lori ilẹ baba awọn.
Lẹyin naa ni Oladosu kilọ fun wọn ki wọn kuro lori oko oun.
Asiko to n ni itakurọsọ pẹlu awọn darandaran naa ni awọn darandaran meji mii jade lati inu igbo ti wọn si bẹrẹ si n fi oogun ati ada le iyawo ati ọmọ rẹ obinrin naa ti ọjọ ori rẹ ko tii pe ogun ọdun.
Iyawo ati ọmọbinrin oloogbe naa sọ pe ori lo ko awọn yọ ti wọn to lugọ sinu igbo kan.
Lẹyin ti awọn darandan naa ri pe awọn ti moribọ lọwọ wọn ni wọn pada lọ kọlu Oloye Oladosu ti wọn si ṣa lada pa.
Iyawo oloogbe ọhun ni inu igbo ti oun wa loun ti n wo bi wọn ṣe n ṣa ọkọ oun ti ko si si ohun nnkankan ti oun le ṣe nipa rẹ.
Obinrin naa to ti di opo bayii sọ pe oun ko le pariwo ki awọn darandaran naa ma baa ṣa oun ati ọmọ oun pa.
O ni lẹyin ti wọn gbẹmi ọkunrin naa tan ni wọn na papa bora ki awọn eeyan abule ọhun to de ibẹ.
Awọn eeyan abule ọnaa ni ọlọpaa ti mu awọn afurasi ọhun bayii amọ awọn ko ni igbagbọ ninu ileeṣẹ ọlọpaa lati ri idajọ ododo gba.
Ọkan lara awọn agbagba abule naa sọ fun awọn akọroyin pe awọn darandaran ọhun ti ṣeleri lati pada lọ ṣọṣẹ nibẹ, eyii to mu ki wọn maa rawọ ẹbẹ si ijọba fun iranlọwọ.