You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ fura o! Ayédèrú ọṣẹ ìfọyín Colgate tó lé ṣàkóbá fún ara ti wà lórí igbá káàkiri - NAFDAC
Ajọ NAFDAC to n ṣakoso ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria ti kede pe ayederu ọṣẹ ifọyin Colgate ti wa lori igba kaakiri.
NAFDAC ṣalaye loju opo X rẹ wi pe awọn eeyan kan lo ta ajọ naa lolobo wi pe ayederu Colgate ti wa lori igba ni Kaduna.
Ajọ naa ni oṣiṣẹ awọn meji lo ṣabẹwo si ibi ti wọn ti n ta ayederu Colgate naa nibi ti wọn ti fi idi rẹ mulẹ pe otitọ ni ọrọ naa.
Awọn oṣiṣẹ NAFDAC meji naa ni awọn ri ayederu "Coglaet ActivGel 100g" ati "Coglaet Herbal 100g'' nibi ti wọn ti n ta a ni Kaduna.
Ẹni to n taja ni ṣọọbu ọhun ṣalaye pe lọwọ aṣoju ileeṣẹ to n ṣe ọṣẹ ifọyin Colgate to maa n kiri ọja kaakiri loun ti ra Colgate ọhun.
Amọ, ko ni ẹri lati fi idi ibi ti o ti ra ọṣẹ ifọyin naa mulẹ.
NAFDAC ni irufẹ Colgate naa ko koju oṣunwọn, ati pe ileeṣẹ to n ṣe e ko forukọ ọṣẹ ifọyin naa silẹ pẹlu ajọ NAFDAC.
Ajọ naa wa sọ pe ọṣẹ ifọyin Colgate yii le ṣakoba fun ilera ara.
NAFDAC ni awọn ti ko ayederu Colgate tawọn ṣawari naa kuro lori igba, nigba ti iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn to n ta ayederu ọṣẹ ifọyin naa.
Ajọ NAFDAC ṣalaye wi pe ayederu Coglaet Crema Dental Herbal 100g" ati "Coglaet ActivGel 100g tawọn ṣawari naa ko ni ontẹ NAFDAC.
Guangzhou YECAI lo ṣe ayederu ọṣẹ ifọyin Colgate naa - NAFDAC
Ajọ NAFDAC ni ileeṣẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ Guangzhou YECAI Oral Cleaning Products Co., Ltd, to wa ni Baiyun District, Guangzhou lorilẹede China lo ṣe ọṣẹ ifọyin naa loṣu Kẹjọ ọdun 2025.
Oṣu Kẹjọ ọdun 2029 si ni wọn kọ sara rẹ wi pe yoo bajẹ.
Ni bayii, gbogbo awọn ọga agba NAFDAC lawọn ẹkun kaakiri Naijiria ni ajọ naa ti sọ fun pe ki wọn ṣawari irufẹ ọṣẹ ifọyin naa lagbegbe ti wọn wa ki wọn le ko o kuro lori igba.
Bakan naa tun ni ajọ NAFDAC rọ awọn ontaja lati ṣe iwadii irufẹ ọṣẹ ifọyin ti wọn ba fẹ ra ki wọn ra a sori igba.
NAFDAC tun rọ araalu lati fi to ajọ naa leti ti wọn ba kẹfin ayederu ọja nibi kibi.
Ajọ naa tun rọ awọn oṣiṣẹ eleto ilera lati fi to ajọ naa leti ti wọn ba ri ẹnikẹni ti ayederu Colgate naa ba ti ṣakoba fun.