Sunday Igboho sọ ìdí tí ìjọba ṣe kọ̀ láti sanwó ìtúsílẹ̀ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X
Ni bayii ti ọpọ eeyan kaakiri agbaye n dunnu lẹyin itusilẹ awọn olukọ ati akẹkọọ Oriire nipinlẹ Oyo, ajijagbara fun Yoruba Nation lasiko kan, Sunday 'Igboho' Adeyemo ti ṣalaye eredi ti ijọba fi kọ lati ṣe ohun ti awọn agbesunmọmi naa bere fun.
Gẹgẹ bii ọrọ Igboho, ti ijọba ba fun awọn agbesunmọmi naa ni nnkan ti wọn bere, yoo ṣe iwuri fun wọn lati tẹsiwaju lati maa ji awọn eeyan gbe kaakiri Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti Igboho fi lede lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, o ni Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe ko tọ lati maa san owo itusilẹ fun awọn agbesunmọmi ati pe kii ṣe ohun to bojumu lati maa tu agbesunmọni silẹ lati paarọ ẹni ti wọn ji gbe.
O ni ṣiṣẹ eyii yoo fun awọn agbesunmọmni ni igboya kaakiri Naijiria lati maa ṣọṣẹ.
Ọjọ karundilogun, oṣu Karun un ọdun 2026 yii ni agbesunmọmi ya bo awọn ile ẹkọ Community Grammar School, Ahoro-Esinele; LA Primary School; ati Baptist Nursery & Primary School, Yawota, ti wọn si ji awỌn eeyan naa gbe lọ sinu igbo kijikiji.
Igboho ninu ọro rẹ gboriyin fun ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati ko awọn ọmọ naa ati olukọ wọn paa wale.
O ni aṣeyọri naa "ko mu idunnu ba awọn mọlẹbi awọn eeyan naa nikan, o tun ti ru igbagbọ awọn ọmọ Naijiria soke ninu afojusun ijọba apapọ lati gbogun ti iwa ọdaran lawujọ.
"O ṣe pataki ka dupẹ lọwọ minisita fun eto abo Naijiria ajagunfẹyinti Christopher Musa, ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, Tunji Disu, ileeṣẹ ologun, olubadamọran pataki si Aarẹ lori eto abo, ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ati gbogbo olori awọn ileeṣẹ eto abo miran fun ifọwọsowọpọ wọn lati jẹ ko ṣeeṣe lati gba awọn eeyan naa silẹ.
"Lati igba ti wọn ti ko awọn akẹkọọ naa lọ ni Tinubu ko yi sinmi lati ri daju pe wọn gba itusilẹ.
"Mo fẹ sọ ni kedere ati lati jẹ ko ye awọn araalu pe ijọba ko sinmi ninu ojuṣe rẹ lati rẹyin gbogbo awọn ọdaran to n ṣọṣẹ ni Oke-Ogun, nipinlẹ Oyo ati ni gbogbo Naijiria lai si aniani.


























