Mo ta ‘Pure Water’ láti rán ara mi nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ ń kò parí rẹ̀, èmi tí wọ́n ń pè ní Olódo tẹ́lẹ̀, ló ń bọ́ bàbá àti ẹbí mi báyìí - Portable

Portable wọ aṣọ olomi ọsan to fi aya rẹ silẹ pẹlu fila dudu lori, o si nawọ soke

Oríṣun àwòrán, Instagram/Portablebaby

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajugbaja akọrin takasufe, Habeeb Okikiola tawọn eeyan mọ si Portbale, ti sọ pe oun ti wọn maa n pe ni olodo ti ko mọ iwe tẹlẹ loun wa di ẹni to n bọ baba oun ati gbogbo ẹbi bayii.

Portable sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti o ṣe pẹlu awọn akọroyin ori itakun ayelujara.

Ọdọmọde olorin naa tun ṣalaye bi o ti gbiyanju lati lọ si ile ẹkọ ati bi nnkan ko ṣe rọrun fun un rara nigba naa.

Okikiola fikun ọrọ rẹ pe oun ta omi ''pure water'' lati le rowo ran ara oun lọ si ile ẹkọ girama tori awọn obi oun ko lagbara lati ran oun lọ si ile ẹkọ.

''Mi o le pari eto ẹkọ mi, mo maa n ta omi ki n le ri owo ile ẹkọ san nigba ti mo wa nile ẹkọ girama.

Mo n ṣe eleyii tori owo ile ẹkọ wọn, n ko si ri ẹni to le ba mi san owo naa,'' Portable lo sọ bẹẹ.

Ṣugbọn Portable tun fi idi rẹ mulẹ pe oun ti pada sile ẹkọ bayii, koda, o ni ẹkọ nipa imọ lori okoowo (Business Administration) loun n kọ nile ẹkọ Gbogbonṣe Kwara Poly to wa niluu Ilorin.

''Baba mi ran awọn buọda ati aunti mi lọ si ile ẹkọ, o maa n bami ninu jẹ tori ijọba ko fun wọn niṣẹ''

Portable ni ''mo maa kẹkọọ jade laipẹ tori akẹkọọ ni mi nile ẹkọ Gbogbonṣe Kwara Poly nibi ti mo ti n kẹkọọ lori imọ nipa okoowo siṣe.

Olodo ni wọn maa n pe mi ninu ẹbi mi tẹlẹ, amọ, emi ti wọn pe ni olodo ni mo wa n bọ gbogbo wọn bayii.''

Ọmọ Olalomi ko ṣai fi aidunnu rẹ han lori ipenija airiṣẹṣe to n koju awọn ẹbi rẹ ti wọn kawe.

''Baba mi ran awọn buọda ati aunti mi lọ si ile ẹkọ, o maa n ba mi ninu jẹ pe ijọba ko fun wọn niṣẹ tabi ṣe iranwọ kankan fun wọn.

Emi naa ni mo n bọ gbogbo wọn bayii.

Bakan naa ni wọn o ri iranwọ kankan gba lati ọdọ ijọba,'' Portable lo sọ bẹẹ.

Ta a ni Portable, Were Olorin, Idaamu Adugbo?

Ọmọ bibi ilu Abeokuta ni Habib Okikiola ti a mọ si Portable, amọ adugbo Sango Ota ni wọn bi si, to si gbe Mushin Olooṣa dagba.

Ni ipari ọdun 2021 ni Habeeb Okikiọla kan lu agbami orin takansufe kikọ, nigba ti orin to kọrin pẹlu gbajumọ olorin Ọlamide ati gbajumọ onijo kan, ti ọpọ mọ si Pocolee.

Orin Zeh to kọ naa, ti di gbajugbaja kaakiri agbaye, to si ti yi igbe aye rẹ pada.

Lati igba ti orin rẹ naa si ti di aigbọdọ maa kọ nibi ariya ati ile ijo gbogbo ati lẹnu tonile talejọ, Portable ti ṣe alabapade awọn agbaagba onkọrin bii Wizkid ati Davido.

Portable sọ fun BBC News Yoruba pe ọdun kẹẹdogun ree ti oun ti bẹrẹ isẹ orin kikọ amọ ọdun kẹwa ree ti oun ti di gbajumọ, ki Ọlọrun to wa ni ko orin Zeh.

Nigba to n salaye awọn ohun ti oju rẹ ti ri sẹyin, Portable salaye bi awọn eeyan bii ọdunrun se dawọ bo o, lati ja si ihooho ọmọluabi lori ẹsun pe o ji kẹkẹ Maruwa.