Àlàyé lóríi bí àjọ NDLEA ṣe mú afurasí ọmọ South Africa kan l'Abuja lórí ẹ̀sùn pé ó gbé oògùn olóró Heroin

Oríṣun àwòrán, NDLEA/X
Ajọ NDLEA to n gbogun ti oogun oloro ni Naijiria ti fọwọ ofin mu afurasi ọmọ orilẹede South Africa kan ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe l'Abuja lori ẹsun pe o gbe oogun oloro heroin sinu ẹru rẹ.
Oogun naa ni ajọ ọhun sọ pe o to iwọn 5.75 kg ti obinrin naa si tun gbe ọmọ lọwọ.
NDLEA ni ọmọ ọdun mẹta ti arabinrin naa gbe lọwọ lo fẹ fi boju ki aṣiri rẹ ma baa tu nibi ti wọn ti n ṣayẹwo fun un ni papakọ ofurufu ilu Abuja.
Lasiko ti ajọ NDLEA n ṣayẹwo awọn ero to rinrin ajo pẹlu baalu Qatar Airways lati Doha si Abuja ni ọwọ tẹ arabinrin naa.
Wọn ni arabinrin naa kọkọ sọ pe oun kọ loun ni ẹru ti oogun oloro wa ninu rẹ, amọ, iwadii pada fi idi rẹ mulẹ pe oun lo ni ẹru ọhun.
Nigba to ya ni obinrin naa jẹwọ wi pe oun loun ni baagi ti oogun oloro ọhun wa ninu rẹ.
Ajọ NDLEA ṣalaye ninu atẹjade kan ti o fi sita wi pe arabinrin ọmọ South Africa naa rinrin ajo lati Cambodia lọ si Doha nibi to ti wa si ilu Abuja.
Iwadii tun fi han pe obinrin naa n ṣiṣẹ pọ pẹlu ikọ kan to n gbe oogun oloro lati Cambodia si South Africa.
Ẹwẹ, NDLEA tun mu ọkunrin kan to n gun ọkada ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed MMIA niluu Eko lẹyin to wọ baalu Ethiopia Airlines de lati Madagascar.
Oogun oloro methamphetamine 87 ni wọn sọ pe afurasi ọhun fi pamọ sinu aṣọ rẹ.
Ọkunrin naa ni a gbọ pe o jẹwọ pe oun ti ṣiṣẹ ọkada gigun fun ọdun mẹẹdogun niluu Eko koun to darapọ mọ ẹgbẹ kan to n gbe oogun oloro ni Uganda.
Ọkunrin ọhun lo jẹwọ pe ṣaaju ni oun ti gbe oogun naa mi ti oun si rinrin ajo lọ si orilẹede Madagascar ṣugbọn awọn ẹṣọ to n ri si wiwọle si orilẹede naa ko jẹ koun raye wọle.
Bayii ni o morile ilu Eko nibi ti ọwọ ti tẹ ẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post



























