Gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ Esinele gba ìtúsílẹ̀

Awọn akẹkọọ ati olukọ to gba itusilẹ

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbogbo awọn akẹkọọ ati olukọ tawọn agbebọn ji gbe ni ilu Esinele ati Yawota ti gba itusilẹ.

Agbẹnusọ aarẹ Bola Tinubu, Bayo Onanuga fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade to fi soju opo X rẹ.

Onanuga ninu atẹjade naa sọ pe ọwọ awọn ẹṣọ aabo tẹ awọn afurasi agbebọn mẹjọ lasiko tawọn ẹṣọ aabo gba itusilẹ awọn akẹkọọ naa.

O fi kun pe awọn ko fun awọn agbebọn ni nnkan ti wọn n beere fun iyẹn itusilẹ ọga wọn kan to n koju igbẹjọ lọdọ ijọba apapọ fun awọn ẹṣẹ rẹ.

Awọn akẹkọọ ati olukọ to gba itusilẹ

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X

Onanuga ni awọn ẹṣọ aabo maa to fi iroyin lede lori bi wọn ṣe gba itusilẹ awọn eeyan naa

Ninu fidio kan ti Onanuga fi soju opo rẹ, ọlukọ agba ilẹ ẹkọ Esinele Rachael Alamu dupẹ lọwọ aarẹ fun akitiyan wọn lati gba itusilẹ wọn.

Alamu ni awọn dupẹ lọwọ aarẹ nitori awọn mọ riri bo ṣe mu aabo awọn ni ọkunkundun.

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ awọn ẹṣọ aabo fun gbogbo iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe, eyi to ni o ṣokunfa idi ti awọn ṣi fi wa laaye di asiko yii.

Ẹ o ranti pe Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn kọlu ile ẹkọ LA School ati Community High School, Ahoro-Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.

Awọn agbebọn naa pa olukọ kan, ji olori ile ẹkọ pẹlu awọn akẹkọọ ti iye wọn jẹ mẹrindinlaaadọta lọ nibi ikọlu naa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Lẹyin naa ni awọn agbebọn tun gbe fidio kan jade nibi ti wọn ti ṣafihan bi wọn ṣe bẹ ori olukọ mii lara awọn ti wọn jigbe.

Aarẹ Tinubu fi idunnu sawọn eeyan to gba itusilẹ kuro ni ahamọ ajinigbe

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu ti fi idunnu rẹ han lori bi awọn ẹṣọ aabo ṣe gba itusilẹ awọn akẹkọọ ati oluko tawọn agbebọn ji gbe ni Ogbomoso, ijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo.

Tinubu ninu atẹjade ti agbenusọ rẹ, Bayo Onanuga to kọkọ kede itusile awọn eeyan naa sọ pe gbogbo akitiyan awọn ẹṣọ aabo ileeṣẹ Ologun, ọlọpaa, DSS, ti wọn ti n ṣiṣẹ lati ọjọ mẹrindinlọgọta (56) tawọn eeyan naa ti w ani ahamọ ajinigbe ko ja si asan.

O ni inu oun dun pe wọn gba itusilẹ awọn eeyan naa lai padanu ohunkohun, ti wọn si tun ri mẹjọ mu ninu awọn ajinigbe naa.

Aarẹ ni o ṣeni laaanu pe awọn akẹkọọ ati olukọ naa, to fi mọ awọn ẹbi wọn koju irufẹ idaamu yii lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Bakan naa ni aarẹ tun gboriyin fun ijọba ipinlẹ Oyo fun bi atilẹyin ti wọn ṣe fun ijọba apapọ lori gbogbo erongba lati doola awọn eeyan naa.

Aarẹ tun ni parọwa si ijọba Oyo lati pese aabo to nipọn si gbogbo awọn ile ẹkọ to wa ni ipinlẹ naa lati dena irufẹ ikọlu bẹẹ lọjọ iwaju.

O fi kun pe ijọba oun maa sa gbogbo ipa lati fiya to tọ ati gbigba idajọ ododo lori fun awọn eeyan naa ati ẹbi olukọ Michael Oydeokun tawọn agbebọn pa si ahamọ wọn.

Aarẹ Tinubu tun dari awọn oṣiṣẹ ilera atawọn to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba ipinlẹ Oyo lati pese itọju to peye fun awọn eeyan to ṣẹṣẹ gba itusilẹ naa.