Ọwọ́ NDLEA tẹ ìyá àgbà ẹni ọdún 101 tó ń ta oògùn olóró ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Ajọ to n gbogun ti egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, ti fi ṣikun ofin mu iya ẹni ọdun mọkanlelọgọrun kan nipinlẹ nipinlẹ Ogun lori ẹsun pe o n ta oogun oloro.
Iya agba naa, Esther Ogunmabo sọ pe oun bẹrẹ owo ọhun lẹyin ti ina jo gbogbo ọja ti oun n ta tẹlẹ.
Lara awọn nnkan ti wọn kan mọ iya agba naa lọwọ lagbegbe Ilisan ni egboogi skunk ati igbo ti iwọn rẹ to 90 giramu.
Akara iya naa tu sepo lasiko ti awọn oṣiṣẹ NDLEA ya bo agbegbe rẹ lati mu awọn to n ta oogun oloro.
Lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ tan, iya naa jẹwọ fun NDLEA lai fi akoko ṣofo nipa bo ṣe bẹrẹ owo naa.
O ni ti oun ba ti ra a tan loun tun maa n tun ta fun awọn to n lo o ni kereje lẹyin ti ọja ti oun n ta tẹlẹ dojude.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi fi lede, o sọ pe ọkan lara awọn ọmọ obinrin ọhun to n gbe niluu Eko lo maa n ko ọja fun ni ọjọ mẹrin-mẹrin, ti oun naa yoo si maa ta a fun awọn onibara rẹ ladugbo.
Babafemi sọ pe awọn ko ti iya agba naa mọle nitori ọjọ ori rẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọga agba ajọ naa, ọgagun Buba Marwa ṣe agbeyẹwo bi ọwọ ṣe tẹ ẹ, o si paṣẹ ki wọn tọju rẹ daadaa nitori o ti di ogbo.
O ni Marwa paṣẹ pe ki wọn tu silẹ lai fi akoko ṣofo, ki wọn si maa ba sọrọ lati yi irori rẹ pada nitori ọjọ ogbo to wa.
Wayi o, bo tilẹ jẹ iya agba ọhun ko ni foju kan ọgba ẹwọn, NDLEA ti tọpin ọmọ rẹ to n ko ọja fun lati ilu Eko.
NDLEA ni lai fọta pe lawọn tọpinpin ọmọ rẹ obinrin to n ko ọja fun lọ siluu Eko nibi ti ọwọ ofin ti tẹ oun naa.



























