Kókó ọ̀rọ̀ tí Trump sọ tó milẹ̀ tìtì nibi ìpàdé àwọn olórí orílẹ̀-èdè àgbáyé l'Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump, sọrọ to milẹ titi nibi ipade awọn olori orilẹede to n lọ lọ niluu New York lAmẹrika.
Trump mẹnu ba orisiiriṣii nnkan bii ogun Russia ati Ukraine, ọrọ lori ọgbọn atọwọda ti wọn n pe ni AI to fi mọ ọrọ lori ogun to bẹ silẹ laarin Iran ati Amẹrika.
Wọnyi ni diẹ lara awọn nnkan ti Trump mẹnu ba ninu ọrọ rẹ.
''Ṣe ki n pa Iran rẹ ni, abi ko jọ sọ asọ yepọ?''
Trump beere bo ya adehun pẹlu Iran le jẹ ki orilẹede naa da si i ju ti atẹyinwa lọ.
O ni ki oun fi opin si orilẹede naa, abi koun tete ṣekupa awọn eeyan orilẹeede naa.
Aarẹ Amẹrika ni oun tun le pa gbogbo orilẹede naa rẹ ti ko si ni si orilẹede kankan ti wọn n pe ni Iran lọjọ iwaju.
Amọ, Trump ni oun gbagbọ wi pe awọn yoo pada buwọlu iwe adehun lẹyin eto idibo Amẹrika oṣu Kọkanla to n bọ.
Orukọ AI yoo yipada si SI
Aarẹ Trump tun sọ pe orilẹede Amẹrika ni akọkọ ti yoo kọkọ ṣe imọ ijinlẹ ọgbọn atawọda, iyẹn AI.
Trump ni oun ko fẹ orukọ ''atawọda ti wọn n pe AI tori o jẹ ko dabi nnkan ayederu.
Aarẹ Amẹrika ni kii ṣe nnkan ayederu rara, nnkan to lagbara gidi gan an ni AI.
Aarẹ wa sọ pe Amẹrika yoo yi orukọ AI pada si SI eyi to tumọ si ''Super Intelligence.''
Ìdí tí Trump fi fòfin de CNN àti iléeṣẹ́ ìròyìn méjì mii ní White House
Aarẹ Donald Trump orilẹede Amẹrika ti kede pe oun ti fofin de ileeṣẹ iroyin CNN, MS NOW ati Politico ni ileeṣẹ ijọba Amẹrika White House.
Trump ṣalaye loju opo X rẹ pe awọn ileeṣẹ iroyin naa maa n kọ irọ nipa ijọba oun ni gbogbo igba.
Amọ, aarẹ Amẹrika ko sọ apẹẹrẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin naa ti parọ nipa isẹjọba rẹ.
Trump ko ṣalaye bi ifofinde naa yoo ti ri, a o le sọ pe boya awọn akọroyin ileeṣẹ iroyin mẹta naa ko ni lanfaani lati wọ White House mọ.
Ẹwẹ, CNN ti ṣapejuwe ikede Trump gẹgẹ bi eyi to tako ominira ileeṣẹ iroyin Amẹrika ati igbesẹ to lodin sofin.
O ṣee ṣe ki kawọn ile iroyin tọrọ kan pe Trump lẹjọ lori ọrọ naa.
Awọn akọroyin CNN ati Politico si wa ni White House lẹyin ti Trump ṣe ikede naa.
Awọn akọroyin CNN tun ba Igbakeji Aarẹ Amẹrika JD Vance rinrin ajo lọ si Iowa.
Ileeṣẹ iroyin MS NOW ti wọn n jẹ MSNBC tẹlẹ kọ lati sọrọ.
Awọn alaṣẹ CNN ṣalaye ninu atẹjade kan ti wọn fi sita wi pe ikede Trump lodi sofin, wọn ni awọn wa lẹyin awọn akọroyin awọn to n ṣiṣẹ ni White House.
''CNN ni ẹtọ labẹ ofin Amẹrika lati ṣiṣẹ wa eyi ti ijọba ko si lẹtọọ lati ṣe idiwọ kankan fun wa.
Ti Trump ba tẹsiwaju lati fofin de awọn akọroyin wa ni White House, eyi ṣe ilodi si ẹtọ wa to wa ninu iwe ofin Amẹrika,'' CNN lo sọ bẹẹ.
Ileeṣẹ iroyin Politico naa sọ pe awọn yoo tṣiwaju lati maa ṣiṣẹ awọn ni White House.
Bakan naa tun ni ileeṣẹ iroyin naa sọ pe awọn yoo gbija ara awọn pẹlu ofin ti Trump ba ni kawọn akọroyin awọn ma lọ White House mọ.
Trump sọ pe ''Ko yẹ kawọn ileeṣẹ iroyin maa kọ irọ ninu iroyin wọn nipa aarẹ orilẹede Amẹrika tabi ijọba Aarẹ Trump tabi orilẹede Amẹrika gan an.''
Trump ko ṣalaye iroyin kan pato gẹgẹ bi apẹẹrẹ ninu ọrọ ti o kọ soju opo rẹ lori ayelujara naa.
Aarẹ ẹgbẹ awọn akọroyin White House, Jacqui Heinrich, sọ pe oun wa lẹyin awọn akẹgbẹ oun ti ijọpa yan ṣọju.
''Ọrọ yii kii ṣe nipa ẹtọ awọn akọroyin nikan, o niṣe pẹlu ẹtọ awọn eeyan Amẹrika lati gbọ iroyin lori gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ ni ọfiisi aarẹ Amẹrika,'' Heinrich ṣalaye.
Lati igba ti Trump ti bẹrẹ ijọba rẹ fun saa keji gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Amẹrika ni gbọmisii-omi-o-to ti n wa laari oun atawọn akọroyin White House.
Ti ẹ o ba gbagbe, Trump fofin de akọroyin CNN, Jim Acosta wi pe ko ma wa si ileeṣẹ ijọba White House mọ ni saa akọkọ rẹ gẹgẹ bi aarẹ Amẹrika.
Amọ ileeṣẹ CNN gbe e lọ si ile ẹjọ nigba naa, wọn si da a pada.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post




























