Aráàlú gbé okú gènde márùn-un tó kú sómi lọ sílé ìjọba fún ìdájọ́ òdodo

Oríṣun àwòrán, SUKUBO SARA-IGBE SUKUBO
Fun bi wọn ṣe padanu ẹmi won ninu ijamba ọkọ oju omi to danu, awọn eeyan ilu Kula, nijọba ibilẹ Akuku Toru, ipinlẹ Rivers, ti gbe oku gende marun-un lọ sile ijọba ibẹ, lati beere idi ti ijọba ko fi ṣe ojuṣe rẹ, ti iku fi mu awọn eeyan awọn lọ loju agbami.
Iṣẹlẹ yii waye l'Ọjọbọ, ọjọ kejilelogun oṣu Kẹwaa ọdun 2026.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Ijamba ọkọ oju omi kan lo sẹlẹ logunjọ oṣu Kẹwaa yii, loju odo Robertkiri, ipinlẹ Rivers.
Awọn ọkọ oju omi meji ti ijamba ọhun kan ni tugboat ati ọkan ti wọn pe ni speedboat.
Ọkọ tugboat yii ti awọn ṣọja kan tẹle n lọ lati gbe agba epo ti iwọn rẹ to igba (200,000-barrel capacity oil vessel), eyi ti ileeṣẹ kan, Ibeto Group n ṣakoso rẹ lati bii ọdun meji ti won ti n ṣiṣẹ ni agbegbe naa.
Awọn eeyan ilu Kula ko fẹ ki wọn gbe agba epo naa, apẹja ni pupọ awọn eeyan naa, eyi ni wọn si ṣe dide lati fi ẹhonu han.
Ohun ti a tun fidi rẹ mulẹ ni pe awọn ọrọ kan wa ti awọn to ni ileeṣẹ naa ko ti I yanju pẹlu awọn araalu.
Bayii ni awọn araalu gbe ọkọ wọn soju agbami, eeyan mẹẹẹdogun (15) lo wa ninu ọkọ naa, ti wọn fẹ dena awọn to fẹ gbe agba nla naa kọja lagbami.
Amọ ọkọ naa pada danu, awọn mẹjọ yè nigba ti ọkọ danu, nigba ti awọn meje ku somi.
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, oku awọn gende marun-un ninu meje ni wọn ti ri yọ lodo, awọn naa ni wọn si gbe lọ sile ijọba ipinlẹ Rivers, ati si ọdọ kọmiṣanna ọlọpaa ibẹ, lati beere ẹjẹ wọn lọwọ ijọba.
Wọn ko ti i ri oku awọn meji yoku titi ti a fi pari iroyin yii.
Ki lo da ọkọ araalu nu?

Oríṣun àwòrán, SUKUBO SARA-IGBE SUKUBO
Olori ọdọ ilu Kula, Sukubo Sara-Igbe Sukubo, ṣalaye fun BBC pe agba epo MV ANAMBRA to gbe epo ti da epo rẹ soju omi awọn latari ai ṣe ohun to tọ awọn to ni ileeṣẹ naa.
O ni epo naa si ti ṣe akoba fun odo awọn lagbegbe Kula.
Eyi lo ni o jẹ kawọn araalu fi ẹhonu han, ti wọn si n beere owo gba ma binu ati iṣẹ nipasẹ agba epo OML 55 to wa niluu awọn.
Sara-Igbe sọ pe logunjọ oṣu Kẹwaa yii, awọn gbọ pe wọn ti fẹ wa gbe agba naa lọ, eyi lo mu ki araalu korajọ.
"O ya wa lẹnu nigba ta a ri I ti wọn lọ gbe awọn ṣọja wa lati Sector 3 Command, Okrika, ti wọn fẹ ki wọn lewaju agba epo naa jade, a kora wa jọ.
"Ọkan lara awon ṣọja yen wa n ba wa sọrọ, a si sọ fun wọn pe ọba wa ti yanju ọrọ naa, a ni ki wọn ṣe ọhun to yẹ ki wọn ṣe ki wọn too le gbe agba naa.
"Ba a ṣe n sọrọ lọwọ, ṣọja kan na ibọn rẹ si awakọ tugboat, o si paṣẹ fun un pe ko maa wa ọkọ naa lọ.
"Bo ṣe ṣina si ọkọ naa bayii, okun to so ọkọ naa ati agba pọ ràn, o si da ọkọ naa nu.
"Ọkọ tugboat keji ko mọ ohun to ṣẹlẹ, oun kan fa agba ni, bi agba yẹn ṣe tẹ ọkọ to ti danu naa mọlẹ loju omi niyẹn."
Eyi lo fa iku awọn eeyan meje bi olori ọdọ ilu Kula naa ṣe wi.
"A fẹ idajọ ododo fawọn ọmọkunrin wa"
Sukubo Sara-Igbe Sukubo to tun jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn ọdọ ni Naijiria, sọ pe awọn n wa idajo ododo fun iku ai nidii to pa awọn gendekunrin yii.
"Tori ẹ la ṣe gbe oku wọn lọ ba wọn nile ijọba Rivers, ni Port Harcourt, ati sọdọ kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Rivers.
"Inu ọfọ ni ilu wa wa, awọn eeyan n sunkun ọmọ wọn ọkunrin, ẹgbọn wọn, aburo wọn, ọkọ wọn ati baba wọn.
"A o ni I gba ki wọn kan ku bẹẹ yẹn la ṣe gbe wọn wa, pe ki Gomina ri ohun to n ṣẹlẹ, a fẹ ki wọn ri I daju pe ẹni to ni agba epo yẹn ko lọ lai jiya."
Ki ni ijọba Rivers wi?
Gomina Siminalayi Fubara ti olori awọn oṣiṣẹ rẹ ṣoju fun, ba awọn eeyan naa kẹdun ohun to ṣẹlẹ si wọn.
O ni oun fi da awọn eeyan Kula loju, pe awọn to yẹ ko wadii iṣẹlẹ yii yoo tu iṣu rẹ de isalẹ ikoko.
"Ijọba ipinlẹ Rivers ko ni I sinmi titi ta o fi ri opin ọrọ yii. Ẹnikẹni to ba lọwọ ninu ijamba naa yoo jiya to tọ si i.
" A ko ni I maa woran kawọn ọmọ ilu Rivers maa jẹ iru iya yii, ki wọn maa koju ijamba ti ko yẹ ko waye rara. A ba awọn eeyan ilu Kula kẹdun. "
Ninu alaye tiẹ, Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Iyke Okoro to ba wọn sọrọ, sọ pe bi ijamba naa ṣe waye loju omi, ẹka ọlọpaa to n ri si ọrọ omi ni yoo gbọ ọ.
O ni ẹka naa ni yoo lewaju, Okoro sọ pe amọ nigba ti kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Rivers, Olugbenga Adepoju ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii, awọn yoo ri I pe iwadii to peye waye.
Ileeṣẹ tọrọ kan naa sọrọ
Max Shipping Services Ltd, ileeṣẹ ti iṣẹlẹ yii kan naa sọrọ latẹnu lọya wọn, Chidinma Ikenna.
Ileeṣẹ naa sọ pe:
'A ko lọwọ ninu epo to danu soju odo ati ijamba ọkọ oju omi to ṣẹlẹ.
Ikenna sọ pe Max Shipping Services Limited lo ni agba epo naa, amọ awọn kọ ni wọn n lo o fun iṣẹ.
O ni awọn ti ya Menal Technical Services Limited labẹ adehun kan tawọn ṣe logunjọ oṣu Kẹsan-an ọdun 2024.
Eyi lo ni iṣẹlẹ yii ko ṣe kan Max Shipping, bi ko ṣe Menal Technical Services.
Ṣaa, wọn ba awọn eeyan Kula kẹdun, amọ wọn ni ọwọ awọn ko si ninu ohun to ṣẹlẹ si wọn.

























