Ìjọba àpapọ̀ kéde ìpínlẹ̀ 26 tí òjò àrọ̀rọ̀dá yóò ti wáyé fún ọ̀sẹ̀ méjìlá èyí tí yóò fa ẹ̀kún omi

Oríṣun àwòrán, BBC/Mikail Musa
Ajọ to n ri si awọn adagun odo ti wọn fi n pese ina ni Naijiria, Nigeria Hydrological Services Agency, NiHSA, ti sọ pe ko jẹ iyalẹnu pe iṣẹlẹ omiyale waye nipinlẹ Eko atawọn ipinlẹ mii ni Naijiria lẹni lọlọ yii.
Ajọ ọhun ti wa kede pe ọsẹ mejila gbako ni awọn iṣẹlẹ naa yoo fi waye ni Naijiria ki saa ojo ti a wa yii to pari.
Ṣaaju ikede yii ni ajọ NIMET to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Naijiria ti kọkọ kede loju opo rẹ pe ipinlẹ mẹrindinlọgbọn kaakiri Najiria ni yoo ni ipin ninu iṣẹlẹ omiyale naa.
Adari ajọ NiHSA Umar Mohammed, ni awọn ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria ṣaaju iṣẹlẹ ọhun amọ gbogbo ikilọ awọn ni araalu kọ eti ọgbọin si.
NiSHA sọ pe "Gbogbo rẹ ni a ti ri ṣaaju, a si kilọ fu awọn araalu.
"Ojo arọrọda ati ẹkun omi naa yoo tun ṣe akoba fun omi ti awọn araalu n mu"
"Bi a ṣe n sọrọ yii pẹlu iṣẹlẹ ẹkun omi to n waye, ti a ko ba ṣe nnkanka nipa rẹ, ojo ṣẹṣẹ bẹrẹ si n rọ ni, nigba ti yoo ba fi di aarin oṣu Keje si oṣu Kẹsan an to jẹ ọsẹ mejila, yoo fẹ ẹ buru ju bo ṣe wa yii lọ.
"A gbagbọ pe yoo buru jọjọ ti yoo ba fi di inu oṣu Kẹjọ si oṣu Kẹsan an, paapaa ninu oṣu Kẹjọ sinu oṣu Kẹsan an."
Muhammad kọminu lori bi ojo arọrọda ati omiyale naa yoo ṣe ṣakoba fun omi ti awọn araalu n mu.
Lọjọ iṣẹgun ni ojo nla kan rọ niluu Eko fun nnkan bii wakati mejila, eyii to mu ki omi gba ọpọ ile ati oju titi, to si mu ko ṣoro fun ọpọ eeyan lati lọ ibi iṣẹ oojọ wọn.
Lawọn apa ibikan nipinlẹ Eko, lati ọjọ Aiku ni ojo naa ti bẹrẹ.
Ojo ọhun pọ to bẹẹ ti awọn ti wọn ti jade ko ri aye pada sile, bẹẹ lawọn mii kori bo inu ojo ọhun lati pada sile wọn.
Lara awọn ibi ti ojo naa ti milẹ titi julọ ni oju ọna marosẹ Oshodi, oju ọna marosẹ Abeokuta lati ibudokọ Oshodi, oju ọna marosẹ Lekki-Epe ati agbebe rẹ, Victoria Island, Agege, Ikeja, Oworonsoki, Gbagada, Funsho Williams Avenue, agbegbe Iwaya ni Yaba atawọn agbegbe mii ti omi wa layika wọn.
Adari ajọ NiHSA naa ṣalaye pe ipinlẹ to wa leti omi ni ipinlẹ Eko, nitori naa, o rọrun fun omiyale lati tete kọlu u.
Ohun to le ṣokunfa iṣẹlẹ iṣẹlẹ ẹkun omi ni Eko
Ninu ọrọ rẹ, ohun mẹta ọtọtọ lo le fa iṣẹlẹ ẹkun omi ni Eko.
O ni " iṣẹlẹ ẹkun omi le ṣẹlẹ nitori ile ti wọn kọ ni fẹgbẹkẹgbẹ ara pọ ni Eko, awọn odo to pọ ni Eko le fa omiyale, bẹẹ ni okun to wa ni Eko le fa omiyale pẹlu.
"Ti awọn ile ti wọn kọ ti ara wọn ba fa iṣẹlẹ ẹkun omi ti awọn odo to wa nibẹ tun kun akunfaya, e wo bi omiyale naa yoo ṣe buru to."
Muhammad amẹnuba awọn gọta ti idọti ti di oju ọna rẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn nnkan to tun n fa omiyale nipinlẹ Eko.
Awọn ipinlẹ ti isẹlẹ ẹkun omi yoo ti waye ree - NIMET
Ẹwẹ, ajọ NIMET to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Naijiria naa ti sọ ṣaaju pe ipinlẹ mẹrindinlọgbọn kaakiri Najiria ni iṣẹlẹ omiyale yoo kan laarin ọjọ kinni si ọjọ kẹwaa, oṣu Keje ọdun 2026 ti a wa yii.
Awọn ipinlẹ naa gẹgẹ bii atẹjade NIMET ni ipinlẹ Taraba, Sokoto, Borno, Zamfara, Kebbi, Katsina, Kaduna, Nasarawa, Plateau, Adamawa, Kwara, Kogi, Oyo, Ogun, Eko, Osun, Ekiti, Delta, Edo, Abia, Imo, Anambra, Enugu, Akwa Ibom, Cross River, Rivers, ati ipinlẹ Bayelsa.



























