IMF fẹ̀sùn kan ìjọba àpapọ̀ pé ó ná ₦N8.83trn tí kò ní àkọsílẹ̀, ìjọba ṣẹ́, Peter Obi àti Atiku ní kí Tinubu fi ipò sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/Atiku/Obo/Tinubu
Ijọba apapọ ti sọ pe irọ ni ọrọ ajọ ayanilowo lagbaye, IMF, sọ pe oun na owo ti iye rẹ to tiriliọnu mẹjọ naira ti ko si ninu akọsilẹ.
Ọrọ yii lo jẹyọ lẹyin ọjọ kan ti oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress, NDC, Peter Obi ke si Aarẹ Bola Tinubu ko kọwe fi ipo silẹ latari iwa ajẹbanu to n waye ninu ijọba rẹ.
Aṣoju ajọ IMF ni Naijiria, Christian Ebeke, sọ niluu Eko pe nnkan bii ida meji owo ti ijọba Naijiria na ni ko si akọsilẹ rẹ rara, bo tilẹ jẹ pe o yẹ ki akọsilẹ rẹ wa.
Amọ nigba to n fesi, minisita to n ri si eto ọrọ aje Naijiria, Taiwo Oyedele, sọ pe ijọba Naijiria kii na owo kankan lai ṣe akọsilẹ rẹ tabi na owo ti ko ṣe eto iṣuna fun ṣaaju.
O ni ọrọ ti IMF sọ "kii ṣe ododo, ọrọ naa si le ṣi awọn araalu lana nipa bi ijọba ṣe n na owo ilu."
Oyedele sọ pe gbogbo owo ti ijọba Tinubu n na lo ni akọsilẹ to si wa ni ibamu bo ṣe yẹ ki ijọba na owo ilu.
O fi kun pe ko bujumu ki awọn kan maa sọ pe ijọba na owo ti ko ni akọsilẹ tabi pe o na owo lai gba aṣẹ lọwọ ile igbimọ aṣofin.
Iwa ajẹbanu pọ ninu ijọba Tinubu, o gbọdọ fi ipo silẹ - Obi
Ẹwẹ, oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu NDC, Peter Obi, ti ke si Aarẹ Bola Tinubu ko kọwe fi ipo silẹ.
Nigba to n sọrọ loju opo X rẹ, Obi ni aṣiri iwa ajẹbanu to n tu labẹ Tinubu fi han pe asiko ti to fun lati fi ipo naa silẹ.
Gẹgẹ bii ọrọ Obi, aṣiri N8.83tr ti ijọba Tinubu na lọdun 2025 gẹgẹ bii ọrọ ajọ IMF lai ni akọsilẹ n fi han pe iwa ajẹbanu ti di tọrọkọbọ ninu ijọba rẹ.
Obi sọ pe ti ijọba ba na owo naa si ẹka eto ẹkọ tabi eto ilera, ayipada nla ni yoo de ba ẹka mejeji naa.
Gomina ipinlẹ Anambra nigba kan ri naa tun fẹsun kan ijọba Tinubu pe o kuna lati tẹlẹ awọn ilana to yẹ nipa bi ijọba ṣe gbọdọ na owo ilu.
O ni ijọba Tinubu ko mọ ohun to n ṣe, ko ni erongba rere fun awọn ọmọ Naijitia, o si ti kuna ninu awọn ileri to ṣe faraalu lasiko ipolongo ibo rẹ, nitori naa, asiko ti to fun lati fi ipo Aarẹ silẹ fun awọ to kaju ilu lati tukọ Naijiria.
Atiku Abubakar ni iwadii gbọdọ waye lori owo naa
Igbakeji Aarẹ Naijiria nigba kan ri, to tun jẹ oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Atiku Abubakar, ti sọ pe iwadii gbọdọ waye lori owo naa to jẹ ida meji eto iṣuna Naijiria.
Ọrọ Atiku fara pẹ ọrọ ti Obi sọ ṣaaju pe iwa ajẹbanu ni ki ijoba maa na owo ti ko ni akọsilẹ tabi gba ontẹ ile ogbimọ aṣofin.
Atiku lo sọrọ naa nigba to n fesi si ọrọ ajọ IMF.
Phrank Shaibu, to n gbẹnusọ fun Atiku sọ pe ọrọ naa ti kọja aṣiṣẹ bi ijọba ṣe na owo amọ o jẹ ọna lati mọọmọ kowo ilu si apo ara ẹni.
O ni "Owo ko le ṣadede poora ninu apo iṣuna ijọba, ẹnikan lo maa bu ọwọ lu owo ọhun fun nina.
"Eeyan lo fọwọ si. Eeyan kan lo buwọ lu u. Eeyan lo na. Eeyan kan lo jẹ anfani owo naa. Awọn ọmọ Naijiria si lẹtọọ lati mọ ẹni naa."
Atiku tun mẹnuba ileeṣẹ ijọba, Presidential Foreign Intervention Promotion Council, ti ẹnikan n dari rẹ ti ijọba si ya owo sọtọ fun ninu eto iṣuna ọdun 2026 bo tilẹ jẹ pe ijọba ni ileeṣẹ naa ko si ni akọsilẹ oun bẹẹ ni oun ko fun adari ileeṣẹ ọhun laṣẹ lati maa dari rẹ.




























