Obìnrin tí wọ́n ṣèèṣì san N100,000 sí àṣùwọ̀n rẹ̀ kọ̀ láti dáwó padà, àwọn èèyàn gbaná jẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àṣìṣe kò mọ ọgbọ́n tàbí ọjọ́ orí, kò sí ẹni tí kò lè ṣe àṣìṣe
Ọkùnrin kan Ani Gerald Chukwuebuka, tó jẹ́ olùgbé ìpínlẹ̀ Eko, tó sì jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ti ké gbàjarè sáwọn ọmọ Nàìjíríà láti gba òun lórí bí òun ṣe máa rí owó ẹgbẹ̀rún ọgọ́rùn-ún náírà tí òun ṣèèṣì san sí akoto arábìnrin kan gbà padà.
Chukwuebuka ké gbàjarè pé èèyàn kan tó fẹ́ owó náà fún òun, tí òun sì ṣèèṣì tẹ nọ́mbà Opay ẹlòmíràn sí orí fóònù tó sì lọ bọ́ sí akoto owó obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Opeyemi Faridat Awodoyin.
Ó ṣàlàyé pé ní ọjọ́rú ni ọ̀rẹ́ òun kan fẹ́ dá owó tí òun yá ẹni náà padà tó sì ní kí òun nọ́mbà báńkì òun sórí fóònù rẹ̀.
Ó ní ibi tí òun ti ń tẹ nọ́mbà náà ni òun ti ṣèèṣì nọ́mbà kan tó parí nọ́mbà tí òun fi ń gba owó ní Opay, tí òun sì tẹ nọ́mbà ti Awodoyin síbẹ̀.
"Èmi àti ọ̀rẹ́ mi jọ wà pọ̀ nígbà tó fẹ́ dá owó náà padà fún mi. Ó kàn fún mi ní fóònù rẹ̀ láti tẹ nọ́mbà mi sí kó fi san owó náà fún mi.
"Bí mo ṣe gba fóònù tí mo fi nọ́mbà mi síbẹ̀ mi ò wo orúkọ tó gbé wá, òun náà kò yẹ̀ ẹ́ wó tó fi san owó ọ̀hún."
Chukwuebuka ní ìgbà tó tó bíi wákàtí díẹ̀ tí òun kò rí owó ló mú òun yẹ áàpù òun wò tí òun kò sì rí owó níbẹ̀.
Ó ní ìgbà náà ni òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí rẹ̀ pé àṣìṣe wà nínú nọ́mbà tí òun fi sílẹ̀ tí owó náà sì ti bọ́ sí akoto owó ẹlòmíràn.
Ó sọ pé èyí mú kí òun kàn sí Awodoyin láti sọ àṣìṣe náà fún àti pé kó bá òun dá owó náà padà.
'Bí mo ṣe pe Awodoyin pé kó bá mi dá owó padà ló búọ́ọ̀kù mi ní WhatsApp'
"Bí mo ṣe pè é ló pariwo, ó kọ́kọ́ sọ pé òun kò rí owó náà àmọ́ nígbà tí mo tún pè é padà, ó sọ pé òun ti rí owó náà.
"Kò pẹ́ sígbà náà ló tún yí òun padà pé àwọn Opay ti yọ owó náà ní àkáǹtì òun nítorí òun jẹ wọ́n lówó."
Chukwuebuka tún ṣàlàyé pé nígbà tó ya ni òun tún lọ bá a sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì WhatsApp láti bẹ̀ ẹ́, tó sì gbà pé òun máa san owó náà díẹ̀díẹ̀ ni.
Ó sọ pé ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀ ni òun gbìyànjú láti bá Awodoyin sọ̀rọ̀ lórí WhatsApp pé kó má gbàgbé ohun tí àwọn jọ sọ àmọ́ ó ní ṣe ni Awodoyin búlọ́ọ̀kù òun lórí ìkànnì náà, tí òun kò si ri bá sọ̀rọ̀ láti ìgbà náà.
Gbogbo ìgbìyànjú rẹ̀ láti bá ọmọbinrin náà láti dá owó padà ló ti já sí pàbó báyìí.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wá ń fa awuyewuye lórí ayélujára, táwọn èèyàn sì ti ń bu ẹnu àtẹ́ lu Awodoyin fún bí ó ṣe kọ̀ láti dá owó tí kìí ṣe tirẹ̀ tí èèyàn ṣèèṣì san sí akoto owó rẹ̀.
Níṣe ni àwọn èèyàn ń kọ ọ̀rọ̀ sójú òpó Facebook pé ìwà olè ló wù, pé ó nílò láti dá owó Chukwuebuka padà.
Níṣe ni àwọn míì ti ẹ̀ ń bù ú ní èpè, pé kò mọ ohun tí ẹni tó ni owó náà ń kojú, tó sì fẹ́ fi owó náà ṣe.
Ọ̀nà wo ni èèyàn fi lè rí owó tí èèyàn bá san sí nọ́mbà Opay tí kìí ṣe ti èèyàn padà?
Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara, àṣìṣe kò lè ṣaláìwáyé, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lo akoto Opay báyìí yálà fún okoòwò tàbí àdáni.
Ó sì ṣeéṣe kí irú àṣìṣe tó wáyé sí Chukwuebuka yìí ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni. Tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí bá wáyé, àwọn ìgbésẹ̀ tí èèyàn le gbé nìyí:
Ó máa kọ́kọ́ fi ẹjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sùn lórí áàpù Opay nípa títẹ rìsíìtì tí èèyàn fi san owó náà.
Lẹ́yìn náà ló máa pe Opay lórí nọ́mbà 0700 888 8328 tàbí 0201 8888328 tàbí kí o kàn sí Opay lórí WhatsApp lórí +234 916 599 8936.
Lẹ́yìn náà ni wà á kàn sí ẹni tó bá ṣèèṣì san owó sí akoto rẹ̀ láti bèèrè pé kó dá owó náà padà.
Ó máa wá dúró kí Opay dá sí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n sì máa kàn sí ẹni tí ó ṣèèsì san owó sí, wọ́n máa gbégi dínà akoto rẹ̀, tí wọ́n sì máa sọ fun pé kó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé èèyàn ṣèèṣì san owó náà ni àti pé kí àwọn dá owó náà padà.
Tí ẹni náà bá wá kọ́ láti dá owó padà, ó máa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tàbí ilé ẹjọ́ láti lọ gba àṣẹ pé kí Opay bá ọ fi ìgbésẹ̀ òfin gba owó náà padà.
Yàtọ̀ sí Opay, èèyàn le gba owó tó bá ṣèèṣì san sí akoto owó míì padà àmọ́ ó máa nílò láti kọ́kọ́ gba àṣẹ láti àgọ́ ọlọ́pàá tàbí ilé ẹjọ́ èyí tó máa mú lọ sí ilé ìfowópamọ́ tí o tis an owó pé kí wọ́n bá ẹ gba owó rẹ padà láti akoto tó ṣèèsì san owó náà sí.

























