"Ẹ̀yin ọ̀dọ́ tí ẹ̀ ń kún pé bí Toun Soetan ṣe ń kọrin ń di yín lọ́wọ́ láti dárà nínú ìjọ, ó ti lọ, ẹ wá dárà yín ká rí i"

Oloogbe Toun Soetan, posi ti won fi sin in ati diẹ lara awon to wa nibi eto isinku naa.

Oríṣun àwòrán, Toun Soetan/Instagram/BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajugbaja olorin ẹmi, Arabinrin Toun Soetan, to jade laye lọjọ kẹtala, oṣu Kẹta ọdun 2026 yii ni wọn ti gbe wọ kaa ilẹ sun.

‎Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹrin yii ni isinku naa waye ni ibudo isinku ti ijọ Oritamefa to wa ni agbegbe Arulogun, niluu Ibadan.

Ṣaaju ni isin orin onigbagbọ ti waye ninu ile ìjọsin Onitebomi Oritamefa, ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ.

Ọpọlọpọ olorin ẹmi bii Bola Aarẹ, Funmi Aragbaye, Philip Adika atawọn mi-in si lo peju pesẹ sibẹ.

Lasiko ti Alufaa naa n waasu nibi eto isinku to waye ni ṣọọṣi Onitẹbọmi Oritamẹfa, Ibadan

Alufa to waasu nibi isin idagbere Toun Soetan sọko ọrọ sawọn ọdọ

‎Ninu iwaasu Alufaa to dari eto naa, Ọjọgbọn Oyekola Bamidele, o ni:

"Gbogbo eniyan ni yoo ka ọjọ iku, ohun gbogbo ni yoo wa sopin, ẹnikẹni ti ko ba gba Ọlọrun gbọ ni yoo ṣegbe."

‎Alufaa Oyekola ṣapejuwe Oloogbe Toun Soetan bii ẹni to ni iwa irẹlẹ. O fi Toun Tabitha inu Bibeli.

O ni bo tilẹ jẹ pe iku Oloogbe Toun Soetan ba ọpọlọpọ eeyan lojiji, sugbọn awọn isẹ rere rẹ ko ni i ku lẹyin rẹ.

‎Nigba to n ṣapejuwe akọrin ẹmi naa bii ẹni ti orin rẹ yatọ, Alufaa Oyekola ni:

" Ẹlomiran yoo ni bi Toun Soetan ṣe n kọrin n di oun lọwọ lati kọrin ninu ìjọ, nisinyi ti Toun ti papoda, ìwọ naa waa kọrin."

‎"Ọpọ ẹyin ọdọ ni ẹ saba maa n kùn nile ijọsin, pe ko si aaye fun yin lati dárà ninu ìjọ, Toun Soetan ti ṣe tiẹ tan, ẹyin naa ẹ wa dara to wu yin ninu ìjọ."‎

Ajinyinrere Funmi Aragbaye lapa osi nibi eto isinku naa.

Wọn maa n pe emi ati Toun Soetan ni ibeji - Funmi Aragbaye

Gbajumọ olorin ẹmi ti oun naa ti n kọrin tipẹ, Ajihinrere Funmi Aragbaye, wa nibi eto isinku naa.

O ṣalaye fun BBC News Yoruba pe:

‎"Lati ọdun 1983 ni emi ati Toun Soetan ti mọra. Ko too di pe mo bẹrẹ si i kọrin lati mọra.

" O jẹ obinrin to maa ń ṣise takuntakun, oninu mimọ obinrin, o ni ife gan-an.

‎"Awọn eeyan maa n sọ pe emi ati Toun jọ ara wa, wọn maa n sọ pe ibeji ni wa. To ba mura, ẹ maa ri Funmi Aragbaye. Ninu ohun gbogbo la fi jọra, ṣe ẹ mọ pe a ki i tọ́jú bi awọn ọdọ isinyi."

‎Nigba to n gba awọn akọrin ẹmi asiko yii nimọran, Ajinhinrere Aragbaye sọ pe awon olorin ẹmi isinyi gbọdọ gbiyanju lati maa wo awokose awọn to wa niwaju wọn.

O ni iyatọ wa ninu orin ẹmi ati orin aye, ki wọn jẹ ki orin wọn maa je orin iwaasu, ki i ṣe ki wọn kan maa lanu kọrin ṣaa.

Ta a ni Oloogbe Toun Soetan?

Olorin ẹmi ni Oloogbe Toun Soetan nigba aye rẹ, ẹni ọdun mẹtalelaadọrin (73) ni nigba ti ọlọjọ de.

Lara awọn orin ti Oloogbe naa kọ to lamilaaka ni: 'Darling Jesus, Train Up Your Child, Iye Ree, Gbe Jesu Ga' ati bẹẹ bẹẹ lọ.

‎Irinajo ajo ẹmi Toun Soetan gba ọna miran yọ lẹyin to lọ sibi isọji kan nile ijọsin Oritamefa Baptist Church, lọdun 1974, irinajo naa lo si bẹrẹ iṣẹ orin ẹmi rẹ.

‎Ijọ Onitebomi Oritamefa to ti gba Ọlọrun gbo lọdun 1974 naa ni won ti ṣe adura ikẹyin fun un lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin ọdun 2026.