Ìgbà ìkẹyìn tí máà díje fún ipò ààrẹ rèé, tí ń kò bá borí ìbò abẹ́nú, máa ṣe àtìlẹyìn fún ẹni tí ADC bá fà kalẹ̀ láti díje ipò ààrẹ - Atiku

Atiku wọ agbádá aláwọ̀ ewé, ó dé fìla tí wọ́n kọ ADC sí

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, Alhaji Atiku Abubakar ní òun ti ṣetán láti ṣe àtìlẹyìn fún ẹnikẹ́ni tí ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Party, ADC bá fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùdíje sípò ààrẹ níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.

Atiku sọ èyí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ètò tó kópa níbẹ̀ lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2026 sọ pé ohun tí àwọn ń gbèrò láti ṣe nínú ADC ni láti fẹnukò lórí olùdíje kan fún ipò ààrẹ ni.

Ó ní tí èyí kò bá kẹ́sẹ járí ni àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe ètò ìdìbò abẹ́nú láti yan olùdíje sípò ààrẹ náà.

"Ẹnikẹ́ni tí ẹgbẹ́ bá fà kalẹ̀ ni máa ṣe àtìlẹyìn fún, kódà, kó jẹ́ Peter Obi"

Ó ní ẹnikẹ́ni tí ẹgbẹ́ bá fà kalẹ̀ ni òun máa ṣe àtìlẹyìn fún kódà kó jẹ́ Peter Obi.

Ó fi kun pé òun kò ní yẹ̀bàá fún ẹni tí ẹgbẹ́ bá fà kalẹ̀, ó ní òun máa ri dájú pé ẹni náà rí àtìlẹyìn tó péye láti ri pé ó gba ipò ààrẹ Nàìjíríà níbi ètò ìdìbò náà.

Níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà ló tún ti sọ pé tí òun kò bá rí ipo ààrẹ níbi ètò ìdìbò ọdún 2027, òun kò ní dupò kankan mọ́.

Atiku, ẹni tó ti ń díje sípò ààrẹ Nàìjíríà fún ọdún pípẹ́, sọ pé àsìkò yìí ni òun ní láti fi jẹ́ káwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe àtìlẹyìn fún òun láti gbapò ààrẹ Nàìjíríà nítorí òun kò ní dupò mọ́ lẹ́yìn èyí.

"Kò sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ àti àgbà"

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn kan ṣe ń sọ pé ó ti dàgbà àti pé àwùjọ àwọn tí kò rí Nàìjíríà tò ni òun náà wà, ó ní òun wà láàárín àwọn àgbà àti ọ̀dọ́ Nàìjíríà ni.

Ó wòye pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ipa àwọn ọ̀dọ́ tó ti wà nípò kan tàbí òmíràn láti ìgbà táwọn ọ̀dọ́ ti ń sọ pé àwọn ń wá ipò agbára ní Nàìjíríà.

"A ti rí onírúurú ipele ipò olórí láàárín àwọn èèyàn ní Nàìjíríàt ó fi mọ́ àwọn àgbà àti àwọn ọ̀dọ́. Mo gbàgbọ́ pé ohun tí a rò pé a máa bá lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ kọ́ ni à ń rí."

Atiku tẹmpẹlẹmọ ipa ìrírí nínú ètò òṣèlú èyí tó ní òun ní láti ìgbà tó ti ṣe igbákejì Olusegun Obasanjo láàárín ọdún 1999 sí 2007.

"Ohun tí mo kọ́ lọ́dọ̀ Olusegun Obasanjo nígbà tó wà ní ààrẹ, mi ò ní lè kọ láti ìta tí mi ò bá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ̀."

Ó ní àwọn ọ̀dọ́ nílò láti ní ẹni tó máa jẹ́ atọ́nà fún wọn nídìí òṣèlú láti ṣe àṣeyọrí.

'Mo máa rí pé ṣíṣe àtúnṣe sí ìwé òfin Nàìjíríà wáyé lórí gbígbé ipò ààrẹ lọ sí ẹkùn kọ̀ọ̀kan tí mo má bá di ààrẹ'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àgbà olóṣèlú náà tún sọ pé tí òun bá fi lè di ààrẹ Nàìjíríà, òun máa ri dájú pé àtúnṣe wáyé sí ìwé òfin Nàìjíríà láti fi ààyè gba gbígbé ipò ààrẹ yíká gbogbo ẹkùn mẹ́fà tó wà ní Nàìjíríà.

Ó ní ṣíṣe èyí máa fi ààyè gba kí ètò ìṣèjọba yíká gbogbo ẹkùn àti pé ó máa jẹ́ kí pínpín agbára lọ bó ṣe yẹ.

"Tí mo bá di ààrẹ Nàìjíríà, kódà tó bá jẹ́ pé àtúnṣe kan ṣoṣo tí mà á rí ṣe nìyẹn, mo máa gbìyànjú rẹ̀."

Ó ní ó jẹ́ ohun tó máa ń dun òun pé òun lòdì sí ìlànà pínpín ipò ààrẹ lẹ́kùn-ò-jẹkùn nígbà tí olóògbé Alex Ekwueme pè fún-un nígbà tí wọ́n ń ṣe àgbéyẹ̀wò ìwé òfin Nàìjíríà tí wọ́n ṣe gbẹ̀yìn.

"Èmi àti Alex Ekwueme ní aríyànjiyàn nígbà tí ó bèèrè fún pínpín ipò ààrẹ sí ẹkùn kọ̀ọ̀kan nígbà náà tí mo sì takò ó.

"Àtúnṣe náà kò ríbi wáyé nítorí àwọn aṣojú láti ẹkùn wa pọ̀ jù wọ́n lọ àmọ́ ó máa ń dùn mí pé mo ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà."

Ó sọ pé nígbà tí òun lọ síbi ètò ìsìnkú rẹ̀, òun gbà pé òun ṣe àṣìṣe, pé ó yẹ kí òun ṣe àtìlẹyìn fún èrò náà nítorí òun nìkan ló le mú pínpín ètò ìṣèjọba tòótọ́ wáyé ní Nàìjíríà