Ọ̀daràn ni ẹnikẹ́ni tó bá ń gbé nínú igbó, ohun tí a máa ṣe fún wọn rèé... - Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/ Screenshot
Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti rọ awọn Ọba alaye nilẹ Yoruba paapaa awọn ti Oke Ogun ni ipinlẹ Oyo lati ṣe atilẹyin fun awọn ọdọ lori igbogunti awọn ọdaran to n da ilẹ Yoruba laamu.
Sunday Igboho parọwa yii nigba to ṣe abẹwo si aafin Okere ti ilu Saki lasiko to lọ beere fun atilẹyin awọn Ọba naa lati koju iwa ijinigbe to ti di tọrọ fọnka sile ni awọn igbo o yi ilẹ Yoruba ka.
O sọ pe ọpọ awọn Ọba ati agbaagba nilẹ Yoruba ni wọn ti ṣe ọpọ iṣẹ lati fopin si iwa ijinigbe tabi igbeṣumọmi nilẹ Yoruba amọ ti oun ti naa fẹ bẹrẹ lati ibi ti wọn ba iṣẹ de.
O ni oun ti bẹrẹ iṣẹ lati ri daju pe gbogbo awọn igbo to yi ilẹ Yoruba ka ni ko si awọn ọdaran nibẹ mọ ti oun si nilo atilẹyin gbogbo awọn to ba yẹ lati kẹsẹ jari.
Sunday Igboho tẹsiwaju pe "Ninu igbo wa, a ko fẹ ọdaran kankan nibẹ mọ, a o nilo wọn mọ, koda bi a ba ba Yoruba ninu igbo, ki lo o n ṣe nibẹ.
"Ẹ maa bọ nigboro lati maa gbe, ki lẹ n ṣe ninu igbo. Ẹnikẹni ti a ba ba ninu igbo, oun toju rẹ ba ri ko faramọ ni."
Igboho ṣeranti pe nigba ti awọn ọdaran n fa wahala ni Ibarapa ti awọn si ṣekilọ fun wọn amọ ti wọn ko gbọ, awọn ri daju pe awọn rẹyin wọn nibẹ nigbẹyin.
O woye pe ti awọn ba ti ri atilẹyin awọn Ọba, o maa rọrun lati le le awọn afurasi ọdaran to wa ninu igbo eyi to gbagbọ pe wọn jẹ iran Fulani.
"A o ni ki eeyan ma gbe ilu wa, iwọ to ba fẹ ba wa gbe, maa bọ nigboro"
O ni o yẹ lati tete gbe igbesẹ lati ri pe awọn ọdaran naa kuro kuro ni ayika ilẹ Yoruba patapata ki wọn ma gba ile ati ilẹ mọ gbogbo eeyan lọwọ nitori ko si ibi ti wọn maa lọ.
O fi kun pe awọn ko ni ki ajoji ma wa lati gbe ilẹ Yoruba ṣugbọn gbogbo awọn to ba fe maa gbe nilẹ Yoruba nilo lati bọ si igboro nibi ti oju ti maa ka gbogbo eeyan.
"A o ni ki eeyan ma gbe ilu wa, iwọ to ba fẹ ba wa gbe, maa bọ nigboro ki a mọ ile ati ọna rẹ. Ọdaran ni ẹnikẹni ti a ba ti ba ninu igbo."
Bakan naa lo ni oun gbagbọ pe awọn kan lo mọọmọ maa gbe inu okunkun tafa si imọlẹ lori ipenija aabo to n ba Naijiria finra yii.
O ni ọgbọn oṣelu ni gbogbo iṣẹlẹ to n waye yii lati fi tabuku ijọba to wa lode paapaa bi eto idibo gbogbogbo ọdun 2027 ṣe ti n sunmọ etile.
Igboho ni irufẹ iṣẹlẹ bayii ti waye lasiko iṣejọba Aarẹ Jonathan ti awọn agbebọn n da ijọba rẹ lati le jẹ ko dabi pe ko kaju oṣuwọn lati dari orilẹ ede.
O ni ọgbọn naa ni wọn n da bayii lati ma jẹ ẹ ki Tinubu ribi wọle saa keji nibi eto idibo gbogbogbo to maa waye ni 2027.
"Pipa ni a maa pa ọmọ Yoruba to ba n ṣe atilẹyin fun ajinigbe"
Ṣaaju ni Sunday Igboho ti sọ ninu fidio kan to gba ori ayelujara pe ọmọ Yoruba kankan ti wọn ba ṣawari rẹ pe o n ṣe atilẹyin fun awọn to n ji eeyan gbe ni oun maa pa.
Igboho ninu fidio kan to wa lori ayelujara sọ pe oun ti n gbọ iroyin pe awọn ọmọ Yoruba kan n ṣe atilẹyin fun awọn ajinigbe lati maa ṣọṣẹ.
O ni oun ko ni koola pẹlu ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ to n ṣe eyi nitori oun maa gbẹmi lọrun ẹni bẹẹ ni.
"Awọn kan wa ti wọn jẹ ọmọ Yoruba ti wọn n ṣe atilẹyin fun wọn, ẹni ti mo ba gbamu to n ṣatilẹyin fun Fulani lati maa ji eeyan gbe, ma a pa ni.
Idajọ rẹ ni pe ka pa."
Ṣé òótọ́ ni pé ajínigbé tu aláboyún àtàwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn tí Sunday Igboho fún wọn ní gbèdéke wákàtí méjì?

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Iroyin to n lọ ni igboro ti sọ pe idile kan to wa ni ahamọ awọn ajinigbe ni Ilu Igboho, ipinlẹ Oyo ti gba itusilẹ leyin ti Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, fun awọn ajinigbe naa ni gbedeke wakati meji lati tu awọn ẹbi naa silẹ.
Eyi mu ki awọn eeyan ilu naa bẹrẹ si ni fo fayọ, ti inu wọn si n n dun si itusilẹ awọn araalu ọhun, ti wọn si fi ijo pade awọn to gba itusilẹ naa.
Fidio kan to wa lori ayelujara ṣafihan bawọn eeyan ṣe n fi ijo pade alaboyun kan, aburo rẹ atawọn ọmọ rẹ ti wọn gba itusilẹ kuro ni ahamọ awọn ajinigbe to n da agbegbe naa laamu.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti Sunday Igboho ṣekilọ fawọn olori awọn Fulani to n gbe ninu ilu Igboho lori bi ijinigbe ṣe n peleke si ni agbegbe naa.
Fidio kan to wa lori ayelujara ṣaaju iroyin pe idile naa ti gba itusilẹ ṣafihan ibi ti Sunday igboho ti n ba awọn olori awọn Fulani sọrọ ni aafin Ọba ilu Igboho to si n fi itara han lori bi eto aabo ṣe ti mẹhẹ ni ilu naa.
Igboho fẹsun kan pe awọn Fulani ni awọn afurasi to n ji awọn eeyan gbe ni agbegbe naa ati pe oun ko ni kawọ rọ ni ilu baba oun, ki oun maa wo awọn ajinigbe naa lati maa da nnkan ru.
O fẹsun kan pe awọn ajinigbe to gbe alaboyun naa atawọn ọmọ rẹ beere fun owo itusilẹ lati tu awọn eeyan naa silẹ amọ niṣe ni wọn pa ẹni to gbe owo lọ fun wọn lai tu awọn eeyan wọn silẹ.
Ọọdunrun miliọnu naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ beere fun lati gba itusilẹ awọn eeyan naa ki wọn to dinku si aadọjọ miliọnu naira.
Igboho ni awọn ajinigbe ko ni maa ṣọṣẹ ni ilu abinibi oun ki oun maa woran ati pe eyi ti wọn ṣe yii ni wọn gbọdọ fi fopin si iwa bẹẹ.
O ni oun ko ni gba ki wọn maa ṣe awọn nnkan ti oun n ja fun opin rẹ ni ilu mii lati maa waye ni ilu baba oun ati pe awọn ajinigbe naa maa kan idin ninu iyọ ti wọn ko bat u awọn eeyan naa silẹ laaarin wakati meji.
O fi kun pe nitori ọba ilu awọn ko fẹ ki ọrọ naa mu ija dani ni oun fi n ba awọn eeyan naa sọrọ ni tubi n nudi, ti oun n fi suuru ṣe ohun gbogbo.
Nigbẹyin, awọn adari Fulani ni agbegbe naa gba itusilẹ alaboyun naa atawọn ọmọ rẹ ki gbedeke wakati meji ti Sunday Igboho fun wọn to pe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Instagram
Irọ ni o, awọn eeyan naa ṣi wa lakata ajinigbe - Ijọba ibilẹ Oorelope
Ẹwẹ, awọn alaṣẹ ijọba ibilẹ Oorelope, nibi ti ilu Igboho ti wọn ti ji awọn eeyan naa gbe wa ti sọ pe irọ ni iroyin to n mi igboro titi lẹyin ti Sunday Igboho ba awọn Fulani kan sọrọ nibẹ lori ijinigbe ọhun.
Ninu atẹjade kan ti alaga kansu naa, Jacob Oluwale Ogundiran, fi lede lọjọ Aiku, o ni irọ ni iroyin itusilẹ awọn eeyan naa, ko si si ootọ kankan ninu rẹ.
Atẹjade ọhun sọ pe "Awọn eeyan naa ti wọn wa lakata ajinigbe ko tii gba itusilẹ. A rọ awọn araalu ki wọn maṣẹ naani iroyin eyikeyi to ba sọ pe wọn ti gba itusilẹ ayafi ti irufẹ iroyin bẹẹ ba ti akata awọn alaṣẹ jade."
Alaga kansu ọhun fi kun pe awọn ọlọpaa ni ibaṣepọ pẹlu awọn agbofinro mii n ṣiṣẹ takuntakun lati doola awọn eeyan naa.
O pari ọrọ rẹ pẹlu arọwa si awọn olugbe ilu ọhun ati ijọba ibilẹ naa ki wọn ṣe suuru ki wọn ma si fi ofin si ọwọ ara wọn.
Lẹyin naa lo ṣeleri pe awọn n ṣiṣẹ takuntakun lati ri daju pe awọn eeyan ọhun ti wọn wa lakata ajinigbe gba ominira wọn laipẹ.




























