Wo kókó ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Abiodun Oyebanji, olùdíje gómìnà fẹ́gbẹ́ APC tó wọlé sáà kejì l'Ekiti

Oríṣun àwòrán, Gov. Biodun Oyebanji/Facebook
Ninu esi idibo gomina to waye nipinlẹ Ekiti lọjọ Satide, ogunjọ osu Kẹfa ọdun 2026, Abiodun Abayomi Oyebanji tẹgbẹ oselu APC lo moke ninu eto idibo naa.
Apapọ ibo to ni jẹ 319, 224, òun sì lo ní ibo to pọ julọ ni gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ merindinlogun to wa ni ìpínlẹ̀ Ekiti.
Àpapọ̀ ibo tí Oyebamiji ni yìí sí lọ jẹ idà marundinlọgọrun nínú ọgọrun ibo tí wọn di lásìkò eto ìdìbò náà.
Èyí sì lọ fi ṣẹ eegun ẹyin awọn oludije ẹgbẹ oselu yoku janlẹ.
Wo koko ohun ti o ko mọ nipa Abiodun Oyebanji:
Ọjọ Kọkanlelogun, osu Kejila ọdun 1967 ni wọn bi Abiodun Oyebaanji.
Ọmọ bibi ilu Ikogosi, nipinlẹ Ekiti ni Oyebanji, o si lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ tijọ Onitẹbọmi to wa niluu naa.
Awo Community High school lo lọ ko too wa bọ si ile ẹkọ Girama C.A.C Grammar School, nilu Efon-Alaaye lọdun1979.
Bakan naa lo lọ sile ẹkọ Girama fun imọ sayẹnsi to jẹ tijọba ipinlẹ Ondo ijọun, ati ile ẹkọ District Commercial Secondary School nilu Aramoko-Ekiti, laarin ọdun 1983 si 1985.
Lẹyin ile ẹkọ Girama lo tẹsiwaju lọ sile ẹkọ fasiti ijọba ipinlẹ Ondo, 'Ondo State University' to di Ekiti State University, Ado-Ekiti bayii lọdun1989.
Abiodun Oyebanji to gbegba oroke ninu ibo gomina ipinlẹ Ekiti yii fun igba keji yii ko sẹsẹ bẹrẹ oselu, o ti di ipo akọwe ijọba ipinlẹ naa mu saaju.
Ẹkọ nipa eto oselu ni Abiodun lọ kọ nibẹ ninu eyi to ti gba oye imọ ijinlẹ akọkọ.
Biodun Oyebanji tun gba oye kun oye ninu imọ ẹkọ nipa oselu yii lati fasiti Ibadan.
Gomina to wọle fun saa keji yii sisẹ bii alakooso nile ifowopamọ Omega to ti kogba wọle bayii, amọ to parada di Heritage Bank titi di ọdun 1999.
Lagbo oselu, Biodun Abayomi Oyebanji sisẹ bii amugbalẹgbẹẹ fun ọrọ ile asofin fun gomina ipinlẹ Ekiti laarin ọdun 1999 si 2000.

Oríṣun àwòrán, @biodunoyebanji
Oun naa si tun ni amugbalẹgbẹ si gomina lori ọrọ asofin naa laarin ọdun 2000 si 2001.
Lẹyin naa ni Oyebanji wa di olori osisẹ ni ọọfisi gomina laarin ọdun 2001 si 2003.
Oyebanji tun jẹ Kọmisanna fọrọ ijọba kan si ekeji nipinlẹ Ekiti, ko to wa di akọwe ijọba ipinlẹ naa fun gomina Kayode Fayemi.
Ipo yii si lo di mu titi ko to wa pinnu lati dije fun ipo gomina ni saa akọkọ to si jawe olubori ninu rẹ .
Biodun Abayomi Oyebanji fẹ iyawo, Ọjọgbọn Arabinrin Oyebanji to n sisẹ́ lọgba Fasiti Ibadan, to tun jẹ ọmọ ọbabinrin niluu Ado Ekiti ni iyawo rẹ.



























