Ilé ẹjọ́ gbẹ́sẹ̀ lé ilẹ̀, ilé ìtura, àtàwọn dúkìá míì tí wọ́n ní pásítọ̀ fi ọ̀nà èrú kó jọ

Pásítọ̀ Theophilus Ebonyi gbé àkọ́lé EFCC lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó fi ìlú Lafia, ìpínlẹ̀ Nasarawa ṣe ibùjókòó ti dájọ́ pé kí ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀ lé ilẹ̀ kan tó wà ní ẹnubodè ìpínlẹ̀ Nasarawa sí Abuja èyí tí wọ́n gbà lọ́wọ́ pásítọ̀ kan.

Adajọ́ M. O. Olajuwon tó gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ sọ pé àjọ tó ń gbógúnti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, ìyẹn Economic and Financial Crime Commission, EFCC ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀nà èrú ni pásítọ̀ Theophilus Ebonyi tó jẹ́ pásítọ̀ àgbà ìjọn On The Rock Ministry International fi kó ọrọ̀ náà jọ.

Àtẹ̀jáde tí àjọ EFCC fi lédé lójú òpó X wọn sọ pé ní ọjọ́rú ni adájọ́ Olajuwon gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ tó sì ní kí wan gba gbogbo dúkìá tí pásítọ̀ náà fi ọ̀nà èrú kó jọ.

Lára àwọn dúkìá tó jẹ́ ti pásítọ̀ Theophilus Ebonyi tí ilé ẹjọ́ ní kí ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀lé ni ilé ìtura tkan tó ní yàrá mẹ́tàlélógún àti gbọ̀ngán ayẹyẹ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ De Thinkers Home and Apartment tó wà ní agbègbè New Layout, Abattoir Road First Gate, Nyanya Gwandara, ìpínlẹ̀ Nasarawa.

Àwọn míì ni iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe omi inú ọ̀rá kan tó wà ní ojúlé ogún, òpópónà Philip Doda, Koroduma, ìjọba ìbílẹ̀ Karu, ìpínlẹ̀ Nasarawa àti ilé méjì tó jẹ́ ọ́fíìsì tó wà ní òpópónà Philip Doda kan náà.

Ilé ẹjọ́ tún ní kí ìjọba tún gbẹ́sẹ̀lé ilé ẹ̀kọ́ Theo International Academy Primary School tó wà ní Second Gate, òpópónà Balogun ní Nyanya Gwandara.

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ tún ní pásítọ̀ Theophilus yóò tún pàdánù owó N1,005,489.27 tí wọ́n bá nínú akoto owó ilé ìfowópamọ́ First Bank sọ́wọ́ ìjọba.

Adájọ́ Olajuwon ní àjọ EFCC ṣe ohun gbogbo tó yẹ lábẹ́ abala kẹtàdínlógún ìwé òfin Advanced Fee Fraud and Other Fraud Related Offences Act èyí tó ṣokùnfà bí wọ́n ṣe gbẹ́sẹ̀lé gbogbo àwọn náà.

Àjọ EFCC ní ìwádìí àwọn fi hàn pé akoto owó kejì pásíts ìjọ náà Theobarth Global Foundation ni wọ́n lò láti fi máa lu àwọn èèyàn ní jìbìtì, tí wọ́n sì máa ń gba owó lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n lù ní jìbìtì.

Lẹ́yìn gbogbo lrí tí EFCC gbé sí iwájú adájọ́, adájọ́ gbé ìdája rẹ̀ kalẹ̀, tó sì sọ pé pásítọ̀ Ebonyi kò mú ẹ̀rí kankan wá sílé ẹjọ́ láti tako EFCC kí wọ́n má fi gbẹ́sẹ̀lé àwọn dúkìá rẹ̀.

Báwo ni pásítọ̀ Ebonyi ṣe lu àwọn èèyàn ní jìbìtì?

Ní ọsún 2023 ni àjọ EFCC fi òfin gbé pásítọ̀ Ebonyi fẹ́sùn wí pé ó lu àwọn èèyàn – aládàni àti àwọn iléeṣẹ́ ní jìbìtì èyí tí àpapọ̀ rẹ̀ lé ní bílíọ̀nù kan náírà.

EFCC ní ó lu àwọn èèyàn ní jìbìtì nípasẹ̀ ṣíṣe ìpolongo pé àjọ ẹlẹ́yinjú àánú Ford Foundation ń pèsè owó ìrànwọ́ ogún bílíọ̀nù dọ́là fáwọn aláìní.

Wọ́n ní ó ṣe ìpolongo yìí nípasẹ̀ Theobarth Global Foundation.

EFCC fẹ̀sùn kàn pé pásítọ̀ náà máa ń sọ fáwọn tó lù ní jìbìtì pé kí wọ́n fi orúkọ sílẹ̀ nípa sísan owó ìgbaniwọ́lé àti ìforúkọsílẹ̀ kí wọ́n tó le jẹ àǹfàní rẹ̀.

Wọ́n ní èèyàn kọ̀ọ̀kan ló ní kí wọ́n san mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lanà ẹgbẹ̀rin náírà èyí tó mú kó owó tó lé ní bílíọ̀nù kan náírà jọ látara àwọn aládàni àtàwọn àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba.

Ìwádìí EFCC tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àjọ Ford Foundation kò ní ààtò kankan tàbí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ebonyi.

Àjọ náà ní àwọn kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú pásítọ̀ náà.