Davido ṣàlàyé ìdí tó fi wọ aṣọ tórúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso wà lára rẹ̀ níbí ìdíje World Cup

Oríṣun àwòrán, Davido/X
Gbajugbaja akọrin takasufe, David Adeleke ti ọpọ eeyan mọ si Davido, ti ṣalaye idi ti o fi wọ aṣọ ti orukọ awọn akẹkọọ mọkandinlogoji ti wọn ji gbe l'Ogbomoso wa lara rẹ nibi ayẹyẹ ibẹrẹ idije 2026 FIFA World Cup.
Davido sọ fun BBC News Africa wi pe ko ṣee ṣe ki oun kọ eti ikun si eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria papaa julọ ijinigbe awọn akẹkọọ mọkandinlogoji atawọn olukọ meje to ṣẹlẹ ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo.
Ilumọọka olorin naa sọ pe ọpọ eeyan le ma sọ nnkankan lori eto aabo to mẹhẹ lati le ma jẹ ki orukọ orilẹede Naijiria bajẹ.
Amọ, Davido sọ pe ko si bi ẹnikẹni ṣe le fẹ tun orukọ Naijiria ṣe nigba ti awọn akẹkọọ wa ni igbekun awọn janduku ajinigbe.
Omo baba olowo sọ pe loootọ lo jẹ nnkan iyi foun pe oun ṣere gẹgẹ bii akọrin nibi ayẹyẹ ibẹrẹ idije World Cup, ṣugbọn o ni oun gbagbọ pe o ṣe pataki foun lati jẹ ki gbogbo aye mọ nnkan to n ṣẹlẹ nipa eto aabo ni Naijiria papaa julọ nipa awọn eeyan to wa ni akata awọn ajinigbe.
OBO ni orin kikọ jẹ ọkan lara ọna toun fi le sọ nipa awọn nnkan to n ṣẹlẹ lorilẹede Naijiria.
''A ni agbara lati jẹ ki gbogbo agbaye mọ nnkan ti o n ṣẹlẹ ni orilẹede wa''
Davido ni ''a ni agbara lati jẹ ki gbogbo agbaye mọ nnkan ti o n ṣẹlẹ ni orilẹede wa.
Agbara mi wa ninu orin ti mo n kọ.
Awọn akẹkọọ atawọn olukọ wọn ti di awati lati ọjọ yii wa, idi gan an niyi ti mo fi pinnu lati jẹ ki gbogbo agbaye mọ nipa iṣẹlẹ naa.''
Ti ẹ o ba gbagbe, Davido wọ aṣọ ti orukọ gbogbo awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe ni Esinele ati Yawota l'Ogbomoso wa lara rẹ pẹlu akọle ''Ẹ da wọn pada wa sile'' lati jẹ ki awọn eeyan mọ nipa iṣẹlẹ naa.
Ọpọ eeyan lo bu ẹnu ẹtẹ lu Davido lori aṣọ to wọ naa wi pe o n tu aṣiri nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria sita fun gbogbo agbaye.
Amọ, awọn kan tun gboṣuba kare fun un wi pe o sọrọ lori nnkan to ṣẹlẹ sawọn ọmọde ni Naijiria, yatọ si awọn ti wọn o sọ nkankan lori nnkan to n ṣẹlẹ.




























