Ademola Adeleke pe ilé ìfowópamọ́ UBA àtàwọn alága kánsù APC lẹ́jọ́

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke
Ile ẹjọ magistrate to kalẹ si iluu Osogbo ni ipinlẹ ọsun ti bẹrẹ igbẹjọ ti gomina Ademola Adeleke pe tako ile ifowopamọ UBA atawọn alaga ijọba ibilẹ to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdún 2024 yii ni igbẹjọ naa waye ni ile ẹjọ giga to wa niluu Osogbo lagbegbe Oke-Fia.
Igbẹjọ naa lo bẹrẹ ni deede agogo mọkanla kọja iṣẹju mẹrinla.
Ohun ti igbẹjọ naa dale lori ni bi ile ifowopamọ UBA ṣe gba awọn alaga ijọba ibilẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC laaye lati tẹ ofin loju mọlẹ nipa fifi aye gba wọn lati jẹ onibara wọn lọna ti ko tọ.
Nigba ti agbẹjọro fun ijọba, Abiodun Badora, ka awọn oriṣiriṣi iwa ti ko ba ofin mu ti awọn alaga ijọba ibilẹ naa wu, o ni wọn jẹbi lọna to pọ labẹ ofin.
Agbẹjọro Abiodun, sọ pe, idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ti wa ni ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2025 ni ko sọ pe, ki awọn alaga ijọba ibilẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC pada si ọọfisi kowa wọn rara.
O fi kun pe saa wọn gẹgẹ bii alaga ti kọja lati inu oṣu Kẹwaa, ọdun 2025.
O fi kun pe wọn ko lẹtọọ lati lọ ṣi akanti kankan ti n ṣe ti ijọba ibilẹ si ile ifowopamọ UBA labẹ ofin. Agbẹjọro naa ni iwa bẹẹ lodi si ofin patapata.
Lẹyin gbogbo ọrọ ẹri ti agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ ọsun sọ, adajọ Samuel Adeyaba, ẹni ti wọn gbe ẹjọ naa si waju rẹ bere awọn agbẹjọro fun ile ifowopamọ UBA ati agbẹjọro fun awọn alaga ijọba ibilẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣugbọn awọn agbẹjọro wọn ko yọju si ile ẹjọ.
Eleyi lo mu ki Adajọ Samuel Adeyaba, bere lọwọ agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Ssun pe, njẹ ofin fi aaye gba a lati tẹsiwaju lai si agbẹjọro awọn ti wọn fi ẹsun kan.
Idahun rẹ ni pe, ofin fi aaye gba ti ko ba ti si idi pataki kankan ti wọn ko fi wa sile ẹjọ.
Nigba naa ni adajọ Samuel Adeyaba, ni ki agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Osun, Abiodun Badora tẹsiwaju ninu ẹri to wa lọwọ rẹ.
Ẹsun ti ijọba ipinlẹ Osun fi kan UBA
Ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan UBA ni bi wọn ṣe faaye gba awọn alaga ijọba ibilẹ ti ile ẹjọ ti le kuro ni ọfiisi lati ṣi akanti ijọba ibilẹ lọna ti ko ba ofin mu.
Adajo bere lọwọ agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Osun pe, ṣe wọn ni ẹlẹri kankan to le sọ ni idaniloju pe, otitọ ni pe awọn alaga ijọba ibilẹ naa ṣi akanti ijọba ibilẹ si UBA ẹka ti Osogbo ni ipinlẹ Osun.
Igba naa ni agbẹjọro fun ijọba pe Arakunrin Mudashiru Oyeyemi ẹni to jẹ akọwe fun ijọba ibilẹ to wa ni ọfiisi gomina ni Abere.
O tun ko awọn iwe ẹri kan ti awọn alaga ijọba ibilẹ naa fi ọwọ si lati fi ṣi akanti ni ile ifowopamọ UBA fun ẹlẹri naa.
Mudashiru Oyeyemi, to jẹ akọwe fun ijọba ibilẹ ni ọfiisi gomina ṣalaye pe, gbogbo awọn iwe ẹri naa lo de ọdọ oun ṣugbọn, ti ko t'ọna rara labẹ isakoso iṣejọba ijọba ibilẹ.
Lẹyin gbogbo ẹri ti agbẹjọro ijọba ipinlẹ ọsun Abiodun Badora fi han niwaju ile ẹjọ ni adajọ Samuel Adeyaba gba lọwọ agbẹjọro Abiodun Badora.
Adajọ Samuel Adeyaba, ka ẹsun ti wọn fi kan ile ifowopamọ UBA sita, ti ẹsun naa si jẹ mọkanlelọgbọn.
Ṣugbọn adajọ ni awọn ko ni le tẹsiwaju mọ lori ẹjọ ọhun ṣugbọn awọn yoo mu ọjọ miran fun ti tẹsiwaju rẹ.
Nigba naa ni agbẹjọro fun ijọba ati adajọ Samuel Adeyaba fori kori ti wọn si mu ọjọ kejidinlọgbọn oṣu, Kẹrin ọdún 2026 yii.
Awọn alaga ijọba ibilẹ ti ọrọ kan ṣe iwọde tako igbẹjọ naa
Gbogbo ọna ni awọn alaga ijọba ibilẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC gba lati ma jẹ ki ijoko igbẹjọ naa waye latari iwọde ti wọn ṣe ṣaaju niluu Osogbo.
Abiodun Idowu, to jẹ alaga fun awọn alaga ijọba ibilẹ ipinlẹ Osun (ALGON) ṣalaye idi ti iwọde alaafia fi waye.
O ni o yẹ ki gomina Ademola Adeleke ko ti jawọ lori ọrọ owo ijọba ibilẹ nitori ijọba apapọ lo kede ki gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ ni ipinlẹ kọọkan maa ṣe akoso agbegbe wọn lai si ọwọ gomina kankan nibẹ mọ.
Abiodun tun tẹsiwaju pe, gomina Ademola Adeleke ko bọwọ fun ofin ile ẹjọ kotẹmilọrun rara.
O ni Ko lẹtọ ki gomina Adeleke tun gbe awọn alaga ijọba ibilẹ ati ile ifowopamọ UBA lo si ile ẹjọ rara.
O ṣalaye pe ohun ti o yẹ ki gomina Adeleke ṣe ni pe, nigba ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ti dajọ tan, ti ẹjọ naa ko ba tẹ gomina lọrun o yẹ ko gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ni.

























