Bíi ẹni tó ṣòwò tí kò jèrè ni ikú Tope Osoba jẹ́ -Foluke Daramola

Gbajumọ oṣere tiata, Foluke Daramola, ti ṣe apejuwe iku akẹgbẹ rẹ, Oloogbe Temitope Osoba, bii ẹni to ṣowo ọja amọ ti ko duro jẹre ọja ọhun.
Foluke Daramola sọrọ yii nibi eto Aṣalẹ awọn oṣere ati titan abẹla ti awọn ẹgbẹ oṣere TAMPAN ṣe ni iranti Tope Osoba lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii.
Ninu ọgba tẹlifiṣan ipinlẹ Eko ti eto naa ti waye ni Foluke ti sọ pe:
"Inu mi bajẹ, emi ati Temitope ni ọpọlọpọ eto ti a la kalẹ, bi yoo ṣe ṣegbeyawo ti yoo di ọlọmọ laye.
"Bi mo ṣe mu un lọ si banki pe ko maa ṣe owo lati maa fi pawọda bo ṣe n ṣe fiimu.
" Mo ba a ṣeto bi yoo ṣe maa yawo ti yoo si maa rowo, eto to ga la nilẹ.
"Amọ igba kan wa ti emi ati ẹ ko rira mọ nitori oriṣiriṣi nnkan to ṣẹlẹ ti mo si tun padanu iya mi.
"Ṣugbọn ero ọkan mi ni pe ma a maa ri Tope, inu mi a maa dun, pe ọmọ yii o ku mọ, nitori o ti bori arun jẹjẹrẹ yẹn,emi ti ro pe iṣoro yẹn ti di afisẹyin ti eegun n fiṣọ ni, mi o mọ pe iru iku bayii lo maa tun waa pa a."
Iru iku wo lo pa Tope Osoba gan-an?
Nigba to n dahun ibeere nipa iku to pa Tope Osoba gan-an, Foluke sọ pe ki i ṣe jẹjẹrẹ ọyan lo pa a.
Oṣere to ba Oloogbe beere iranlọwọ lasiko ti iṣoro jẹjẹrẹ ọmu naa ṣẹlẹ si i ni 2024 sọ pe:
"Emi o ki n fẹ sọ nnkan ti o ba da mi loju, amọ mo mọ pe igba ti emi ati Tope fi jọ wa lọdun to kọja, o ti ṣẹgun jẹjẹrẹ yẹn, ko si jẹjẹrẹ mọ.
"Lẹyin oṣu meji si mẹta to gba itọju tan, emi ati ẹ tun pada lọ sileewosan, dokita si fidi ẹ mulẹ fun wa pe ko si jẹjẹrẹ yẹn mọ.
"Koda, ọyan rẹ ti wọn ge, wọn o ge gbogbo ẹ, wọn kan yọ koko yẹn ni nibẹ ni, ko dẹ ti i di jẹjẹrẹ.
"Awọn nnkan mi-in wa nidii rẹ ti awọn ọlọpaa n ṣe iwadii le lori, ti ko ti i ye awa gan-an, ko ti i da wa loju pato, amọ ki i ṣe jẹjẹrẹ lo pa a."
Nipa awọn onitiata ti ko pọ nibi eto naa, Daramola sọ pe ki i ṣe pe wọn ko nifẹẹ Oloogbe, o ni kaluku lo ni tiẹ lara to n ran labẹ aṣọ.
Toyosi Adesanya sọrọ lori awọn oṣere to n ba ara wọn ṣọta nitori ẹgbẹ

Yatọ si Foluke Daramola, gbajumọ oṣere mi-in to tun wa nibi eto naa ni Toyosi Adesanya.
Nigba to n sọrọ lorukọ ẹgbẹ oṣere TAMPAN, Toyosi Adesanya bu ẹnu atẹ lu awọn oṣere kan to ni wọn n ṣọtẹ ẹni to ba ku ninu awọn.
"Gbogbo wa la da agbada iku, amọ iyalẹnu lo maa n jẹ pe bi eeyan kan ba ku, awọn kan a tun ṣi maa ṣọtẹ rẹ, wọn a ni ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN.
"Tope ku, awọn kan n sọ pe ko ṣe ẹgbẹ, kawọn eeyan ma dawo fun un.
"Tope ṣiṣẹ, o ṣe ẹgbẹ, ẹ jẹ ka yee ṣe bẹẹ funra wa.
"Gbogbo wa la wa nibi yii, ta a ni a n ṣẹyẹ fun un, ipa ki ni iwọ sa fun un nigba aye ẹ. Ẹ jẹ ka yee ṣe bẹẹ.
"Tope fi atẹjiṣẹ ohùn ranṣẹ si mi lọjọ kẹta oṣu Keje, o ni ki n maa pe oun siṣẹ. O ni bi mo ṣe gbiyanju ti mo di ọlọmọ laye, oun naa fẹ lọmọ laye."
Toyosi fi kun un pe Tope gbiyanju, ṣugbọn ko duro jẹ idaamu rẹ.
Lakootan ọrọ Toyosi, o ba awọn ẹbi Oloogbe to ni awọn jọ jẹ ọmọ ilu Remo kẹdun, o si rọ wọn lati gba ohun to ṣẹlẹ mọra.
Oluṣọ Itunu Onadeko ko wa sibi eto naa
Bi awọn eeyan kan ti wọn wọ aṣọ agbara ti a mọ si Sutana, ti wọn si wa lati ijọ Sẹlẹ ṣe n wọle si gbagede ti eto yii ti waye, ẹnikan ṣoṣo ti awọn eeyan n foju sọna fun lati ri ninu wọn ni Oluṣọ Itunu Onadeko to jẹ ọkọ Tope Osoba.
Amọ Oluṣo naa ko wa rara.
Bakan naa ni awọn eeyan kan n sọ ọ pe ko tiẹ yẹ ki ẹnikẹni wọ Sutana wa si agbo naa rara.
Wọn ni eyi yoo maa mu awọn eeyan ranti Oluṣọ Itunu ti ẹnu n kun lori iku Tope ni.
Ni ibẹrẹ eto, Oluṣọ mi-in ti wọn pe orukọ rẹ ni Kingsley Ataifo lo ṣide eto pẹlu adura.
Lẹyin rẹ si ni eto bẹrẹ pẹrẹwu, ṣugbọn ti eto naa fi pari, Oluṣọ Itunu ko yọju.
Awọn ẹbi diẹ to wa nibẹ sọrọ nipa ibanujẹ ti iku Tope Osoba mu wa, awọn mi-in ko si wa ninu wọn nitori iku ọfọ ni pẹlu bi Tope Osoba fi iya ati baba agba fun awọn obi rẹ saye lọ.
Olùṣọ́ Onadeko ọ̀rẹ́kùnrin Tope Osoba ṣàlàyé nǹkan tó mọ̀ nípa ikú gbajúmọ̀ òṣèré tó lọ àtàwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án

Oríṣun àwòrán, Temitope Osoba/Instagram/Temitopa Osoba Fans/TikTok
Ọrẹkunrin gbajumọ oṣere ori itage, Temitope Osoba, to jade laye; Wolii Itunu Onadeko ti ṣalaye bi oṣere naa ṣe dagbere faye.
Wolii Onadeko ṣalaye ninu ifọrọwerọ ti o ṣe pẹlu Celestial Reality Check lopin ọsẹ to kọja wi pe ni agọ ọlọpaa kan ni Ikorodu nipinlẹ Eko ni o ku si.
Onadeko sọrọ yii lẹyin ti ọpọ eeyan ti fẹsun kan an lori ayelujara wi pe oun lo lu u ti ẹmi fi bọ lẹnu rẹ.
Awọn kan tiẹ sọ pe ọrẹkunrin Tope ni o fun un ni majele jẹ ti o si gba ibẹ ku.
Amọ, Wolii Onadeko ṣalaye wi pe ẹnikan lo pe oun lori foonu lọganjọ oru wi pe Tope ti ku.
''Ẹni ti mi o mọ ri rara lo pe mi ni nnkan bi ago mejila oru wi pe Tope ti ku si agọ ọlọpaa kan ni Ikorodu.
Onadeko to jẹ Oluṣọ ile ijọsin CCC Onibuore Cathedral, Bogije, Ibeju-Lekki niluu Eko sọ pe oun ko tiẹ mọ agọ ọlọpaa ti o ku si gan an ni Ikorodu.
Oluṣọ Onadeko ṣalaye pe Arabinrin Kehinde Osoba ti oun naa ni ile ijọsin ni Tope lọ ri ki o to ku.
''Tope sọ fun mi pe oun fẹ lọ ri Arabinrin Kehinde, koda, o ni ki a jọ lọ sibẹ.
Ṣugbọn mo sọ fun un wi pe iṣẹ ijọ ko le jẹ ki n ri aye lati tẹle e lọ sibẹ.
Ẹni to maa n ṣe irun ti Tope maa n sun sọdọ rẹ ni wọn jọ lọ sọdọ Arabinrin Kehinde Osoba.
Amọ, mo n ba a sọrọ ni gbogbo asiko naa, koda, o tun kọ ''Ogo Tuntun'' soju opo ayelujara rẹ lasiko naa.
Lẹyin naa ni mo gbọ wi pe Tope ti ku si agọ ọlọpaa.
Bo tilẹ jẹ pe mi o mọ agọ ọlọpaa ti o ku si, lẹsẹ kẹsẹ ni mo lọ si agọ ọlọpaa to sun mọ mi lati fi ọrọ naa to wọn leti,'' Onadeko lo ṣalaye bẹẹ.
Onadeko sọ pe iyalẹnu lo jẹ foun wi pe ọpọ eeyan n sọ lori ayelujara wi pe arun jẹjẹrẹ ọyan ti o mu un tẹlẹ lo pa a, nigba ti awọn mii sọ pe ẹbi oun lo fiya jẹ ẹ to fi ku.
Wolii ijọ CCC naa sọ pe lootọ ni o ti ni arun jẹjẹrẹ ọyan tẹlẹ, amọ, ki i ṣe arun naa lo ṣekupa a.
''Nigba ti mo kọkọ pade Tope, o sọ fun mi pe oun fẹ ṣiṣẹ abẹ lori arun jẹjẹrẹ ọyan lẹyin ti mo ṣe eto aabo fun un''
Onadeko ṣalaye siwaju si i pe ''nigba ti mo kọkọ pade Tope, o sọ fun mi pe oun fẹ ṣiṣẹ abẹ lori arun jẹjẹrẹ ọyan lẹyin ti mo ṣe eto aabo fun un.''
Oluṣo Onadeko tun ṣalaye wi pe irọ to jinna si ootọ niroyin kan tawọn eeyan n gbe kiri wi pe oun lo ọgbọn miliọnu tawọn eeyan da fun un lati tọju ara rẹ kọ ṣọọṣi.
O ni akanti Tope ni wọn fi gbogbo owo ti o ri ranṣẹ si, kii ṣe akanti oun.
Onadeko ni oun mọ pe awọn eeyan fun un lowo to fi mọ Oloye Mike Adenuga to fun un ni iwe sọwe dowo.
Ṣugbọn Oluṣọ loun ko fọwọ kan owo naa rara.
Wolii Onadeko ni nnkan bi ọdun meji sẹyin loun pade Tope, nigba ti ile ijọsin CCC Bogije si ti wa fun bii ogun ọdun bayii.
Laarin ọsẹ to kọja ni iroyin jade wi pe Tope dagbere faye lẹni ogoji ọdun.



























