Bàbá àti ọmọ ni Olubadan àti Makinde, kò yẹ kí ìjà máa wáyé láàárín wọn - Balogun Olubadan

Àkọlé fídíò, Ọba kì í ṣe òṣèlú, Olubadan, ẹ jáwọ́ níbẹ̀ kẹ́ ẹ má baà mú àrífín wá - Balogun Olubadan
Bàbá àti ọmọ ni Olubadan àti Makinde, kò yẹ kí ìjà máa wáyé láàárín wọn - Balogun Olubadan

Balogun Olubadan; Ọba Tajudeen Abímbọlá Ajibola ti kilọ fun Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja lati jawọ ninu oṣelu.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu fidio kan ti Balogun Olubadan ṣe ti BBC Yoruba si wa nibẹ.

O ni oniruru awuyewuye lo n lọ laarin igboro pe Olubadan fẹ yọ gomina Seyi Makinde nipo, ati pe Makinde funra rẹ naa fẹ yọ Olubadan nipo.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Makinde le yọ Olubadan nipo gẹgẹ bii agbara ti ofin fun ni Naijiria amọ ofin ko fun Olubadan lagbara lati yọ Makinde nipo.

Ọba Tajudeen Abímbọlá Ajibola ṣalaye pe baba ati ọmọ ni Olubadan ati Makinde jẹ, ko si yẹ ko si ija kankan maa waye laarin awọn mejeji.

Amọ o fidi rẹ mulẹ pe Olubadan gbọdọ jawọ ninu oṣelu ki ọrọ naa to di nnkan arifun fun un.

Ẹkunrẹrẹ ohun ti Balogun Olubadan sọ wa ninu fidio oke yii.