Wo àwọn ìpínlẹ́ àti ìlú tí àwọn agbébọn ti kọlù nílẹ̀ẹ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, AFP
Iroyin ijinigbe, ikọlu agbebọn ati ipaniyan ti kuro ni ma jẹ a gbọ kaakiri ilẹ Naijiria, bo tilẹ jẹ pe apa Ariwa lo ti bẹrẹ nigba kan.
Lasiko yii, ikọlu awon agbebọn ko mọ ni apa Ariwa tabi Ila-Oorun Naijiria mọ, o ti n waye ni Guusu-Iwọ -Oorun ti ṣe ilẹ Yoruba.
Ni awọn ipinlẹ bii Kwara, Ekiti, Oyo atawọn ibi ti wọn tin sọ ede Yoruba ni Kogi, ikọlu to mu ẹmi eeyan dani, ti won tun ko ọpọ eeyan wọgbo lọ ti waye.
Wọnyi ni awon ilu ti àwọn agbebọn ti kọlu nilẹẹ Yoruba
Kwara: Lara wọn apa ibi to jẹ ede Yoruba ni won n sọ nipinlẹ Kwara ti awon agbebọn ti kọlu ni:
Ijọba ibilẹ Oyun, Isin, Oke-Ede.
Ariwa Kwara: Edu ati ijọba ibilẹ Patigi.
Manigbagbe ikọlu to waye ni Kwara loṣu Kẹta ọdun 2026 yii, ni ti ilu Nuku, nijọba ibilẹ Kaiama, nibi ti wọn ti pa eeyan to le lọgọrun-un, ti wọn si ko ọpọ eeyan wọgbo lọ.
Ati bi wọn ṣe ji awọn olujọsin gbe ni ṣọọṣi ECWA niluu Kwara kan naa.
Bakan naa ni ikọlu waye nijọba ibilẹ Ekiti/Isin, nipari 2025, ni ṣọọṣi Christ Apostolic Church, Eruku.
Ẹmi sun ninu ikọlu naa, wọn si gbe ọpọ eeyan wọgbo lọ ki ijọba too ṣọna bi wọn ṣe pada wale.
Lẹyin eyi ni ikọlu mi-in tun waye ni Isapa, ni Kwara kan naa, ti wọn gbe eeyan mọkanla wọgbo lọ.
Ondo
Ariwa Akure:
Lara awọn agbegbe to ti koju ikọlu awọn agbebọn lagbegbe yii ni Pastor camp, Abule Sunday, Ademekun camp ati Alajido camp lagbegbe Ala Elefosan.
O to agbẹ ogun (20) ti iroyin sọ pe wọn ba ikọlu oru mọju naa lọ.
Ijọba ibilẹ Owo: Ilu Owo ni won ti pa ọpọ olujọsin ninu ṣọọṣi loṣu Kẹfa ọdun 2022, wọn si tun ti kọlu ilu naa lẹyin eyi.
Ekiti:
Ikọlu to waye laipẹ niluu Ekiti, yatọ si awon eyi to ti ṣẹlẹ ṣaaju ni eyi to ṣẹlẹ niluu Eda Oniyo.
Asiko isọji kan ni awon agbebọn yabo wọn nileejọsin to wa ni Eda Oniyo, nijọba ibilẹ Ilejemeje.
Wọn pa pasitọ, won si ji ọmọ ijọ to to mẹẹẹdogun lọ bi iroyin ṣe sọ.
Ṣaaju ni wọn ti kọlu ijọba ibilẹ Ajoni, l'Ekiti kan naa.
Awọn ilu to ke gbajare nigba naa ni Itapaji, Ijowa, Iyemero, Oke-Ako, Irele ati Ipao.
Kogi:
Awọn apa ibi ti wọn ti n sọ ede Yoruba ti wọn ti koju ikọlu agbebọn ri nipinlẹ Kogi ni: Kabba, Yagba East, Mopamuro ati Ijumu.
Oyo
Ko too kan ti ijọba ibilẹ Oriire to waye l'Ahoro Esinele lọjọ Ẹti to kọja yii, awọn agbebọn ti kọlu agbegbe Oloka, niluu Oyo, nibi ti won ti pa ọdẹ aṣọgbo marun-un, nigba ti won ya bo won lojiji laajin.
Ijọba ibilẹ Oriire yii kan naa ni wọn ti mu awon ọlọdẹ naa balẹ loṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii.
Lọjọ keji oṣu Karun-un ọdun 2026, awọn agbebọn ji ẹnikan ti won pe orukọ rẹ ni Alaaji Aleshinloye lọ ni Irawo, ijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Oyo.
Ṣaaju ni won ti gbe ọmọbinrin kan lọ lagbegbe Challenge, n' Ibadan, wọn si pa olukọ-fẹyinti kan so oko rẹ ni Ago Are, Oke-Ogun, ipinlẹ Oyo.
Bo tilẹ jẹ pe igbesẹ ọlọkan-o-jọkan n waye lati ọdọ ijọba apapọ, tipinlẹ ati awọn alẹnulọrọ lati ṣẹgun ijinigbe, igbesunmọmi ati rogbodiyan awon agbebọn lorilẹede yii, isoro ai si aabo to peye naa ṣi n tẹsiwaju kaakiri Naijiria.
Ogun
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fidi rẹ mulẹ lọjọ kejila, oṣu Karun-un ọdun 2026, pe awọn ajinigbe yabo ile alagboole kan ti a mọ si Estate,n'Ijebu-Ode.
Ipojo Golden Estate ni wọn pe ibẹ, lagbegbe Oke Eri. Wọn fidi ẹ mulẹ pe wọn gbe eeyan mẹta lọ ninu ẹbi kan ṣoṣo.



























