Ọlọ́pàá ṣàlàyé bí àwọn alamí ṣe ran àwọn ajínigbé tó kọlu iléẹ̀kọ́, jí akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé l'Oyo lọ́wọ́

Aworan eeyan kan to n pe lori foonu lapa ọtun aworan awọn agbebọn lapa osi.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 12

Awọn iroyin tuntun ti n jade nipa ijinigbe to waye ni ileẹkọ girama ati alakọbẹrẹ meji kan ni Ahoro Esiele pẹlu bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe n sọ pe awọn ti ṣiṣọ loju awọn afurasi agbodegba kan ti wọn ṣe alami fun awọn ajinigbe naa ti wọn si tun ba wọn sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ṣalaye pe awọn ọtẹlẹmuyẹ rẹ ti kẹẹfin awọn afurasi naa nipasẹ ipe ori foonu to waye laarin wọn atawọn agbebọn naa lasiko ti ikọlu naa n waye.

Gẹgẹbi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, ibanisọrọ to waye laarin awọn afurasi naa atawọn agbebọn ọhun da lori awọn koko ọna tawọn agbebọn naa yoo gba kọja lawọn ọna to wa ni igbo ọba National Park si awọn agbegbe kan ti wọn la kalẹ gẹ bi ibuba wọn.

Eyi lo mu ki ọwọ tẹ eeyan mẹfa bayii ti wọn si ti wa lahamọ ọlọpaa lati ṣeranwọ fun iwadii lori ikọlu naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Ọlayinka Ayanlade ṣalaye pe iwadi fihan pe awọn eeyan naa lo ṣe alami fun awọn agbebọn to ṣe ikọlu naa.

Bakan naa ni alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ṣalaye pe ifọrọjomitoro ọrọ lori ọna ti awọn agbebọn naa yoo gba laarin igbo ọba to wa lagbegbe naa lati de ibuba wọn.

Ìjọba fọwọ́ òfin mú afurasí mẹ́fà lórí ìjinigbé àti ìpànìyàn tó wáyé nílé ẹ̀kọ́ l'Ogbomoso, àwọn olùkọ́ ṣe ìfẹ̀hónúhàn

Arabinrin kan pọn ọmọ sẹyin, o si n sunkun, ọkunrin kan to de fila funfin mu iwe ilewọ dani

Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe ọwọ ti tẹ afurasi mẹfa ati eeyan mẹta mii lori iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan to waye niluu Esinele ati Yawota ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso nipinlẹ Oyo.

Ṣaaju ni Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti fidi rẹ mulẹ pe meje lawọn olukọ tawọn agbebọn naa ji gbe lọ.

Kete ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ tan ni ijọba paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ile ẹkọ to wa lagbegbe naa.

Ṣugbọn ijọba ipinlẹ Oyo pada kede ṣiṣi pada awọn ile ẹkọ naa lonii ọjọ Aje ọjọ kejidinlogun oṣu Karun un yii lẹyin tawọn ẹṣọ eleto aabo ti lọ si agbegbe naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, awon olukọ ṣe ifẹhonuhan niluu Ogbomoso lonii ọjọ Aje lati pe fun itusilẹ awọn akẹgbẹ wọn atawọn akẹkọọ to wa ni ahamo awọn agbebon.

‎Awọn olukọ naa rọ ijọba apapọ ati ijọba Ipinlẹ Oyo lati ri daju wi pe awọn akẹgbẹ wọn to wa ni ahamo awọn agbebon ati awọn akẹkọọ ri itusilẹ gba.

‎Awọn olukọ ọhun to wa lati awọn ijọba ibilẹ to wa nilu Ogbomoso bẹrẹ iwọde naa ni bii aago mẹsan an aarọ ti wọn si ṣe iwọde naa lọ si ile ẹkọ girama ati ti alakọbẹrẹ mẹwa lagbegbe Ogbomoso.

‎Aabo to peye ko si fun awọn olukọ to wa ni igberiko

‎Ọkan ninu awọn to n ṣe ifẹhonuhan naa to tun jẹ olukọ ni ijọba ibilẹ ti iṣẹlẹ naa ti waye ṣalaye wi pe eto aabo ni igberiko fun awọn olukọ ko dara to.

‎Iyanda Joshua to jẹ olukọ ni ile ẹkọ Lasubu Alada ni ijọba ibilẹ Oriire ṣalaye wi pe bi awọn olukọ ko ba jade lati ṣe ifẹhonuhan ìjọba le ma ṣe amojuto eto aabọ awọn olukọ to wa ni igberiko.

‎O rọ Gomina Ipinle Oyo Seyi Makinde lati ri i wi pe awọn to wa ni igbekun awọn agbebon naa gba itusilẹ.

‎Bolaji Folashade ọkàn lara awọn to n ṣe ifẹhonuhan sọ pe bi awọn olukọ ko ba jade lati fi aidunnu wọn han, ijọba le ma gbe igbese to yẹ.

‎Folashade ni ki ìjọba ibilẹ Oyo sanwo idoola fun awọn afurasi agbebon naa.

Bakan naa ni o ro awọn to wa ni ipo alaṣẹ lati gbe igbese ki awọn akẹkọọ ati olukọ to wa ni akata awọn agbebon le gba ominira.

‎Alaga ajo to n ri si ọrọ awọn olukọ nipinlẹ Oyo lagbegbe Ogbomoso, Ojelabi Michael, ro awọn olukọ to nṣe ifẹhonuhan lati gba alafia laye.

‎O ni ìjọba Ipinlẹ Oyo n ṣe akitiyan lati ri wi pe awọn to wa ni akata awọn ajinigbe gba ominira, nigba to n rọ wọn lati pada si yara ikekọọ wọn.

Olùkọ́ méje ni ajínigbé gbé lọ l'Ogbomosọ, wọ́n pa ọ̀kan- Gomina Seyi Makinde

Gomina Seyi Makinde, o de fila pupa, wọ aṣọ alawọ aro, o si lo igo so oju rẹ, o n wo ọ̀ọ́kan.

Oríṣun àwòrán, Gov. Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti ṣalaye pe olukọ meje ni awon agbebọn to kọlu ile ẹkọ meji lọjọ Ẹti to kọja niluu Ogbomoso, ipinle Oyo, gbe lọ, bẹẹ ni wọn pa ẹnikan ninu wọn.

Ọjọ Aiku ni Makinde fidi onka yii mulẹ, lasiko to n ba awon akọroyin sọrọ lori bawọn agbebọn ṣe ya wọ awọn ile ẹkọ meji ni Ahoro-Esinele, nijọba ibilẹ Oriire, Ogbomoso nipinlẹ Oyo.

Nipa ti onka awọn akẹkọọ to wa ni akata awon ajinigbe naa bayii, Seyi Makinde ko fidi eyi mulẹ.

"Olukọ to n kọ ẹkọ ẹsin Islam ni wọn pa lasiko ikọlu naa"

Gẹgẹ bi Gomina Makinde ṣe ṣalaye, o ni olukọ to n kọ awọn akẹkọọ nipa ẹkọ ẹsin Islam ni awọn agbebọn naa pa lasiko ikọlu ọhun.

Gomina sọ pe òye foju han pe awọn ikọ aṣekupani to n sa kuro lapa Ariwa Naijiria latari bawọn ologun ṣe n gbogun ti wọn, lo n sa wa si apa isalẹ nilẹẹ Yoruba.

Bakan naa ni gomina ṣalaye pe eeyan mẹfa ni ọwọ ti ba bii afurasi lagbegbe ti iṣẹlẹ yii ti waye.

O ni wọn fura si won pe awọn ni wọn n ta awon agbebọn naa lolobo.

Bakan naa ni Makinde sọ pe awọn mẹta kan naa tun wa ti iṣẹlẹ naa ni I ṣe pẹlu wọn, ti wọn ti mu pẹlu.

"Makinde sọ pe oun ti n ba awọn alaṣẹ sọrọ ni awọn ipinlẹ yoku, lori aisi aabo to n peleke si I yii.

O ni agbebọn ti wọn ba le nibi kan yoo sa wa si apa ibomi-in ti aabo ibẹ ko fẹsẹ mulẹ naa ni.

"Iṣoro ti a ni ni pe a gbọdọ mura silẹ de awon to n sa wa sọdọ wa yii, boya lile wọn pada ni tabi ka pa agbebọn to n sa fun awọn to n le e."

"Ijọba ipinlẹ Oyo ko ni I fi ti ologun nikan ṣe lati yanju iṣoro yii"

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Seyi Makinde sọ pe ologun nikan kọ ni ijọba oun yoo gbojule lati yanju aisi aabo yii.

O ni ajọsọ ti n waye pẹlu awon olori ẹsin atawọn olori awujọ, titi kan awọn alaṣẹ igbimọ ijọ Onitẹbọmi ta a mọ si Baptist, pẹlu bo ṣe jẹ pe ijọ naa lo ni ọkan lara awọn ile ẹkọ ti ajinigbe kọlu yii.

"A ti pinnu pe ki I ṣe ilana igbogunti wọn nikan la maa fi yanju ọrọ yii, a ti n ba awọn olori agbegbe, olori ẹsin; paapaa julọ awọn ijọ Baptist Convention, sọrọ"

Gomina Seyi Makinde lo sọ bẹẹ.

O rọ awọn olugbe agbegbe iṣẹlẹ yii lati ṣe suuru, o si fi da awọn ẹbi ti wọn ji eeyan wọn gbe loju pe iṣẹ ti n lọ lati ri I pe wọn pada wale pẹlu alaafia.

"A ko fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ yii, gbogbo ohun ti a ba lagbara la maa ṣe kiakia ta a si maa ko awon ọmọ wa bọ wale pẹlu alaafia."

Makinde fi kun un pe ijọba oun ko kawọ gbera lori iṣẹlẹ aburu yii.

O ni gbogbo agbara ti iṣakoso oun ni loun yoo lo lati ri i pe awọn to wa nigbekun ajinigbe pada wale.

Gomina ipinlẹ Oyo ṣapejuwe iṣẹlẹ yii bii eyi to buru pupọ to si mu ipenija dani.

Makinde sọ pe ojoojumọ ni ijọba oun yoo maa pe ipade oniroyin bayii, lati le maa jẹ ki araalu gbọ ibi ti iṣẹ ba n de lori ilakaka ati gba awon to wa nigbekun kalẹ.

Ṣaaju ni Ṣeyi Makinde ti kọkọ ba awọn olori ogun ṣepade, atawọn ẹṣọ alaabo nipinlẹ Oyo, lati mọ bo ṣe n lọ nipa ikọlu yii.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju

Awọn agbebọn ti kọlu ile ẹkọ LA School ati Community High School, Ahoro-Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn naa pa olukọ kan, ji olori ile ẹkọ pẹlu awọn akẹkọọ ti ẹnikẹni ko ti i le fi iye wọn mulẹ lọ nibi ikọlu naa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti naa, o ni awọn ajinigbe yawọ ile ẹkọ yii ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹsan-an aarọ.

Awọn akẹkọọ n ṣeto orin kikọ ti won maa n ṣe lori ila lasiko ti awọn agbebọn naa de bo ṣe wi.

Bi wọn ṣe de ni wọn ṣina ibọn bolẹ, wọn gbe ọga agba ile ẹkọ naa, Abilekọ Rachael Alamu pẹlu awon akẹkọọ ti ẹnikẹni ko mọ iye wọn lọ.

Ninu ikọlu naa ni wọn ti yinbọn fun olukọ kan, ẹni ti iroyin sọ pe o ti jade laye, bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ko fidi eyi mulẹ.

"Awọn agbebọn ti wọ agbegbe Ahoro-Esinele, nijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo. Wọn gbe ọga ile ẹkọ ati awọn akẹkọọ ti a ko mọ iye won lọ"

Bẹẹ ni atẹjade ọlọpaa wi.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí fídíò ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ àti arábìnrin tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso táwọn agbébọn fi sórí ayélujára

Arabinrin meji, obinrin kan ninu wọn pọn ọmọ lẹyin, ekeji kawọ lori

Oríṣun àwòrán, Oyewale Seun Samuel

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe oun ti ri awọn fidio kan to ṣafihan awọn eeyan kan to wa lara awọn tawọn janduku agbebọn ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire niluu Ogbomoso lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fi sita ni o ti ṣalaye wi pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ri pe awọn doola gbogbo awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ ile ẹkọ ti wọn ji gbe lọ ni Esinele ati Yawota ni ijọba ibilẹ Oriire.

Olayinka sọ pe gbogbo awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa ni yoo foju wina ofin.

O tun fi da gbogbo ẹbi awọn eeyan to wa lakata awọn ajinigbe wi pe gbogbo wọn ni yoo pada wale lọ ba ẹbi wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati ma foya, amọ, ki wọn fọwọ sowọ pọ pẹlu ọlọpaa bi akitiyan ṣe n lọ lọwọ lati ṣawari awọn eeyan ti wọn ji gbe lọ naa.

Olayinka tun rọ awọn araalu to ba mọ ohunkohun nipa ibi tawon ajinigbe ko awọn eeyan naa si wi pe ki wọn fi to ọlọpaa leti.

Bakan naa tun ni ileeṣẹ ọlọpaa tun rọ araalu wi pe ki wọn ye gbe iroyin ti ko ba lẹsẹ nlẹ eyi to le da ibẹru bojo silẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ìjọba, ẹ má jẹ́ ká kú sí àkàtà àwọn ajínigbé o, ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ girama táwọn agbébọn jígbé pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ l'Ogbomoso ké gbàjarè

Awọn eeyan ilu Esinele ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomso ati Ọga agba ile ẹkọ Esinele tawọn agbebọn ti ji ọga ile ẹkọ naa atawọn akẹkọọ lọ

Oríṣun àwòrán, Hon Olamijuwonlo Alao Akala/Facebook

Ọga ile ẹkọ girama Community High School, Esinele ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbọmoso, Arabinrin Alamu F.R. ti rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ, Gomina Seyi Maiinde ipinlẹ Oyo atawọn ọmọ Naijiria lati doola oun atawọn akẹkọọ ile ẹkọ naa tawọn janduku agbebọn jigbe lọjọ Ẹti to kọja tii ṣe ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un yii.

Arabinrin Alamu sọ ninu fidio kan to wa lori itakun ayelujara pe ni nnkan bi ago mẹsan an aabọ owurọ ọjọ Ẹti to kọja lawọn agbebọn kan ṣekọlu si ile ẹkọ naa ni Esinele ti wọn si ji oun atawọn akẹkọọ kan gbe lọ.

Ọga ile ẹkọ naa tun fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa wa lara awọn tawọn agbebọn naa jigbe, gbogbo wọn si ti wa ninu igbo lati ọjọ Ẹti.

''Mo ṣe fidio yii lati beere fun iranwọ lọwọ gbogbo eeyan, bẹrẹ lati ọdọ ijọba apapọ Naijiria, Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo, ajọ awọn ọmọlẹyin Kristi, CAN ati gbogbo eeyan.

Mo fẹ ki ẹ bawa yanju ọrọ yii ni itubi inubi ki a maa baa ku sibi,'' Arabinrin Alamu lo sọ bẹẹ.

Ọga ọlọpaa Naijiria ṣabẹwo si Oriire nibi tawọn agbebọn ti ji ọga ile ẹkọ atawọn akẹkọọ gbe lọ

Ẹwẹ, ọga ọlọpaa Naijiria, Tunji Disu, ti ṣabẹwo si ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso nibi tawọn agbebọn ti ji ọga ile ẹkọ, awọn oṣiṣẹ atawọn akẹkọọ lọ ni Esinele.

Ọga ọlọpaa fi aidunnu rẹ lori iṣẹlẹ naa, o si kẹdun pẹlu ẹbi awọn eeyan to ku ninu iṣẹlẹ naa.

Disu kọwọọ rin pẹlu Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, CP Ojo Adekimi, latari bi ijọba ibilẹ Oriire ṣe paala pẹlu ipinlẹ Kwara.

Kọmiṣọna ọlọpaa to n ri si eto aabo awọn ile ẹkọ, CP Abayomi Shogunle, naa wa lara awọn to tẹle ọga ọlọpaa Naijiria lọ si ijọba ibilẹ Oriire.

Lasiko abẹwo ọhun ni Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, CP Abimbola Ayodeji Olugbenga, jabọ fun ọga agba ọlọpaa Naijiria lori ibi ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ba iṣẹ iwadii de.

Ọga agba ọlọpaa wa sọ fun gbogbo awọn obi ati alagbatọ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ajọṣepọ awọn ẹṣọ eleto aabo mii ti n ṣisẹ takun takun lori a ti doola awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ ile ẹkọ tawọn agbebọn jigbe lọ.

O ni gbogbo awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa ni yoo foju wina ofin.

Ọga agba ọlọpaa to bẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa ṣeleri pe alaafia yoo pada jọba lagbege ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Disu tun paṣẹ pe ki wọn ko awọn ọlọpaa mii lọ si ijọba ibilẹ Oriire lati ṣawari ati lati doola awọn ti wọn jigbe ninu igbo.